Mi ò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú Ilana Omo Oodua àti Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye mọ́ - Wale Adeniran

Oríṣun àwòrán, Collage
Igbákejì Alaga tẹ́lẹ̀rí fún ẹgbẹ́ Ilana Omo Oodua, Wale Adeniran ti kéde pé òun kò ní àjọṣepọ̀ kankan pẹ̀lú ẹgbẹ́ náà mọ́.
Bákan náà ni Adeniran tún kéde pé kò sí àjọṣepọ̀ kankan mọ́ láàárín òun àti alága ẹgbẹ́ Ilana Omo Oodua, Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye mọ́.
Adeniran nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́ Ẹtì, Ọ̀jọ́ Kẹta, Oṣù Kejì ọdún 2023 ní láti ọjọ́ kíní oṣù Kejì ọdún 2023 ní òun ti yẹ̀bá láti máa jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Ilana Omo Oodua.
Ó ní ìpinnu òun yìí kò ṣẹ̀yìn fídíò kan tí olùrànlọ́wọ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye fi léde nínú oṣù Kejìlá ọdún 2022 níbi tó ti fi onírúurú ẹ̀sùn kan òun.
Ó ní èyí tó lágbára jù nínú ẹ̀sùn náà ni èyí tí wọ́n ti fẹ̀sùn kan pé òun kó owó ẹgbẹ́ náà jẹ́.
Adeniran tẹ̀síwájú pé lẹ́yìn àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n kà sí òun lọ́rùn náà ni òun rọ gbogbo àwọn lẹ́nulọ́rọ̀ nínú ẹgbẹ́ náà láti ṣèwádìí gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n kà sí òun lọ́rùn.
"Láti ìgbà náà ni mo ti yẹ̀bá gẹ́gẹ́ bí alága àti ọmọ ẹgbẹ́ Ilana Omo Oodua kí ìgbìmọ̀ tó bá ń ṣe ìwádìí le ṣe ìwádìí wọn dáadáa."
"Nígbà tó tún di ọjọ́ Kẹwàá oṣù Kìíní, ọdún 2023, mo tún pè fún ìwádìí mìíràn kí wọ́n sì fi àbọ̀ ìwádìí wọn léde tí mo sì ṣetán láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìgbìmọ̀ láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bó ṣe tọ́."
Mi o jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí
Adeniran wá ní láti ìgbà náà òun kò rí kí ìgbìmọ̀ kankan ránṣẹ́ pé ou fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tàbí ìwádìí kankan.
Ó ní èyí ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun ni kìí se òótọ́ àti pé gbogbo àwọn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn òun kò ní ẹ̀rí kankan láti fi gbe ẹ̀sùn wọn lẹ́sẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé kìí ṣe òun ni òun máa ṣe ìwádìí ara òun láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun nítorí náà ó yẹ kí àwọn tó fi ẹ̀sùn kan òun ṣèwádìí òun.
Ó fi kun pé nígbà tí kò si ti ìgbìmọ̀ kankan tí wọ́n gbé dìde láti ṣe ìwádìí yìí, ó fi hàn pé òun kò ní ẹbọ lẹ́rù tí Ọlọ́run sì ti wẹ òun mọ́.
Adeniran ní ọwọ́ òun ló kù sí bóyá kí òun lọ sí ilé ẹjọ́ láti pé ẹjọ́ tako àwọn tó parọ́ mọ́ òun.
Mi ò ṣe ẹgbẹ́ Ilana Omo Oodua mọ́ àmọ́ mo ṣì ní ìgbàgbọ́ nínú ìdádúró Yoruba Nation
Alága tẹ́lẹ̀ rí fún Ilana Omo Oodua náà ní pẹ̀lú ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun yìí láì sì ní ẹ̀rí kankan tí wọ́n yóò fi gbe ẹ̀sùn wọn lẹ́sẹ̀.
Ó ní òun kò ṣe ẹgbẹ́ Ilana Omo Oodua mọ́ àti pé òun kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye.
Bákan náà ló ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú Ilana Omo Oodua, síbẹ̀ òun ṣì ní ìgbàgbọ́ nínú Yoruba Nation.
Adeniran wá dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ènìyàn lọ́kan-ò-jọ̀kan fún àdúrótì wọn fún nígbà tí ẹ̀sùn náà fi ń lọ.












