Mourinho kò ọ́rọ́ rẹ̀ jẹ,o padà wá dì akọ́nimọ̀ọ́gbá tuntun fún ikọ̀ Tothenham

Aworan Jose Mourinho

Oríṣun àwòrán, SpursOfficial

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Aya bẹ silẹ o bẹ sare lọrọ Jose Mourinho to gba iṣẹ akọnimọọgba tuntun Tottenham fẹ jọ.

Lọsan Ọjọru ni yoo ṣe igbaradi akọkọ pẹlu awọn agbabọọlu ẹgbẹ naa lalai fi asiko falẹ.

Loju opo Twitter kaakiri lawọn eeyan ti n sọ nipa iyipada tawọn n reti lati ọdọ Mourinho amọ wọn ko ye sọ nipa bo ti ṣe ṣaaju sọ pe oun ko ni gba iṣẹ akọnimọọgba ẹgbẹ naa.

Bẹẹni,Mourinho ti sọ tẹlẹ pe ifẹ toun ni si Chelsea pọ bẹ debi pe ohun ko le gba iṣẹ akọnimọọgba Tottenham.

Akọsilẹ fi han pe o sọ ọrọ yi lọdun 2015 ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ Chelsea pẹlu Tottenham ninu idije League Cup ni papa iṣere Wembley.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin,Mourinho ni alaga ẹgbẹ Tottenham Daniel Levy ti fi igba kan ba ohun sọrọ nipa gbigba iṣẹ ni Tottenham lọdun 2007.

Ki lawọn eeyan n sọ nipa iyansipo Mourinho

Gẹgẹ bi ohun gbogbo to ni ṣe pẹlu Mourinho,iriwisi ọtọọtọ lo ti n waye lati igba ti wọn yan si ipo tuntun yi.

Bawọn kan ti ṣe n dawọọ idunnu lawọn miran n sọ pe ko si ipa to le mu ba Tottenham yatọ si eleyi to ti wa nilẹ tẹlẹ

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Skip X post, 3

End of X post, 3

Skip X post, 4

End of X post, 4

Bi iroyin naa ti ṣe lu sita

Jose Mourinho ti da akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham, lẹyin ti wọn yọ Mauricio Pochettino ni isẹ.

Akọnimọọgba tẹlẹri fun ikọ agbabọọlu Chelsea ati Manchester United ti bu ọwọ lu iwe adehun ọlọdun marun un 2022 si 2023.

Mourinho ni o dun mọ oun ninu nitori ọpọ igba ni oun ti ma n woye lati je akọnimọọgba fun ẹgbẹ agbabọọlu Tothenham.

Lọpọ igba ni o ti kọ isẹ akọnimọọgba ni orilẹede China, Spain, Portugal lati igba to ti kuro ni Manchester United.

Mourinho n gbe ni ilu London, ti o si ti gba ami ẹyẹ Premier League mẹta ati FA Cup pẹlu ikọ Chelsea, bẹẹ lo si gba Europa League and Carabao Cup pẹlu ikọ Manchester United.