UNICEF: À ń fẹ́ ìrànwọ́ $88m fún ìpesè óúnjẹ ní DR Congo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọ wẹ́wẹ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà Irínwó lo ń kojú ebi apaku-dorogbo ni orílẹ̀èdè DR Congo.Àjọ isokan àgbáyé lo fi ọ̀rọ̀ òhún léde wípé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìdílé ni ẹkùn Kasai, lọ tí sá wọ inú igbó nigba ti ebi tí ń sọṣẹ fún wọn, táwọn miran si ti gbẹmi mì.
Ẹkùn Kasai jẹ́ agbègbè tó gbilẹ́ nínú ọrọ̀ ajé lásìkò kan, tí wọn sì ń gbé ìgbé ayé àlàáfíà lorile-ede DR Congo, kí ìwà jagidi jagan to bẹ̀rẹ̀ nibẹ lọ́dún 2016.
wọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Jagidi jagan ọ̀hún bẹ́ silẹ lẹ́yin ti ìjọba ń hùwà àìbìkítà tí ó sì di ohun tí jagidi jagan fi bẹ̀rẹ̀. Àjọ isọkàn àgbáyé kéde nínú oṣù Kejìlá ọdún tó kọjá pé, wàhálà tó ń wáyé ní DR Congo jẹ́ èyí tó ga jù lọ nínú ìtàn wọn, tó sì nílò ìdáhùn pàjáwìrì Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé tó ń rí sí ìtọ́jú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ (UNICEF), tún polongo lati bẹ̀bẹ̀ fún iranlọwọ owó tó tó Mílíọ̀nù méjìdínláàdọ́run dọ́là láti rán ẹkùn Kasai lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbenuso Àjọ UNICEF, Christophe Boulierac, to ṣẹ̀ṣẹ̀ tajo de láti Kasai, ṣàlàyé bíi agbègbè náà ṣe burú tó lásìkò to bẹ ilé ìwòsàn mẹta wo.Boulierac ṣàlàyé bí àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ ṣe ń kú nítorí ebi








