Oyo Attack: Ilé ìwòsàn UCH ni Kọmíṣọ́nnà náà ti ń gba ìtọ́jú

olopaa
Àkọlé àwòrán, Iṣẹlẹ iku awakọ kọmiṣọnna ṣeni laanu

Kọmiṣọnna fawọn ọlọpaa ni ipinlẹ Oyo ni awọn maa gbe awọn ọmọ janduku to ṣe iṣẹ buruku yii ri.

O fidiẹ mulẹ pe nitootọ ni iku awakọ kọmiṣọnna naa ba ni ninu jẹ ṣugbọn ọ́dílí to jẹ ọlọpaa to n ṣọ kọmiṣọnna ṣi n agb itọju nile iwosan ijọba bayii.

Oga agba awọn agbofinro fi da awọn eniyan ipinlẹ Oyo loju pe o di dandan ki agbara ofin mu awọn to ṣiṣẹ ibi naa.

O ni ọwọ ko ni pẹ tẹ awọn janduku naa nitori iwadiii ti bẹrẹ lọgan ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Ki lo ti ṣẹlẹ tẹlẹ?

Awọn gende agbebọn kan ti kọlu Kọmiṣọ́nna fọrọ ilẹ ati ilegbe nipinlẹ Ọyọ, Amofin Abdulraheem Abiodun lalẹ Ọjọru ana.

Biodun Abdu-Raheem

Oríṣun àwòrán, Biodun Abdu-Raheem

Isẹlẹ naa la gbọ pe o waye ni deede aago mẹjọ alẹ ana nigba ti wọn n ja Kọmiṣọ́nna naa sinu ile rẹ, ti wọn si yin awakọ rẹ, Lukman Adebayo ni ibọn eyi to mu ko jade laye loju ẹsẹ, nigba ti wọn tun yin osisẹ ọlọpaa to n sọ ọ ni ibọn lapa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Gbenga Fadeyi salaye pe agbegbe ile Kọmiṣọ́nna naa ni Olunde Academy nilu Ibadan ni isẹlẹ naa ti waye.

Fadeyi ni Kọmiṣọ́nna ọlọpaa ti wa pasẹ pe wọn gbọdọ se awari awọn olubi ẹda to huwa laabi yii kiamọsa.

Biodun Abdu-Raheem

Oríṣun àwòrán, Biodun Abdu-Raheem

Àkọlé àwòrán, Agbébọn kọlu Kọmísọ́nnà fọ́rọ̀ ilẹ̀ àti ilégbèé ní Ọyọ, awakọ̀ dèrò ọ̀run

"Wọn pa awakọ kọmiṣọ́nna naa, ti wọn si tun yinbọn mọ ọlọpaa to n sọ pẹlu.

A maa wa wọn kan, ti ọwọ wa yoo si tẹ wọn, wọn si gbọdọ finmu ko ata ofin pẹlu, ti ẹlẹsẹ wọn ko si ni lọ laijiya.

Ko si ẹni to lee sọ iru ipo ti ilera Kọmiṣọna funra rẹ wa bayii nile iwosan UCH ti wọn gbe lọ,

Tabi idi ti wọn se kọ luu, bẹẹ ni awọn agbebọn naa tun mu ibọn ọlọpa to n sọ kọmiṣọnna naa lọ.

Ni bayii, ile asofin ipinlẹ Ọyọ ti pe ipade pajawiri igbimọ ile to wa fọrọ eto aabo lati jiroro lori isẹlẹ yii.

Àkọlé fídíò, Ẹ wo fídíò Kìnìhún ní ibùgbé rẹ̀ tuntun ní Bogije, Lekki