Sex style: Se lootọ?: Wo irú Sítàílì tó yẹ láti fi bẹ̀rẹ̀ ìbàlópọ̀ lẹ́yìn ìbímọ- Tola Ajayi
Ṣé aṣẹ́wó ni obìnrin tó ń bèèrè fún ìbálòpọ̀ ni ọ̀pọ̀ igba?
Eto tuntun kan ti ileeṣẹ BBC Yoruba bẹrẹ bayii ni eto Se lóòtọ́?
Eto Se lootọ? ni a gbe kale lati maa dahun ibeere nipa ilera ti awọn ololufẹ BBC Yoruba n beere ni eyi ti a o maa fi yanana awọn ero, igbagbọ ati ironusi awọn eeyan kan to ti n rapala wọ inu aṣa ati igbagbọ iran Yoruba.
A o maa sọ nipa awọn ero ati igbagbọ to jẹ o wa nitootọ nipa ilera ati awọn eyi to jẹ pe ahesọ lasan ni.
A o maa gbe awọn akọṣẹmọṣẹ wa sori eto nibi ti a o ti maa beere ibeere marun un nipa awọn ero ati igbagbọ naa ki ẹyin ololufẹ wa fi le mọ eyi to jẹ ootọ ati eyi ti kii ṣe ootọ ninu awọn ọrọ, ero ati igbagbọ naa.
Eto Se lootọ? yii wa pelu ajọsepọ BBC Yoruba ati BBC Africa Health team ni Nairobi ni orilẹ-ede Kenya.
Eto yii ni yoo maa salaye kikun pẹlu iranlọwọ awọn akọṣẹmọṣẹ nipa ohun ti ko ye ẹyin ololufẹ wa naa to.
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àwọn ti Ààrẹ Tinubu fẹ́ yàn sípò Mínísítà
- Àwọn iròyin ẹlẹ́jẹ̀ márùn ún tó fẹ́ẹ̀ tú Nàìjíríà ká
- Bó ṣe ń wáyé ní Oyo, ló tún ń ṣẹlẹ̀ ní Kano, ilé ẹjọ́ júwe ilé fún Emir mẹ́rin tí Ganduje yan
- Ẹ wo àwọn ọ̀dọ́mọdé Naijiria tó ń ṣe bẹbẹ nínú isẹ́ aládaní nílé
- Mọ̀ síi nípa ewu tó rọ̀ mọ́ níní ìbálòpọ̀ lásìkò ìlóyún lórí ètò Sé lóòtọ́ ní BBC
- Èwo nínú àwọn amóhùnmáwòrán yìí lẹ rántí?
- Àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ Osun nawọ́ ìrànwọ́ sí Ọ̀wọ̀ lórí ààbò,ẹ wò ọnà tí wọn fẹ̀ gbé gbà
Se lootọ? lori asiko to yẹ fun ibalopọ leyin ibimọ:
Lọsẹ yii. Akọṣẹmọṣẹ Tola Ajayi to jẹ oludari agba ni Nordica Center ni ipinlẹ Eko ni olukọ wa lori eto.
Koko ti a n gbe yẹwo lọsẹ yii ni asiko ibalopọ laisi ewu fun obinrin lẹyin ibimọ.
Arabinrin Tola Ajayi to jẹ ọkan lara awọn oludari agba ni Nordica Center lo ba wa dahun awọn ibeere lori asiko to ye ki obinrin bẹre ibalopọ pada laisi ewu.
Ati irufẹ sitaili ti ko mu ewu dani pẹlu ero awọn kan pe aṣẹwo lo n beere fun ibalopọ julọ.

Mọ̀ sii nipa igbesẹ too le gbe ti o ba wa nibẹ lasiko ti iyawo rẹ n rọbi ati bẹẹ bẹẹ lọ.