Lionel Messi: Thiago Silva ìwà agọ̀ ló mú Messi sọ fun akọ́nimọ̀ọ́gbá Brazil pé kó gbẹ́nu dákẹ́

Oríṣun àwòrán, Other
Bo tilẹ jẹ pe Messi naa lo gba goolu kan ti ẹgbẹ agbabọọlu Argentina fi bori sawọn.
Ki lo le mu ki agbabọọlu sọ fun akọnimọọgba pe ẹnu rẹ n run?
Gbajugbaja agbabọọlu Barcelona to jẹ ọmọ Argentina lo sọ fun akọnimọọgba Brazil, Tite pe ko yee sọrọ mọ ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹẹsọrẹẹ to waye laarin orilẹ-ede mejeeji lorilẹ-ede Saudi Arabia lọjọ Ẹti.
Messi ati Tite tahun si ara wọn nigba ti ere bọọlu naa si n gbona girigiri, bo tilẹ jẹ pe Messi naa lo gba goolu kan ti ẹgbẹ agbabọọlu Argentina fi bori sawọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Messi kan ṣadeede lọ sẹgbẹ kan lori papa nibi ti Tite wa, nibẹ lo ti fi ika sẹnu to si ni ''fẹẹmu'' fun akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Brazil.
Tite fun ra rẹ ṣalaye pe lootọọ loun ti n ṣaroye fun rẹfiiri pe nipa bi ifẹsẹwọnsẹ ṣe n lọ, ati pe oun ati Messi jọ ni gbolohun asọ nigba ti ipele akọkọ ere bọọlu pari.
Akọnimọọgba Brazil ni o yẹ ki Messi gba kaadi ikilọ yẹlo, lẹyin naa lọ sọ pe ki oun gbẹnu dakẹ, bayii loun sọ fun un pe ko dakẹ ẹnu rẹ.
Ninu ọrọ tiẹ, balogun ẹgbẹ agbabọọlu Brazil, Thiago Silva bu ẹnu ẹtẹ lu ihuwasi Messi si Tite.
O ni iwa ti ko boju mu ni lati sọ pe ki agbalagba gbẹnu dakẹ.
Silva fikun ọrọ rẹ pe alaṣeju ni Messi, oun nikan lo fẹ fọn feere, o fẹ dari ere bọọlu naa, bakan naa lo n ṣe ariyanjiyan pẹlu rẹfiri.
- Irọ́ ni pé wọ́n sèkọlù sí Gómìnà Seyi Makinde - Ọlọ́pàá Kogi
- Àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ ti di dandan fáwọn tó bá fẹ́ ṣèyàwó ní Nàìjíríà- Ilé aṣojú-ṣòfin
- Ilé ẹjọ́ ni agbábọ́ọ̀lù ọmọ Nàìjíríà, Dickson Etuhu jẹ́bi ẹ̀sùn títa ìdíje Sweden
- Àwọn ọmọ Nàìjíríà bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu NTA lórí ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ìdíje bọ́ọ̀lù
- Adigunjalẹ̀ fìbọn fọ́ ojú ọmọ tó fẹ́ lọ sìnrú ìlú nílùú Èkó
- Àgbẹdọ̀! Má kọ̀wé fipò sílẹ̀, àwọn àgbààgbà Yorùbá sọ fún Osinbajo












