'Ẹ da ẹjọ́ nù', agbẹjọ́rò Adedoyin sọ fún ilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, others
Agbẹjọ́rò fún olùjẹ́jọ́ lórí ikú Timothy Adegoke, Yusuf Alli (SAN), ti rọ ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Osun tó wà ní ìlú Osogbo láti jọ̀ ọ́ jàre tú oníbàárà òun, ìyẹn Rahmaon Adedoyin sílẹ̀.
Rahmon Adedoyin, tó ni ilé ìtura Hilton Hotel tó wà ní Ile Ife àti àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ mẹ́fà mìíràn ló ń kojú ìgbẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn ikú Timothy Adegoke, akẹ́kọ̀ọ́ onípele kejì ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Obafemi Awolowo, Ile Ife.
Ní ọdún 2021 ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.
Nígbà tí ìgbẹ́jọ́ tún wáyé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní ilé ẹjọ́ lọ́jọ́bọ̀, agbẹjọ́rò Rahman Adedoyin sọ fún ilé ẹjọ́ pé gbogbo ẹ̀rí tó wà níwájú ilé ẹjọ́ fi kan pé Adedoyin kò mọ nǹkankan nípa ikú ọkùnrin náà.
Yusuf Alli sọ fún ilé ẹjọ́ pé nǹkan tó mú Adedoyin wà lára àwọn tó ń kojú ìgbẹ́jọ́ kò ṣẹ̀yìn wí pé òun ni olùdásílẹ̀ ilé ìtura tí ọkùnrin náà kú sí.
Bákan náà ló ní kò yẹ kí ilé ẹjọ́ fìyà jẹ aláìṣẹ̀ nítorí ìka tó bá ṣẹ̀ ni ọba ń gé nítorí náà kí ilé ẹjọ́ dá Adedoyin sílẹ̀ kó máa lọ láyọ̀ àti àláfíà.
Falana kò yẹ láti ṣojú ìjọba Osun níbi ìgbẹ́jọ́ yìí
Ṣaájú ni Yusuf Alli àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ méjì mìíràn ti kọ́kọ́ sọ fún ilé ẹjọ́ pé kí wọ́n dá agbẹjọ́rò olùpẹjọ́, Femi Falan dúró láti yé ṣojú ẹbí Timothy Adegoke àti ìjọba Osun níbi ìgbẹ́jọ́ náà mọ́.
Wọ́n ní Falana kọ̀ láti fi ẹ̀rí han ilé ẹjọ́ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Osun fún Falana láṣẹ láti máa ṣojú àwọn níbi ìgbẹ́jọ́ náà.
Ẹ̀wẹ̀, nígbà tó ń fèsì Femi Falana ní kí ilé ẹjọ́ má gbọ̀ ọ́ ti àwọn agbẹjọ́rò ọ̀hún nítorí wọ́n fẹ́ mọ̀ọ́mọ́ dá ìgbẹ́jọ́ náà padà sí ìbẹ̀rẹ̀ ni.
Falana ní tí ilé ẹjọ́ bá gba nǹkan tí àwọn agbẹọ́rò náà ń sọ wọlé, ó túmọ̀ sí pé gbogbo ẹ̀rí àti àwọn ìjókòó tó ti wáyé lórí ẹjọ́ náà láti inú oṣù Kẹrin ọdún tó kójá tí òun ti gba ẹjọ́ náà máa jẹ́ ‘didànù.
Ó rọ adájọ́ Adepele Ojo láti kọtí ọ̀gbọ̀in sí nǹkan tí wọ́n ń bèèrè fún kí ìgbẹ́jọ́ lè tẹ̀síwájú àti pé kí ìdájọ́ lórí ẹjọ́ náà le wáyé ní kíákíá.
Lẹ́yìn náà ni adájọ́ Adepele Ojo wá sún ìgbẹ́jọ́ síwájú fun oṣù kan síi.
Femi Falana àti Yusuf Ali balẹ̀ sílé ẹjọ́ fún ìtẹ̀síwájú ìgbẹ́jọ́ Ramon Adedoyin

Agbẹjọro agba Naijiria, Femi Falana ti bale sile ẹjọ ti igbẹjọ Rahman Adedoyin yoo ti maa tẹsiwaju lonii.
Yatọ si Falana, Awọn agbẹjọro olujẹjọ naa tun ti wa yara ile ẹjọ ọhun pẹlu.
Lara awọn agbẹjọro to ti wa ni ikalẹ ni Yusuf Ali, SAN, atawọn akẹgbẹ rẹ.
Adedoyin n jẹjọ to ni ṣe pẹlu ẹsun ipaniyan lẹyin iku Adegoke nile itura rẹ, Hilton, eyii to wa niluu Ile Ife.
Yatọ si Adedoyin, awọn oṣiṣẹ ile itura naa tun koju ẹsun ipaniyan kan naa.
Akẹkọọ ipele ‘Masters’ ni Tomothy Adegoke ki wọn to ṣeku pa a nile itura Adedoyin.
Ramon Adedoyin yóò tún padà sílé ẹjọ́ lónìí lórí ikú Timothy Adegoke
Ni ọjọ kejì, oṣù kejì, ọdún yí ní wọn joko keyin lórí ẹjọ́ ikú tó pá Timothy Adegoke sílè Ìtura Hilton Dr Ramon Adedoyin n'ilu Ilé-Ifè.
Nígbà náà ni wọ́n sún igbejo na si ọjọ́ kẹrindínlógún, oṣù kẹta, ọdún 2023 yí ṣùgbọ́n tí ijoko na kò wáyé ní ọjọ́ na mọ.
Òhun ló fà a tí wọ́n fi sún igbejo na si ọjọ́ ketadinlogbon oṣù kẹrin tí a wà yí.
Gbigba akọsilẹ awọn agbẹjọro olujẹjọ ati olupẹjọ lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan Dokita Ramon Adedoyin atawọn oṣiṣẹ rẹ mẹfa ko waye mọ ni ọjọ kẹrin dínlógún oṣù kẹta ọdún yí mọ.
Adedoyin atawọn olujẹjọ yooku ni wọn n jẹjọ lori iku to pa akẹkọọ Fasiti Ifẹ kan, Timothy Adegoke sinu ilé itura Hilton tí dókítà Ramon Adedoyin nílùú Ile-Ife loṣu kọkanla ọdun 2021.
Lasiko igbẹjọ to waye gbẹyin lọjọ keji oṣu keji ọdun yii ni Onidajọ Agba Adepele Ojo atawọn agbẹjọro fẹnu ko pe ki wọn pade loni ọjọ'bọ fun gbigbo akọsilẹ awọn abala mejeeji wọle (Adoption of written addresses).
Gégé bi awọn agbẹjọro apá mejeeji ṣe kuna lati gbe iwe akọsilẹ wọn lọ sile ẹjọ laarin asiko to wa ninu ofin lo fa a ti igbẹjọ naa ko fi le wáyé ní oṣù kẹta ọdún 2023 yí.
Amọ ṣa, agbẹjọro olupẹjọ, Adeṣina sọ pe gbogbo awọn agbẹjọro ni wọn ti fẹnuko lati pada lọ fun igbẹjọ lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kérin ọdun yii.












