Bàbá Adeboye ló kóͅkóͅ soͅ àsoͅtéͅlèͅ peͅ èmi ni ipò Gómìnà ìpínlèͅ Osun kan – Adeleke

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina ipinleͅ Osun, Ademola Adeleke ti salaye bi oludari ijoͅ The Redeemed Christian Church of God, Pasitoͅ Enoch Adeboye se jeͅ eͅni to koͅkoͅ soͅ fun oun pe oun ni ipo gomina ipinleͅ Osun sun kan.
Adeleke lo soͅ beͅeͅ ni ilu Ifewara, nipinleͅ Osun nibi to ti n si ilewosan tuntun, Jennifer Etuh medical center.
O ni oͅdun 2018 ni baba Adeboye koͅkoͅ soͅ asoͅteͅleͅ pe oun ni ipo gomina ipinleͅ Osun sun kan.
O ni nigba ti asoͅteͅleͅ naa ko koͅkoͅ dabi eͅni pe ko wa si imusͅeͅ, oun ko ba okan jeͅ, o un mura si eͅkoͅ oun.
‘’Woͅn yan mi jeͅ ni oͅdun 2018, mo pada si ileeͅkoͅ lati gbaradi fun ipo gomina Osun’’
‘’Pasitoͅ Adeboye lo fi ami ororo yan mi ni oͅdun 2018 to si soͅ pe emi ni ipo gomina ipinleͅ Osun sun kan.’’
‘’Mo ni igbagboͅ ninu oͅroͅ asoͅteͅleͅ naa amoͅ woͅn fi wuruwuru gba ipo naa loͅwoͅ mi ni oͅdun 2018.’’
‘’Mo pada si ileeͅkoͅ lati se igbaradi fun ipo ti mo feͅ, ti mo si pada ni oͅdun 2022, ti asoͅteͅleͅ naa si beͅreͅ si ni seͅ.’’
‘’Lati igba ti mo si ti di gomina ni mo ti beͅreͅ si ni se awoͅn ohun ti mo ni loͅkan lati se fun awoͅn araalu.’’
‘’Adari rere gboͅdoͅ ni ibeͅru Oͅloͅrun ni oͅkan, eyi ti mo si jeͅ oͅkan ninu woͅn. ‘’
‘’Idi niyii ti mo fi n san gbogbo owo osu osiseͅ ti woͅn jeͅ seͅyin. Adari gboͅdoͅ se ohun to toͅ fun awoͅn araalu.’’












