Portable tún fojú balé ẹjọ́ lónìí, ibi tí ìgbẹ́jọ́ dé dúró lórí ẹ̀sùn mẹ́fà tí wọ́n kà si lọ́rùn nìyí

Portable nígbà tó ń wọ ilé ẹjọ́
Àkọlé àwòrán, Portable nígbà tó ń wọ ilé ẹjọ́

Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Ogun tẹ̀ka ìlú Ifo ti sún ìgbẹ́jọ́ olórin tàkasúfèé nnì Habbeb Okokiola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Portable sí ọjọ́ Kẹrìnlélógún oṣù Karùn-ún ọdún 2023.

Níbi ìgbẹ́jọ́ tó wáyé lónìí ni àwọn olùpẹjọ́ ti kó àwọn ènìyàn kan wá láti wá jẹ́rìí tako Portable pẹ̀lú àwọn fóònù tí wan jí gbé èyí tí wọ́n ní àwọn rí gbà padà lẹ́nu ìgbà tí ìgbẹ́jọ́ náà bẹ̀rẹ̀.

Ẹ̀wẹ̀, agbẹjọ́rò Portable wá sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń rí àwọn ẹ̀rí tí wọ́n kó wá náà ni, pé kí ilé ẹjọ́ fún àwọn ni ààyè láti ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí náà.

Èyí ló fà á tí adájọ́ fi sun ìgbẹ́jọ́ náà sí ọjọ́ Kẹrìnlélógún oṣù Karùn-ún láti tẹ̀síwájú ẹjọ́ náà.

Àkíyèsí ni pé Portable wá sí ilé ẹjọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ láì sí ariwo tàbí èrò lẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ àti bí ó ṣe wáyé níbi ìgbẹ́jọ́ tó kójá.

Wọ́ọ́rọ́wọ́ ni Habeeb Okikiọla, Portable wọlé sílé ẹjọ́ gíga ní Ifọ láài pariwo rárá pé ó ti zeh tàbí kò zeh!

Portable

Wo ibi ti ọ̀rọ̀ ìgbẹ́jọ́ Portable dé dúró báyíì ní kété tí Adájọ́ wọlé nílé ẹjọ́

Portable fun ara rẹ ti wa ni Ile-ẹjọ bayii yii, awọn oṣiṣe Ile-ẹjọ naa ti wa ni kalẹ, awọn eeyan kọọkan si ti n de lati wo bi igbẹjọ naa yoo ṣe lọ.

Portable

Igbẹjọ olorin Portable ni ile-ẹjọ Ifo

Ati kale si Ile-ẹjọ ti o wa ni ilu Ifo nipinlẹ Ogun nibi ti olorin Habeeb Okikiola ti a mọ si Portable ti maa fi oju ba Ile-ẹjọ fun awọn ẹsun ti wọn fi kan.

Koda, Adajo ti wa ni ikalẹ ninu ile ẹjọ ni Ifo ni ipinle Ogun bayii

Portable

Òní ni Portable yóò tún fojú ba ilé ẹjọ́ ní Ifọ lórí ẹ̀sùn mẹ́fà tí wọ́n fi kàn án

Idajo

Oríṣun àwòrán, @Others

Habeeb Okikiola ti ọpọ n pe ni Portable ni oun ati agbẹjọro rẹ yoo foju ba ile ẹjọ ni oni, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹrin, ọdun 2023 yii.

Saaju ni wọn ti gba oniduro rẹ lẹyin to ṣe ọjọ mẹta lastimọle loṣu to kọja lori ẹsun mẹfa ti awọn agbofinro Naijiria fi kan an.@Others

Àwọn ẹ̀sùn mẹ́fa tí Portable yóò jẹ́jọ́ lé lórí rèé – Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá

Diẹ lara awọn ẹsun ti wọn ka si Portable lẹsẹ?

Ninu ile ẹjọ loṣu to kọja ni ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti fẹsun kan Portable pe:

Ẹsun pe o lu ọkunrin kan ni agbegbe Otta ti ẹni naa si fi ẹsun kan an lọdọ Kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ̀ Ogun.

Ọpọlọpọ ẹsun ni awọn eeyan tun ti fi kan an nipa ṣiṣe ikọlu si wọn torinaa, a o fi ọrọ wa a lẹnu wo.

Adejobi sọ pe ko si oju iṣaju labẹ ofin “torinaa ẹ jẹ ko foju ba ile ẹjọ ki a si gba awọn adajọ laye lati gbọ awọn ẹsun ti wọn fi kan an. Ko kọja ofin rara.”

Ẹwẹm awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi aridaju han pe wọn fi panpẹ ofin mu Portable ni ọjọ Ẹti ọsẹ to kọja ti wọn si ni wọn gbe igbesẹ naa lẹyin ti wọn fun un ni gbedeke oni wakati mejilelaadọrin lati bọwọ fun ipe ti ọlọpaa fi pe e.

Mo ti yí ohùn padà ẹ̀jẹ̀ kò lágbára ju omi lọ mọ́ – Portable

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Gbajugbaja olorin takasufẹ, Portable ti ni ohun ti yi ohun pada lori ọrọ ti oun ma n sọ pe ẹjẹ lagbara ju omi lọ, ti awọn oloyinbo n pe ni Blood is thicker tha water.

O ni eleyii ti yipada bayii, nitori nkan ko rọgbọmọ.

Ohun ti owe yii tunmọ si tẹlẹ ni pe mọlẹbi ẹni ni ma n gbani silẹ ni ọjọ gbogbo nitori okun to so wọn pọ ni agbara ju awọn ọrẹ to ku lọ.

Amọ olorin Zazu naa ni owe ọhun ko ni itumọ si oun ni aye ode oni nitori ohun gbogbo ti yipada.

''Adupẹ lọwọ awọn to fi ifẹ han si wa''

O ni laipẹ ni ni oun mọ pe ajumọbi ko kan ti aanu,ẹni a ba ran si ni lo n seni loore.

O ni igbayi ni oun ṣẹṣẹ mọ pe awọn ajoji ati awọn ti kii ṣe mọlẹbi lee seni loore ju awọn to jẹ ẹjẹ kan naa pẹlu rẹ.

‘’ Ni igba lailai wọn ma n sọ pe ẹjẹ ni ipọn ju omii lọ amọ ni aye o de oni la eti ẹ ko ma gbọ, ẹjẹ ko lagbara ju omi lọ mọ o’’

‘’Igba ti o ba ni owo nikan ni wọn ma n fi ifẹ han si eniyan. Ko si ifẹ otitọ mọ ni ilu wa, se o gbọ?

‘’Zazu iya mi sọ fun mi pe o ni awọn eniyan kan ti a ko gbọdọ bere omi ni ọwọ wọn lati mu, ko si bi oungbẹ naa ti gbẹ eniyan to, shongbọ?’’

''Adupẹ lọwọ awọn to fi ifẹ han si wa.''

‘’Amọ awọn kan wa to jẹ pe ti wọn ko ba ni owo, iwa kan ni wọn maa hu si wa, ti wọn ba si ni owo bayii, iwa miran ni wọn maa gbe jade.’’