Yunusa-Ari ti INEC Adamawa wọ gàù bí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní kíkún

Oríṣun àwòrán, others
Giwa ile iṣẹ ọlọpaa orilẹ-ede yii, Usman Alkali, ti paṣẹ pe ki iṣe iwadii bẹrẹ lori igbesẹ ẹni ti o jẹ ọga ajọ eleto idibo ipinlẹ Adamawa, Hudu Yunusa-Ari.
Ọrọ yi ko sẹyin lẹta ti ajọ to n ri si eto idibo orilẹ-ede kọ lọjọ kejidinlogun, oṣu yii, ti wọn si ṣalaye ni kikun lori awọn ilana ajọ INEC ti Yunusa Ari ko tẹlẹ.
Alkali lo ti yan ẹka ikọ ileeṣẹ ọlọpaa to nidi iwadii lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ INEC kí wọn si fimu Ari ko ata ofin.
Ninu atẹjade ti ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa kọ latọwọ alukoro ajọ ileeṣẹ ọlọpaa, Usman Baba Alkani ni: " ileeṣẹ ọlọpaa yoo ri daju wi pe o di opo ijọba awarawa
mu,
mo tun fi n da awọn ọmọ orilẹede Naijiria loju ati awọn ile okeere wi pe gbogbo ohun tó yẹ ni ileeṣẹ ọlọpaa yoo ṣe lati ri daju wi pe gbogbo awọn to wa nidi iṣẹlẹ naa ni wọn foju bale ẹjọ.
Yunusa-Ari dojuti ẹgbẹ awọn agbẹjọro; o si gbọdọ jiya ẹsẹ rẹ
Ẹwẹ, agbarijopo awọn agbẹjọro ti kesi ajọ to n ṣe konkari awọn agbẹjọro, NBA lati fiya jẹ Hudu Yunusa-Ari,nitori igbesẹ rẹ tabuku ajọ ọhun.
Awọn agbẹjọro ọhun labẹ asia, Justice House International Organisation (JHIO), ninu iwe ti wọn kọ si aarẹ ajọ agbẹjọro niluu Abuja, Yakubu Maikyau, ti Toyo Jimmy fọwọsi. ni w#on ti sọ bẹẹ.
Ajọ ọhun ni pe Ari tapa si ofin ajọ idibo pẹlu bi o ti kede ẹni ti o bori gẹgẹ bi gomina Ipinlẹ Adamawa lai ti pari kika esi ibo ti wọn di, eyi ti o ba orukọ ẹgbẹ awọn agbẹjọro jẹ.
Ajo JHIO ro Maikyau lati gbe iwadii kalẹ kí wọn si fi iya to tọ jẹ ẹ ni ibamu pẹlu ofin to so ẹgbẹ ọhun pọ.















