Fake News; Àwọn iròyin ẹlẹ́jẹ̀ márùn ún tó fẹ́ẹ̀ tú Nàìjíríà ká

Oríṣun àwòrán, others
Ilé ìgbìmọ àṣòfin àgbà ní Nàìjíríà ti ká àbádofin tí yóò maa kó àwọn ènìyàn ní ìjánú láti gbé ìròyìn òfégè tàbí sọ ọ̀rọ̀ kòbákùgbé sí olésèlú lórí ayelujára
fún ìgbà keji lánàá
Abadofin náà ni wọn pé àkọlé rẹ̀ ni 'Protection from internet Falsehood and Manipulation Bill 2019, èyí ti sẹnatọ Muhammed Musa ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ̀.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ ní àbádofín yìí fi yàtọ sí èyí ti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ asofin àgbà to kọja ṣe àgbékalẹ rẹ̀, sùgbọ́n Musa ni bí ayélujára ṣe ń ràn ìṣẹ̀jọba lọ́wọ́ ni àwọn ènìyàn ń lòó láti ṣe akóba fun ọmí aláafíà Naijíríà, nítori náà o ṣe pàtàkì láti mójú tóo.
Kíní ìdí tí àbádòfin yìí fi pọ̀ dàndàn fáwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asofin lásìkò yìí
Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilé aṣòfin to dá si ọ̀rọ̀ náà sàlàyé pé, kí ìlọsíwájú to lè wáyé, tólórí tẹ̀lẹ́mù gbọdọ wà ní ìṣọ̀kan sùgbọ́n, àwọn ènìyàn ń lò ayélujára láti gbé àwọn ìròyìn òfégè síta láti ṣátá ètò àti ìpínnú ìjọba.
Wọ́n fi kún un pé ń ọ̀pọ ìgbà èyí a máa dá èdè àiyede sílẹ̀ láàrín àrá ìlú ti ó si máa n la ẹmí lọ nígbà míràn, tàbí kí o mú itẹsíwájú ǹkan rere nira.
Awọn àṣòfin fi kún un pé ni àye òdé òní, ọ̀pọ̀ àwọn ilé ìṣẹ́ ìròyìn tí ayelujara ló n dá omi aláafia ilú rú, ìlú ti kò si sí òfìn ẹ̀ṣẹ̀ ò sí ni bẹ, nítori náà òfin yìí jẹ ki olúkulùkù súnraki nítori ìjìyà to wà nibẹ̀

Oríṣun àwòrán, Senate
Ìjìyà to wà fún ẹni ti ó ba rú òfin yìí
Ilé ìgbìmọ̀ àṣofin tí ṣe àgékalẹ̀ ẹgẹ̀rún lọ́nà ọọdúrún naíra fun ọlọdani to ba lùgbàdi ẹṣẹ̀ yìí àti mílíọnù mẹ́wàá naira fún ilé iṣẹ́.
Bakan náà ni wọ́n rọ àwọn alárina fún ilé iṣẹ́ lori ayélujara láti ṣọ́rọ́ nitori kò yọ ẹnikẹni kalẹ̀.
Ìròyìn òfégà Márùn-ún to ti fẹ́ẹ̀ pín Naijiria yẹ́lẹyẹ̀lẹ sẹ́yìn
Ẹ fí omí iyọ wẹ̀ nítorí Ebola:
Ní ọdún ọdún 2014 tí àìsàn ẹbola wọ orílẹ̀-èdè Naijiríà ní ìròyìn kan gba ìgbòrò kan pé báàlẹ Igala, ilú kan ipinlẹ Kogi ni ki àwọn ènìyàn máa fi omí iyọ wẹ̀ kí wọ́n máa ba ni àìsàn ebola.
Eyí mú kí ọ̀pọ̀ ènìyàn maa fi omí iyọ wẹ ti ọ̀pọ́ si di èrò ilé ìwòsàn fún àlòjù iyọ̀ nígbà ti àwọn ènìyàn mejí ku.
Iroyin ẹlẹjẹ yìí tàn ká gbogbo orílẹ̀-èdè Naijiria.

