Kogi/Bayelsa Election: À mọ̀ pé rògbòdìyàn yóò ṣẹlẹ̀ ní ìdìbò náà - Ọlọ̀pàá

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ile isẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria ti ni awọn oloṣelu lo ra aṣọ ọlọpaa fun awọn janduku ti wọn wọ aṣọ ọlọpaa lati da ibo ru lasiko idibo ipinlẹ Kogi ati Bayelsa.
Ọga Agba ile iṣẹ ọlọpaa, Mohammed Adamu lo sọ eyi lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ile aarẹ ni Abuja.
Lori idibo to waye lọsẹ to kọja yii, Adamu ni awọn oṣisẹ Ajọ ọlọpaa ni ami idanimọ tootọ tiwọn, awọn oloṣelu lo lọ pese aṣọ fun awọn ayederu ọlọpaa.
O fikun un wi pe awọn ti fi panpẹ ọba mu awọn ayederu ọlọpaa mọkanla naa ni ipinlẹ Kogi ati Bayelsa.
Bakan naa ni ọga agba ile iṣẹ ọlọpaa fi kun un wi pe awọn mọ wi pe rogbodiyan yoo ṣẹlẹ ni idibo ipinlẹ mejeeji.
Amọ o ni awọn ọlọpaa tootọ ko pọ to bo se yẹ ko to, to si ni wi pe awọn ṣisẹ awọn karakara.









