Àwọn ọmọ Nàìjíríà ìṣí keji tí ogun lé kúrò ní Sudan ti wọ bàálù padà sílé

Aworan awọn akẹkọọ to n pada sile lati Egypt

Ọkọ baalu meji mii ti yoo gbe awọn ọmọ Naijiria ti ogun le kuro ni Sudan ti n bọ lọna bayii.

Ikede yi lati ọdọ Agbẹnusọ ajọ to n risi ọrọ ọmọ Naijiria nilẹ okere,NIDCOM,arakunrin Abdulrahaman Balogun sọ pe awọn baalu yi yoo gbera lati ibudokọ baalu Aswan ati Taco Aviation.

Iye awọn ti wọn n gbe bọ wa ko ti daju ṣugbọn o ni obinrin marundinlaadoje wa lara awọn to n pada sile.

Akẹkọọ ni ọpọ ninu wọn.

Awọn akọroyin mii to wa ni Sudan fi to wa leti pe awọn akẹkọọ obinrin ni wọn kọkọ bẹrẹ si ni gbe lọ si papakọ ofurufu eleyi to wa ni Port Sudan.

Bakan naa ni Abdulrahaman sọ pe awọn yoo pari eto gbigbe awọn ọmọ Naijriia to wa ni Egypt loni.

''A lero lati pari eto gbigbe awọn eeyan wa pada sile ti baalu Azman ba gbe awọn eeyan irinwo to ku ti MaxAir yoo si ko awọn eeyan to ṣẹku.Ki Ọlọrun ṣe ni irọrun''

Ni Alẹ Ọjọru ni awọn iṣi akẹkọọ akọkọ balẹ si papakọ ofurufu Naijiria to wa ni Abuja.

Awọn alaṣẹ ijọba Naijria lo n ṣeto gbigbe awọn ọmọ ilẹ naa pada sile lẹyin ti ogun si ọp[ọ ni ipopada lorileede Sudan,

Owó N100K, káàdì ìpe àti àwọn nkán míì tí wọn fún àwọn tó darí láti Sudan

Awọn akẹkọọ to dari lati Sudan

Awọn ọmọ Naijriia ti ogun le de lati Sudan ti ri ẹbun owo ọgọrun lọna ẹgbẹrun ati awọn nkan mii gba kete ti wọn dari si papakọ ofurufu ni Abuja.

Akọroyin wa jabọ pẹ owo yi wa lati ọwọ ijọba apapọ pẹlu atilẹyin lọdọ Dangote Foundation.

Bẹẹ ni wọn fun awọn ti ko ni eeyan ti yoo wa mu wọn lọ sile ni anfaani aaye ibusun nile itura mọjumọ.

A tun gbọ pe awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ kanna tun fun wọn ni siimu ipe pẹlu kaadi ipe ti iye owo rẹ to ẹgbẹrun marun un Naira.

Gbogbo nkan wọnyi ni ijọba lawọn lero pe yoo jẹ ki ipada sile wọn tubọ rọrun.

Ìkọ àkọ́kọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà tí ogun lé kúrò ní Sudan tí balẹ̀ sí Abuja
Aworan awọn ogun lende to dari pada si Naijiria lati Sudan

Oríṣun àwòrán, @nidcom_gov

Ikọ akọkọ awọn ọmọ orileede Naijira ti ogun le ni Sudan ti dari pada sile.

Ni alẹ Ọjọbo ni nkan bi ago mọkanla abọ alẹ ni wọn balẹ si papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe ni olu ilu Naijiria tii ṣe Abuja.

Nkan bi irinwo din diẹ lawọn iṣi akọkọ yi ti ireti si wa pe awọn mii yoo tun dari pada sile.

Ninu awọn to wa pade wọn ni Minisita fun abojuto ọrọ ijamba ati igbayegbadun ọmọniyan lorilẹ-ede yii.,Sadiya Faruk ati ọga ajọ to n ri si ọrọ iṣẹlẹ pajawiri,NEMA,Mustapha Habib Ahmed to fi mọ Abike Dabiri Erewa to n risi ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okere.

Awọn obinrin ati ikoko wa ninu awọn to dari de yi to fi mọ awọn akẹkọọ to n kawe ni Sudan.

O ti le ni ọsẹ meji bayi ti ogun ti bẹ silẹ ni Sudan ti awọn ọmọ orileede yi ati ilẹ mii lagbaye ti n gbiyanju lati sa kuro nibi ikọlu ọhun.

O kere tan eeyan ẹẹdẹgbẹta la gbọ pe o ti ba ikọlu yi lọ.

Bàlúù ọmọogun tó gbé ìṣí àkọ́kọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà tí ogun lé ní Sudan ti gbéra kúrò ní Egypt

baluu ọmọogun NAijiria naa

Oríṣun àwòrán, TWITTER/@NIDCOM_GOV

Baluu ogun ti ileeṣẹ ọmọogun Naijiria, NAF c-130H to l ko awọn ọmọ Naijiria to wa lorilẹede Sudan nibi ti ina ogun ti n jo lọwọ bayii ti gbera kuro ni Aswan gẹgẹbi awọn alaṣẹ orilẹede Egypt ṣe sọ.

Ireti wa wi pe baluu naa yoo gunlẹ si papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe nilu Abuja ni nnkan bii agogo mọkanla kọja iṣẹju mẹtalelogun lalẹ ọjọru.

Alaga ajọ to n ri si igbayegbadun awọn mọ Naijiria loke okun, NIDCOM, Arabinrin Abikẹ Dabiri -Erewa ṣalaye pe ileeṣẹ aṣoju ijọba Naijiria lorilẹede Egypt ti n ko awọn mọ Naijiria ti ogun le kuro ni Sudan lọ si ala ilẹ naa lagbegbe Arqueel lorilẹede Egypt ati pe awọn obinrin ni wọn n kọkọ n da lohun.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Ṣaaju, awọn idiwọ kan ti koju eto kiko awọn ọmọ Naijiria ti ogun le kuro ni Egypt naa nitori aigbọraẹniye pẹlu awọn alaṣẹ orilẹede Egypt ti wọn n faake kọri pe awọn ko ni gba ki ọmọ Naijiria kankan wọle nitori wahala iwe aṣẹ irinna Visa.

Amọṣa ajọ NIDCOM tun ṣalaye lẹyin o rẹyin pe aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ati akẹgbẹ rẹ fun orilẹede Egypt ti jọ sọrọ, wọn si ti gba lati tẹle awọn ofin maṣumatọ kan ti Egypt la kalẹ.

Ki lawọn ọmọ Naijiria to wa nibẹ n sọ?

Bakan naa lawọn ọmọ Naijiria kan pẹlu ti n fi iroyin nipa ohun to n ṣẹlẹ nibẹ ṣọwọ sori ayelujara Twitter.

Ọkan lara wọn sọ pe ibudo ogunlende kan lawọn awakọ to gbe awọn akẹkọọ lọ si ala ilẹ abawọle si orilẹede Egypt.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 3