Russia ju àdó olóró si Ukraine, ènìyàn 12 gbéͅmìí mì

Oríṣun àwòrán, Ukraine State Emergency Service
Eniyan mejila ti gbeͅmi mi leͅyin ti orileͅede Russia ju ado oloro si awoͅn ilu nla kaakiri Ukraine to fi mo olu ilu orileͅede naa, Kyiv.
Eniyan meͅwaa to fi moͅ oͅmoͅde lo ku ninu ado oloro ti Ukraine j ulu awoͅn ile igbe ni gbungun ilu Uman.
Ijoͅba ileͅ Ukraine ni obinrin kan ati oͅmoͅ oͅdun meͅta reͅ naa ku ni ilu Dnipro.
Bakan naa ni ado oloro dun lakoͅlakoͅ ni awoͅn ilu bii Kremenchuk ati Poltava.
Aareͅ orileͅede Ukraine, Volodymr Zelensky ni ile alaja nla ti awoͅn eniyan ti ku naa wa lara awoͅn ile igbe meͅwaa ti ado oloro naa bajeͅ ni Uman.
Ajo eleto pajawiri ni oͅmoͅde kan ti woͅn bi ni oͅdun 2013 ku ninu isͅeͅleͅ naa ati awoͅn moͅkanla miran to n gba iwosan.
Aareͅ Zelensky ni ikoͅlu naa safihan pe awoͅn ajoͅ lagbaye gboͅdoͅ mura si ijiya to toͅ si Russia fun awoͅn igbeseͅ woͅnyii.
‘’A le dawoͅ ibi duro nipa lilo ohun ijagun, eleyii ti ikoͅ oͅmoͅogun wa n se loͅwoͅ. Bakan naa ni woͅn le fofin de Russia, eleyii ti awoͅn ajoͅ lagbaye gboͅdoͅ mura si.’’
Adari ikoͅ oͅmoͅgun ilu Kyiv ni igba akoͅkoͅ niyii leͅyin oͅjoͅ 51 ti Russia yoo maa ju ado oloro si ileͅ naa.
Amoͅ ko I tii si akoͅsile iye awoͅn eniyan to faragba ninu iseͅleͅ naa ni Kyiv to jeͅ olu ilu Ukraine.
Ikoͅ oͅmoͅogun ileͅ Ukraine ni ado oloro moͅkanlelogun ninu meͅtalelogun ti woͅn ju si Ukraine ni awoͅn gboͅn danu pelu ohun ija drone to n tako ado oloro missile.















