Nítorí aàyè láti páàkì ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ sí Tolulope gún Pablo pa ní Ajah ní Eko

Oríṣun àwòrán, Others
Ọkunrin ẹni ọdun ọkanlelogoji kan, Tolulope Olowu. lo ti ko si pampẹ awọn ọlọpaa lẹyin to gun aladugbo rẹ kan pa nipinlẹ Eko.
Iṣẹlẹ naa lo waye ninu ile alajọgbẹ First Unity Estate to wa ni agbegbe Badore ni Ajah.
Tolulope Olowu ni o gun aladugbo rẹ ẹni ti awọn eeyan mọ si Pablo pa lẹyin ti ariyanjiyan waye lori aye igbokosi "paaki" to wa ninu ile ajọgbẹ ọhun.
Iṣẹlẹ to waye ni bi aago mẹwaa alẹ ọjọ Abamẹta to kọja lọ, bo tilẹ jẹ wi pe awọn aladugbo gbiyanju titi lati ba wọn pari aawọ ọhun, pabo lọ jasi ko to di wi pe Tolulope gun Pablo lọbẹ ninu to si jade laye lẹsẹkẹsẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fidi isẹlẹ naa mulẹ .
O ṣalaye wi pe deede aago mẹwaa alẹ ọjọ Abamẹta ni iṣẹlẹ ọhun waye kí wọn to fi to ile iṣe ọlọpaa leti ni deede aago meji ooru ana.
Benjamin Hundeyin ni "awọn ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Langbasa to wa nidi iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ti debi iṣẹlẹ ọhun ti wọn si ti ya aworan agbegbe ti isẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ".
Hundeyin ni ẹni ti o jẹbi ẹsun naa ati ohun eelo to fi pa Pablo lọ ti wa ni akata awọn ọlọpaa,
O tẹsiwaju wi pe oku Pablo ti wá ní yara igboku pamọ si ti ile iwosan Yaba fun ayẹwo, bí ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii ni kikun lori ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.















