Ṣé lóòótọ́ ni NBA jáwé lọ rọ́kún nílé fún agbẹjọ́rò tó ń fa igbó lórí ayélujára?

Ifunaya Delilah

Oríṣun àwòrán, Ifunaya Delilah

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni Naijiria, NBA, ti jawe lọ gbele ẹ fun Ifunaya Delilah lori ẹsun aṣemaṣe.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2021 ni wọn burawọle fun ọdọbinrin naa gẹgẹ bii agbẹjọro ni Naijiria.

Amọ ọpọ araalu lo ti kọkọ n bu ẹnu atẹ lu awọn iwa ti agbẹjọrọ naa n wu lori ayelujara.

Lara awọn iwa ti Delilah n wu ti awọn eeyan ni ko bojumu ni bo ṣe maa n fa igbo ati bo ṣe maa n wọ awọn aṣọ to n ṣi idaji ara rẹ silẹ.

Delilah di gbajumọ loju opo Twitter ati Instagram latari awọn aṣọ to n ṣi ara silẹ to maa n wọ loju opo naa ati bo ṣe maa n fa igbo.

“Irọ nla! NBA ko jawe lọ rọkun nile fun mi”

Ẹwẹ ninu atẹjade kan loju opo Twitter rẹ, agbẹjọro naa ti sọ pe irọ ni iroyin pe NBA da oun duro ninu ẹgbẹ naa.

O ni “Jawe lọ rọkun nile fun tani?”

“Ki ni ẹri ti ẹ ni lati fi irufẹ iroyin bayii si igboro aye? Ẹ jọwọ, ẹ dẹkun ati maa pin iroyin ẹlẹjẹ kiri lai ṣe iwadii lati mọ ododo ọrọ ti ẹ n kọ iroyin nipa rẹ.”

“Lootọ ni aworan ihoho mi lu jade lori ayelujara amọ ko kan aye”

Lẹnu ọjọ mẹta yii ni agbẹjọro naa kede ninu fidio kan pe aworan ihoho oun ti lu sita.

O ni “Gbogbo eeyan lo mọ mi pe mo n gbe igbeaye mi bo ṣe wu mi lai ro ti ọjọ ọla.”

“Looto ni mo n fa igbo atawọn nnkan mii, amọ eyi to ṣẹṣẹ waye lẹnu ọjọ mẹta yii ni pe aworan ihoho mi lu sita lori Twitter, ko dẹ kan aye.”

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

“Awọn kan n sọ pe o yẹ ki n ro ti ọjọ ọla mi atawọn ọmọ mi.”

“Mo ti maa n sọ tipẹtipẹ pe ko wu mi lati bi ọmọ kankan.”

“Bẹẹni, mi o ni bimọ, bẹẹni mi o si gbero lati lọ sile ọkọ.”