Mo ń ní ìdálẹ́bi lọ́kàn mi pé nítorí mi làwọ́n òbí mi ṣe di èrò ẹ̀wọ̀n – Sonia ọmọ Sẹ́nétọ̀ Ekweremadu

Ọmọbinrin igbakeji aarẹile aṣofin agba Naijiria nigbakan ri, Sẹnetọ Ike Ekweremadu, Sonia ti sọrọ fun igba akọkọ lati igba ti ọrọ ẹjọ lilo ẹya ara eeyan ti wọn fi kan awọn obi rẹ bẹrẹ lorilẹede UK.
Ninu ọrọ to ba BBC sọ, Sonia Ekweremadu sọ pe inu iporuru ọkan ni oun wa lati igba ti wọn ti iroyin ti jade pe ọwọ awọn agbofin ti tẹ awọn obi oun, paapaajulọ pẹlu bi o ṣe han si oun idi ti wọn fi mu wọn.
“ile ni emi atawọn awọn mọlẹbi mi wa nigba ti a gburo ilẹkun. Awọn obi wa la tiẹ ro pe o de ṣugbọn awọn ọlọpaa la ri lẹnu ọna, wọn ṣalaye pe awọn wa mu mi fun nnkankan. Ara mi kọkọ bu mọ aṣọ ni”
Ile ẹjọ da Ekweremadu lẹbi lori ẹsun lilo ẹya ara eeyan lọna ti ko ba ofin mu
Ile ẹjọ kan lorilẹede UK da Ekweremadu, iyawo rẹ Beatrice ati Obeta to jẹ dokita wọn lẹbi lṣu kẹta ọdun 2023 lori ẹsun lilo ẹya ara eniyan lọna ti ko bofin mu lasiko ti wọn gbe ọmọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan wa si orilẹede UK lati ipinlẹ Eko ni Naijiria lati lee lo kidinrin rẹ.
Ile ẹjọ naa sọ pe Sẹnetọ Ekweremadu, ẹni ọgọta ọdun, iyawo rẹ to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ati dokita Obinna Obeta to jẹ ẹni aadọta ọdun yoo fi aṣọ penpe roko ọba nitori pe wọn jẹbi gbigbimọ pọ lati fi ẹtan gba kidinrin arakunrin naa lara rẹ, eyi si ni akọkọ iru ẹ labẹ ofin to tako owo ẹrun igbalode ti wọn ṣẹṣẹ fidi rẹ sọlẹ lorilẹede naa.
Awọn alaṣẹ orilẹede UK sọ pe awọn mẹtẹta yii fi ẹtan gbe arakunrin naa kuro ni ilu Eko lorilẹede Naijiria lọ si orilẹede UK lọdun to kọja lati lo kidinrin rẹ ni ile iwosan kan ni ilu London.

Oríṣun àwòrán, IKE EKWEREMADU/FACEBOOK
N ko fara mọ idajọ ile ẹjọ lori awọn obi mi
Nigba ti BBC bi Sonia nipa ero rẹ lori idajọ awọn obi rẹ, Sonia ni oun ko fara mọ idajọ naa, ṣugbọn oun sọ eyi nitoripe awọn obi oun loun n gbe si lẹyin.
“Idajọ naa ye mi, amọṣa mi o fi ara mọ ọ, a le sọ pe nitori pe mo jẹ ọmọ wọn, ẹyin awọn obi mi ni maa gbe si.
“Amọṣa ofin gbọdọ ṣe iṣẹ rẹ. Sibẹ a ni lati ṣe ara wa ni ọkan gẹgẹ bi ẹbi kan naa.”
‘Mo wa labẹ itọju aisan kidinrin bayii’

Oríṣun àwòrán, PA Media
Sonia Ekweremadu, ọm Sẹnetọ Ekweremadu ti awọn Obi rẹ n tori lọ si ẹwọn nitori igbesẹ wọn lati lo kidinrin ọmọkunrin kan fi rọpo tirẹ naa ṣalaye fun BBC pe oun wa labẹ itọju aisan kidinrin bayii.
O ni aisan kidinrin ti oyinbo n pe ni Nephrotic syndrome lo n da oun laamu.
Aisan yii ni o maa n mu ki iye eroja Proteni ara to wa ninu itọ o pọ ju bi o ṣe yẹ lọ.
O tun ṣalaye pe ọna abayọ meji to wa fun oun ki oun ṣi tẹ siwaju lati itọju ti oyinbo n pe ni ‘dialysis’ titi iyoku aye oun tabi ki oun ṣe paṣipaarọ kidinrin.
Nigba ti BBC tun bi wọn idi ti wọn ko fi wa eeyan to le fun wọn ni kidinrin kan laarin ẹbi wọn, Sonia sọ pe ẹya “APO1” ni oun nitori naa ko si bi oun ṣe le ri laarin awọn mọlẹbi oun.
O ni irufẹ aisan kidinrin bayii maa n jẹyọ ni ẹbi baba oun, nitori naa o ṣoro diẹ lati ri eeyan ti o le fi kidinrin rẹ tọrẹ.Sonia ni oun ko mọ nipa bi wọn ṣe ri ọdọkunrin ti wọn fẹ lo naa nitori pe awọn mọlẹbi oun lo mojuto ọrọ itọju oun.
‘Igbesi aye mi ko le ri bakan naa mọ, mo n ni idalẹbi ninu ọkan mi’

Sonia sọ pe oun n bẹ awọn obi oun wo ni ọgba ẹwọn ti wọn wa, alaafia ni wọn si wa ṣugbọn oun ko le bi ọkan wọn ṣe n poruru si.
O ni oun kabamọ bi ọrọ naa ṣe yọri si fun ẹbi oun, paapaajulọ awọn obi oun to nilati la gbogbo oun ti wọn n la kọja nitori oun, eyi n mu ki oun ni idalẹbi lọkan oun.
Amọṣa, Sonia sọ pe awọn nnkan ti oun ti kọ gẹgẹbi ẹkọ ninu gbogbo iṣẹlẹ yii fihan pe biribiri laye n yi.
Obiri ni ile aye, lọjọ kan o le wa ninu igbadun ninu ile rẹ, ki o si tun yi biri lọjọ keji ki gbogbo nnkan ti dorikodo.”
O ni nnkan ko le ri bakan naa mọ fun ẹbi oun.
“Ero mi ni pe nnkan ko le ri bakan naa mọ, nibayii na mo n ni idalẹbi lọkan mi nitori pe nitori mi ni gbogbo nnkan wọnyii ṣe ṣẹlẹ.”