Buhari ti kú:
Ní Oṣù kẹsan an, ọdún 2017 ni Iròyìn gbòdé pé ààrẹ Nàìjíríà Muhammedu Buhari kú.
Won ni o ku lásìkò to lọ fun itọju fún ìgbà pípẹ ni ilẹ Gẹ́ẹ̀sí, wọ́n tún fi kùn un pé ayéderu Buhari lo wá si Naijira eyí ti wọ́n n pe ni ará Sudan.

Ọ̀rọ̀ yìí kọ́kọ́ jẹyọ lórí YouTube láti ẹnú Nnamdi Kanu to jẹ olórí IPOB, ọ̀rọ̀ yìí jà ranyin-ranyin lórí ayelujara tí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn si n gbé ìròyìn náà kíri.
Ọ̀rọ̀ yìí pada tàn de ọ̀dọ̀ ààrẹ to si ni láti fi dá àwọn ara ìlú lóju ni ìgbà ti ìdìbò ọdun 2019 súnmọ, to si jade láti wá fi dá awọn ènìyàn lójú pé oun ni Buhari tààrà, bakán náà ni ilé iṣẹ́ ààrẹ tún fi àtẹjáde síta lórí ọ̀rọ̀ náà.
Ìjà to ṣẹ́yọ láàrin àwọn àgbẹ̀ àti Darandaran:
Àwòràn òfégè kan to tàn lori àtẹjiṣẹ́ twitter léyin ti ìjà bẹ́ silẹ̀ láàrin àgbẹ̀ àti danrandaran ti ìgbà ènìyàn sì báa lọ, ní wọ́n ni àwọn aworan náà jẹ ọkàn lara àwọn ti fúlani pa.
Nínú àwọràn náà ni obinrin kan dojubolẹ ninu àgbàrá ẹjẹ̀ rẹ̀ pẹ́lú àpá to lágbára ni apá rẹ̀, eyí ni wọ́n ni o jẹ ọkan lára àworan to wà ninu iṣẹ̀lẹ̀ náà.
Sùgbọ́n àwọran náà ti n ja lorí ayélujára láti ọdún 2011 tó si jẹ àra àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ to wáye ninu ìjà abẹlé láàrin ọkọ ati ìyàwo ni Naijiria.
Bákàn náà ni àwọran miran tun jáde tí ọ̀pọ ẹ̀mí si sòfò, sùgbọ́n àyẹ̀wò fihan pé àwọn ènìyàn náà kìí tilẹ ṣe ara Naijiria àti pé Dominican Republic ni fóto náà ti wá, ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmba ojú pópó ló fàá lọ́dun 2015.

Atiku pín Ounjẹ àti owó fún ìpolongo idibò:
Laureetta Onochie to jẹ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún ààrẹ Buhari lórí ọ̀rọ ayélujara padà tọ́rọ́ àfóríjìn gbàngba lẹyin tó parọ́ pé ààrẹ Buhari kọ òpòpónà túntún si Naijiria.
Ṣùgbọ́n ìwádìí fihan pé ojúlówó òpópónà náà wà ni Rwanda.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

Oríṣun àwòrán, BBC Sport
Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, Onochie tún gbée sórí Twitter ré pé Atiku Abubakar, "O fi àwọn ènìyàn si inú òṣì bi o ṣe ń pín Ounjẹ àti owó lásíkò ìpolongo idibò". Onochie gbé àwòràn Ounjé ati owó síta pe eyi wáye ni Sokoto.
Atiku yii lo jẹ́ alátakò Buhari fun ipò àarẹ lásìkò ìdìbò ọdún 2019
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2

Buhari fẹ́ fẹ́ ìyáwó túntun:
Eyí to súnmọ etílẹ̀ jùlọ ni ìròyìn to gbòde láipẹ pé àarẹ Buhari ń mura láti fẹ́ ọkàn nínú àwọn mínísítà rẹ̀ Sadiya Umar Faruq.
Bo tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn òfegè ni pé Buhari fẹ fẹ́ Sadiya, síbẹ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣètò ìyàwò náà lórí ayélujára

Ìrọ̀yìn òfégé náà gbalẹ̀ de bi pé wọ́n ṣe ìyàwò náà lóri ayelujára ni eyi ti ayé gbọ́ ti ọ̀rún náà mọ̀.
BBC n gba awọn eeyan ni imọran lati ṣọra nipa pinpin iroyin ofege kaakiri.
Nitori pe, iroyin ofege maa n da wahala silẹ ni.














