2023 Election:Oludije sipo gomina ni ẹgbẹ oṣelu SDP sọ awọn ohun ti yoo sẹ ti o ba de ipo.

Àkọlé fídíò, 2023 Election:Oludije sipo gomina ni ẹgbẹ oṣelu SDP sọ awọn ohun ti yoo sẹ ti o ba de ipo.

Oludije sipo gomina nipinlẹ Ogun labẹ ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, Anthony Ojeshina ti fi awọn ohun ti wọn ṣe fun awọn araalu lede ti wọn ba dibo wọle fun un gẹgẹ bi gomina.

Ojeshina ni iru ipinlẹ Ogun ti ohun fẹ ni iru eleyii ti iya ko ni jẹ araalu ti ijọba apapọ ko ba tilẹ fun wọn ni owo lati ọwọ ijọba apapọ, iyen ''Federal allocation''.

Oludije sipo gomina naa ni awọn iriri ohun ati imọ ẹrọ ti oun ni ni ẹka alada nla ni oke okun, ati iriri oṣiṣẹ ijọba gẹgẹ bi kọmisọnna yoo fun oun ni anfaani lati ṣe ijọba ti awọn araalu fẹ.

Awọn nkan miran to ni lọkan lati ṣe wa ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba...