Ibadan Oba Crisis: Lekan Balogun ní ìjọba kò pe àwọn sípàdé kó tó gbé ẹjọ́ kúrò nílé ẹjọ́

Awọn ọba mọkanlelogun nilẹ Ibadan

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn ọba mọkanlelogun to n de ade lẹyin Olubadan tilẹ Ibadan ti fesi lori iroyin kan to n ja rainrain nilẹ pe ileeẹjọ ti fẹ gba ade lori wọn.

Ọjọ Isẹgun lawọn iwe iroyin kan gbe sita pe, adajọ ile ẹjọ giga kan nilu Ibadan, Aderonke Aderemi ti kede pe ki wọn gbe iwe ofin to se igbega fawọn ọba mọkanlelogun nilẹ Ibadan ti sẹgbẹ kan naa, eyi to fun wọn lasẹ lati maa de ade bii ọba nilẹ Ibadan.

Iroyin naa fikun pe, gomina Seyi Makinde lo pinnu lati gbe ẹjọ fanfa laarin Olubadan ati awọn ọba alade yoku naa kuro nile ẹjọ, ki wọn lee yanju ọrọ naa nitubi n nubi, ki alaafia si pada jọba laarin Olubadan ati awọn ijoye rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọba Lekan Balogun, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ kede pe, igbesẹ naa ko bojumu, ti awọn ko si faramọ rara nitori pe wọn kii fari lẹyin olori.

Ọba Balogun kede pe ti ijọba yoo ba gbe iru igbesẹ naa, sebi o yẹ ko bun awọn ọba mọkanlelogun naa gbọ, ki awọn si dijọ se ipinnu lori rẹ amọ eyi ko ri bẹẹ.

O fikun pe ade ori awọn wa titi laelae ni, ko si si ohunkohun to lee yẹ ade lori awọn nitori awọn yoo pada lọ pe ẹjọ miran lori igbesẹ tijọba gbe naa ni.

Ajimobi, aya rẹ ati awọn ọba mkanlelogun to gba ade nilẹ Ibadan

Oríṣun àwòrán, @pulseafricamag

"Ko si ẹni to lee gba ade lori awa ọba mọkanlelogun nilẹ Ibadan nitori ọna to ba ofin mu la fi de ade naa, kii se ọna eru. Wọn ko pe wa si ipade ki wọn to ni awọn fẹ gbe ẹjọ kuro nile ẹjọ nitori naa ko lee seese. Awa naa yoo pe ẹjọ miran lati tako igbesẹ yii ni kiakia. Ko sẹ ni to lee yan wa jẹ, a ko lee gba."

"Ki lo de ti ilana oye jijẹ nilẹ Ibadan ko se lee yatọ gẹgẹ bi awọn ilu miran nilẹ Yoruba. Bi ilu Eko se kere to yẹn, ọba mẹtalelaadọta lo wa nibẹ, amọ ọba kansoso lo wanilẹ Ibadan bo se tobi to. Bakan naa ni ọmọ sori nilẹ Ekiti, Ondo, Ẹgba ati bẹẹ bẹẹ lọ amọ ti Ibadan nikan lo yatọ nilẹ Yoruba."

Awọn ọba mọkanlelogun nilẹ Ibadan

Oríṣun àwòrán, @pulseafricamag

Ọba Lekan Balogun wa n beere pe ki lo de to jẹ ifẹ inu eeyan kansoso ni wọn fẹ tẹ lọrun lai ro idagbasoke ilẹ Ibadan lapapọ, nitori naa, o ni eyi ko lee seese, awọn yoo dijọ pade nile ẹjọ ni, ade yoo wa titi laelae ni, ko si ohun to lee yẹ lori awọn lọna to lodi sofin.