Ilé alájà mẹ́ta dàwó l’Abuja, ọ̀pọ̀ èèyàn há sábẹ́ rẹ̀, ẹ̀mí ṣòfò!

Iroyin ni eeyan ti dagbere faye nibi ile alaja mẹta kan to dawo ni agbegbe Gwarimpa nilu Abuja tii ṣe olu ilu Najiria l’Ọjọbọ ọsẹ.
Bo tilẹ jẹ pe a ko tii ri ẹkunrẹrẹ ko jọ, akọroyin BBC to lọ wo ohun to ṣẹlẹ fabọ jẹni pe wọn ti doola eeyan mejila bayii amọ ko si ẹni to tii le sọ pato iye eeyan to ti dagbere faye nibẹ.
Ẹwẹ, oṣojumikoro kan ti akọroyin wa ba sọrọ ṣalaye pe ọrẹ oun wa ninu ile naa lasiko ti o dawo ni agbegbe 7th Avenue, Gwarimpa, Abuja.
“Mo n kọja lọ lakoko naa ni mo dede rii ti ile naa ati eyi to wa lẹgbẹ rẹ n mi titi, ki n to yi oju pada, gbogbo nnkan kan yi biri afi wọọ nilẹ.”
Arakunrin naa ṣalaye pe eeyan akọkọ ti awọn doola to si jẹ ọrẹ oun, ẹsẹ rẹ mejeji ti ge.


Aworan ati fọnran ile to dawo naa ti gba ori ayelujara kan lasiko ti awọn oṣiṣẹ pajawiri lọ sibẹ.
Oludari ẹka ileeṣẹ to n bojuto idagbasoke ilu Abuja, Muktar Galadima sọ fun awọn oniroyin pe awọn oṣiṣẹ pajawiri ti wa nibẹ lati tun doola awọn eeyan sii.
Bakan naa, akọroyin wa jabọ pe laarin Oṣu mẹfa ni wọn ti kọ ile naa de ibi to de duro ko to dawo yii.















