Wo iye tí agbénipaṣètùtùọlà kan ń ta ẹsẹ̀ odindi èèyàn ní ìpínlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, other
Ọwọ ọlọpaa ti tẹ afurasi afiniṣetutuọla kan, Ifasọji Ayangbẹsan, ni ipinlẹ Ogun.
Afurasi naa sọ pe ẹgbẹrun lọna ogun naira ni oun n ta ẹsẹ eniyan ti wọn ba lọwọ rẹ.
Iroyin sọ pe ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kini ni wọn ṣeku pa ẹni to ni ẹsẹ ti ọgbẹni Ayangbẹsan to jẹ afurasi naa ra.
Ileeṣẹ ọlọpaa ṣe afihan afurasi naa ati awọn mejila miran ti ọwọ ṣinkun ofin ba lọjọru ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun eyi to wa ni agbegbe Eleweran nilu Abẹokuta.
Awọn ọlọpaa ni afurasi naa tun gbiyanju lati fi miliọnu kan naira owo riba fun ọlọpaa to mu u ṣugbọn onitọun kọ jalẹ pe afi ko fimu kata ofin.
Agbegbe Iloti ni ijọba ibilẹ Ijẹbu Ode ni afurasi naa n gbe, o ni ọwọ ọrẹ oun kan, ti orukọ rẹ n jẹ Lukman, ni oun ti gba awọn ẹsẹ eeyan naa.
'Agbẹjọro lo ni ki n wa N10m wa bi mo ba fẹ bọ ninu ọrọ naa'
Ayangbẹsan ni ilẹ isinku ni ọrẹ oun naa ti maa n wu awọn oku ti wọn ba sin jade ti yoo si ge ẹsẹ wọn.
“Mo ra ẹsẹ oku eeyan tutu meji naa ni, ṣugbọn n ko lọwọ ninu bi wọn ṣe pa onitọun. Ọrẹ mi Lukman lo wa ba mi pe oun ni ẹsẹ eeyan meji ti oun fẹ ta.
“Mo sọ fun un lootọ pe mi o nilo rẹ, ṣugbọn o ni mo le lo wọn fun etutu ọla ki aye mi naa le dara, mo si gb si i lẹnu.”
Nigba ti wọn n bii pe ki gan lo sun un de idi gbigbiyanju ati fun ọlọpaa ni miliọnu kan naira owo riba, afurasi naa ni agbẹjọro kan lo ni ki oun pese miliọnu mẹwaa naira lati le bọ ninu ẹjọ naa, ṣugbọn miliọnu kan naira loun ri.
O ni igba ti oun lọ fun agbẹjọro naa ni owo ọhun ni awọn ọlọpaa mu oun.












