Tolani Ajayi: Sex style and danger in pregnancy: Irú sítàílì ìbálòpọ̀ wo ló n jẹ́ kí oyún tètè dúró?

Àkọlé fídíò, TolaSex style and danger in pregnancy: Irú sítàílì ìbálòpọ̀ wo ló n jẹ́ kí oyún tètè dúró?

Wo ohun tó le fa oyún bíbàjẹ́ lásìkò ibalopọ lori eto Se lootọ ni lori ikannni BBC Yoruba.

Akọṣẹmọṣẹ nipa ilera obinri to tun jẹ onimọ nipa ibalopọ gbalejo BBC lori eto Sé lóòtọ́ ni?

Arabinrin Tolani Ranti Ajayi sọrọ ni kikun lórí igbagbọ awọn eniyan lori ohun to le ṣẹlẹ si obinrin to ba n ni ibalopọ lasiko to wa ninu oyun.

O só nipa awọn koko to jẹ ootọ ati awọn to jẹ ahesọ nipa ipo iloyun obinrin ati iru sitaili ibalopọ to le maa ṣe akoba fun obinrin bẹẹ.

Bakan naa ni Arabinrin Tolani ajayi sọrọ lori ero awọn eeyan kan lori pe iru sitaili ibalopọ ti eeyan ba ṣe maa n ṣokunfa ki eni naa bi ọmọ to dẹ diẹ tabi ko bi akanda ẹda.

O tun sọ pe iru sitaili ibalopo ko nii fi ṣe lati sọ boya ọmọ ọkunrin ni eeyan a bi ni tabi ọmọ obinrin.