PDP: Ọjọ́rú la máa mọ̀ bóyá Jonathan ṣelòdì sí PDP ní ìdìbò Bayelsa

Oríṣun àwòrán, Alamy
Ẹgbẹ oselu PDP ti ni ibi ipade awọn igbimọ amusẹya ẹgbẹ oṣelu PDP ti yoo waye lọla ni awọn yoo ti se agbeyẹwo bi eto idibo ṣe lọ ni ipinlẹ Kogi ati Bayelsa.
Akọwe ẹgbẹ oṣelu PDP, Kola Ologbondiyan lo sọ ọrọ yii lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ.
Eyi ko ṣẹyin bi awọn adari ẹgbẹ oselu APC ni ipinlẹ Bayelsa ṣe ṣe abẹwo si Aarẹ tẹlẹri, Goodluck Jonathan lẹyin idibo sipo gomina to waye ni Bayelsa.
- Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé Cameroon ni wọ́n ti ru Kìnìhún VI wá?
- World Toilet Day: Ṣé lóòtọ́ ni ìlú Eko gba ipò gidi tórí ṣíṣe ìgbọ̀nsẹ̀ níta gbangba?
- Nínú kó o fi omi fọ ìdi tàbí lo tííṣù fi fá a, Èwo ló rọrùn?
- Ọ̀daràn tó wà lẹ́wọ̀n tún wọ́'ke $100miílíọnu - EFCC
- Wada: Alága àjọ ìdìbò INEC àti ọgá ọlọ́pàá, mò fà yín lè Ọlọrun lọ̀wọ́
Minisita abẹle fun ọrọ to jẹmọ epo bẹntiroolu, Oloye Timipre Sylva ati Gomina ti wọn dibo yan ni ipinlẹ Bayelsa, David Lyon pẹlu awọn to lo ṣe abẹwo naa.
Ologbondiyan ni nibi ipade Ajọ amuṣẹya naa ni awọn yoo ti yanayan ipa ti ẹgbẹ oṣelu PDP ko ninu idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ Bayelsa ati Kogi.
O ni awọn yoo ṣe agbeyẹwo abẹwo ti ẹgbẹ oṣelu APC ṣe si Jonathan ati igbesẹ ti awọn yoo gbe lori rẹ.
Ẹgbẹ oṣelu PDP kuna lati kẹsẹjari ninu idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ Bayelsa, lẹyin ogun ọdun ti wọn ti n ṣe ijọba ipinlẹ naa.









