'Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló máa ń bú mi pé mo fẹ́ ẹni tó ní ìpèníjà ara àmọ́ ohun tó mú mi fẹ́ ọkọ mi nìyí'

Abiodun David Dada baba ọlọmọ mẹta to ni ipenija aawọ ara lẹyin ti ibatan rẹ kan da asiidi si lara, eleyii to ba ẹwa oju rẹ jẹ.
Ronke Dada nigba ti o n ba ile iṣẹ BBC sọrọ ṣalaye wi pe awọn obi oun koro oju si irufẹ ẹni ti oun mu wale gẹgẹ bi ọkọ, ṣugbon ifẹ ti o wa laarin awọn ti dagba ju ki awọn obi oun da omi tutu si oun lọkan.
Ronke juwe ọkọ rẹ gẹgẹ bi ẹni ti o ni ibẹru Ọlọrun eyi to jẹ idi pataki ti oun fi fẹ ẹ to si tun tẹsiwaju wi pe orisirisi orukọ ni wọn n pe ọkọ oun David Dada nigboro nitori aleebu to wa lara rẹ.
Ninu ọrọ rẹ Ronke ni “mo rii gẹgẹ bi ẹni ti o ni ibẹru Ọlọrun, o fun mi ni ayọ ati ibalẹ ọkan lati gba ti mo ti fẹ ẹ."
"Oju ko ti mi nitori wi pe mo fẹ eeyan to ni ipenija ara nitori ojoojumọ ni o maa n mu inu mi dun”.
Mo ti darijin ibatan mi to da Asiidi si mi lara.

Abiodun David Dada nigba ti oun ṣalaye iṣẹlẹ to sọ ọ di ẹni ti o ni ipẹnija ara ṣalaye wi pe ọmọ ọdun kan ati osu mẹfa ni oun wa nigba ti ibatan mi doun kan da asiidi si oun lara.
Abiodun salaye pe nitori aigbọra ẹni ye to waye laarin ibatan oun ọhun ati iya oun ni o se hu iwa naa.
"O sọ fun Iya mi wi pe oun yo fi iru ẹni ti oun jẹ han an, abode rẹ ni ti asiidi ti o da si mi lori to si sọ mi di ẹni ti o ni ipẹnija aawọ oju”.
Abiodun fi kun pe “lọjọ ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ, ibatan mi gbe mi latori ibusun ti mo n sun si to si da asiidi si mi lori ati ẹnu."
"Ọpẹlopẹ alabagbe iya mi to sọ fun wọn nipa ohun ti ibatan mi se”.
Abiodun ẹni ọdun mejilelọgbọn ni ile iwosan ni iya oun sare gbe oun lọ, koda awọn Dokita ti ro wi pe oun ko le ye e.
O sọ wi pe lẹyin ọdun mẹrin nile iwosan ni Ọlọrun to doola ẹmi oun.
O ni bi o tilẹ jẹ wi pe ọwọ awọn ọlọpaa tẹ ibatan oun to wu iwa ibajẹ ọhun ṣugbon lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ ati ki mọlẹbi maa daru iya oun gba ki wọn tu ibatan oun naa silẹ ni gbaga ọlọpaa to wa.
Orisi orukọ ni awọn eniyan maa n pe mi
Abioun tun ni orisirisi orukọ ni awọn eeyan maa n pe oun bii ojuju, egungun ati awọn orukọ miiran ti kii tẹ oun lọrun.
"O wu mi ki n kẹkọ gboye iṣegun oyingbo ṣugbon nitori ipenija ti mo ni awọn ile ẹkọ ko gba mi lati kẹkọọ lọdọ wọn."
Idi niyi to fi eyi lo fi jẹ wi pe iṣẹ awọn to n so bata ni mo kọ, ti mo si ti di ọga nibẹ.
Abiodun tẹsiwaju wi pe o wu oun lati ṣe iṣẹ abẹ ki wọn le ya ẹnu ohun ati ẹti nitori oun ko gbọran daradara mo lẹyin iṣẹlẹ naa.















