2020 Africa Prize:Ẹ wo àwọn ọ̀dọ́mọdé Naijiria tó ń ṣe bẹbẹ níní iṣẹ́ aládaní

Aisha Raheem àtí Victor Boyle-Komolafe

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àkọlé àwòrán, Aisha Raheem àtí Victor Boyle-Komolafe ti pegedé nínú àwọ́n orúkọ tí wọ́n fi sílẹ̀ fún àmì ẹ̀yẹ 2020 Africa Prize.

Aisha Raheem ati Victor Boyle-Komolafe ti wọn jẹ ọmọ Naijiria ti wọn n gbe ohun ribibiri ṣe ni wọn ti pegede ninu awọn ti wọn fi orukọ wọn silẹ fun ami ẹyẹ 2020 Africa Prize.

Eka Ami Ẹyẹ onimọ ẹrọ ni wọn fi orukọ wọn si.

Aisha Raheem gbe imọ ẹrọ kalẹ ti yoo ma a ran awọn agbẹ lọwọ ati ẹbi wọn lati ri wi pe wọn ko ko ounjẹ danu lọna aitọ.

Bakan naa ni Victor Boyle naa gbe imọ ẹrọ jade ti yoo ma se atunlo awọn nkan ti awọn eniyan ko lo mọ lati gbe ohun ara ọtọ jade.

Tani Victor Boyle-Komolafe to fẹ gba Ami Ẹyẹ 2020 Africa Price?

  • Fasiti ile iwe giga Toronto ni Boyle Komolafe kọkọ lọ lati kọ ẹkọ to ni i se pẹlu ihuwasi ati awujọ ni ọdun 2005 si ọdun 2008
  • Fasiti ile iwe giga Liverpool lo ti kọ ẹkọ eto isuna owo ni ọdun 2009 si ọdun 2012.
  • O ṣiṣẹ gẹgẹ bi oluranlọwọ fun ile iṣẹ Kakawa Asset Management fun oṣu mẹta lati oṣu Kẹfa si oṣu kẹjọ ọdun 2008.
  • Bakan naa lo sisẹ gẹgẹ bi ọmọ ẹkose ni ile iwe Price Water Company, PWC ni oṣu kẹfa, ọdun 2011 si oṣu kẹjọ, ọdun 2011.
Àkọlé fídíò, World Diabetes Day: Ọdún kọkandinlogun ti mo ti wà lẹ́nu itọ ṣúgà nìyí
  • Ni ọdun 2009 si ọdun 2012 ni o darapọ mọ ile iwe Liverpool International College, nibi ti o ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi oluranlọwọ fun awọn akẹkọọ pẹlu akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu ile iwe naa.
  • Ọdun 2013 si 2014 ni o sisẹ gẹgẹ bi akapo owo agba fun ile iwe Meadow Hall School ni ilu Eko lorilẹ-ede Naijrira
  • Ọdun 2013 si 2016 ni o ṣiṣe gẹgẹ bi akapo owo agba fun ile iṣẹ KPMG lorilẹ-ede Naijiria
  • Boyle-Komolafe ni oludasilẹ ile ounjẹ Ojoro Kitchen lati ọdun 2015 titi di asiko yii
  • Oun naa ni oludari ile iṣẹ Capture Solutions Limited lati ọdun 2018 titi di asiko yii.

Tani Aisha Raheem to fẹ gba ami ẹyẹ 2020 Africa Price?

  • Aisha Raheem to jẹ ọmọ orilẹ-ede Naijiria bẹrẹ ile iṣẹ rẹ Farmz2U lati lọ imọ ẹrọ fun ipese ounjẹ to n ṣe ara loore
  • Ọdun mẹsan an ni Raheem wa ti o ti n kọle fun awọn ẹran ọsin
  • O ni imọ ninu iṣakoso ati idanilẹkọọ fun isẹ aladani fun awọn eniyan
  • Ọdun 2017 ni Raheem bẹrẹ iṣẹ ara rẹ to n lo imọ ẹrọ lati ran awọn oṣiṣẹ ọgbin lati pese ounjẹ fun awọn eniyan.
Àkọlé fídíò, Divorcee: Ó sàn kí wọ́n yàgò fúnra wọn ju ki wọ́n ṣe ara wọn léṣe- Fisayo
  • Aisha ni igba ti oun ri koko ni omu oun ni oun bẹrẹ si ni kiyesi irufẹ ounjẹ ti oun n jẹ.
  • Ile iṣẹ Aisha n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ajọ ilẹ okeere lati gbe iṣẹ ọgbin larugẹ.
  • Imọran Aisha Raheem fun awọn ọdọ ni wi pe ki wọn ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ, ki wọn si gbajumọ nkan ti wọn ba fẹ ṣe.
Àkọlé fídíò, Ẹ wo fídíò Kìnìhún ní ibùgbé rẹ̀ tuntun ní Bogije, Lekki