Àṣìta ìbọn ba gbajúgbajá òṣèré tíátà

aworan Asia Abdelmajid

Oríṣun àwòrán, ALFAITORY FAMILY

Eekan osere tiata kan ti jade laye lẹyin to fara gbọta ibọn lẹkun ariwa ilu Khatoum tii ṣe olu ilu orilẹede Sudan.

Ọpọ kayefi ni iṣẹlẹ naa ti n ṣe awọn olugbe orilẹede naa pẹlu bi iroyin ṣe n fojojumọ yannana awọn eeyan wọn, mọlẹbi ati ẹni mimọ wọn to n bọ ha sinu wahala to n waye lorilẹede naa.

Oṣere tiata naa, Asia Abdelmajid, to pe ẹni ọgọrin ọdun lọsdun to kọja jẹ gbajumọ elere itage lorilẹede naa; lẹyin ti afẹfẹ sanmọri fẹ si iha ọdọ rẹ, to si di ilumọọka lẹyin ere kan to jade lọdun 1965 ti wọn pe akọle rẹ ni ‘Pamseeka’.

Ere itage naa di ape wa wo ni gbọngan aṣa orilẹede Sudan to wa ni Omdurman nibi ti wọn ti fi sami ayajọ ọdun kini ijijangbara orilẹede naa lọwọ aṣiwaju ikọ ọmọogun aditẹgbajọba kan nibẹ.

Awọn eeyan orilẹede naa ri Asia Abdelmajid gẹgẹ bi aṣiwaju ere itage lorilẹede naa, ati gẹgẹ bi akọkọ akọṣẹmọṣẹ ere itage lobinrin ki o to fẹyinti lọ maa ṣe iṣẹ olukọni.

Aṣita ibọn ba Asia Abdelmajid ni inu ile rẹ

Awọn mọlẹbi rẹ ni wọn awọn sin oku rẹ lẹyin wakati diẹ ti ọta ibọn awọn ọmọogun to n fi ija pẹẹta lorilẹede naa ba a l’Ọjọru ni ile ẹkọ jẹleosinmi kan ti o ti n ṣiṣẹ.

Wọn ni o lewu diẹ lati gbe oku rẹ lọ si iboji isinku lẹyin ti o ku.

Ko si ẹni le sọ igun to yinbọn ba a ni agbegbe Bahri.

Amọṣa awọn ọmọogun Rapid Support Forces, RSF to wa lawọn ibugbe kaakiri ilu Khatoum ṣi n ba awọn ikọ ọmọogun orilẹede naa, to n ṣe ikọlu lati ofurufu, fa a.

Awọn ọmọ ogun RSF n sọ pe awọn ikọ ologun gbiyanju lati ko awọn ọlọpaa kogberegbe sita lọjọru ṣugbn wọn ni awọn gbena koju wọn.

Akọwe agba ajọ iṣọkan agbaye, UN Antonio Gutarres ti ke si awọn igun to n ja lorilẹede naalati dawọ ogun duro ni kiakia ki ọrọ naa to burẹkẹ di ogun.

Awọn ohun to yẹ ni mimọ nipa Asia Abdelmajid

  • Ẹni ọgọrin ọdun ni Asia Abdelmajid ki o to jade laye.
  • Ohun ni iyawo gbajumọ akewi mọ orilẹede Sudan ni, Mohamed Moftah al-Faitory, ti oun pẹlu ti jade laye.
  • Gbajumọ oṣere tiata ni Asia Abdelmajid ki o to jade laye
  • Bakan naa ni gbajumọ oṣere tiata naa tun jẹ olukọ
  • Aṣita ibọn lo ba a ni ile rẹ to wa ni ẹkun ariwa ilu Khatoum.
  • O di gbajumọ lẹyin ere itage kan to ṣe ni ọdun 1965 ti wọn pe akori rẹ ni Pamseeka.
  • Ere itage rẹ, Pamseeka di ape wa wo ni gbọngan aṣa orilẹede Sudan to wa ni Omdurman nibi ti wọn ti fi sami ayajọ ọdun kini ijijangbara orilẹede naa lọwọ aṣiwaju ikọ ọmọogun aditẹgbajọba kan nibẹ.