NYSC: Adigunjalẹ̀ fìbọn fọ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n lójú nílú Èkó

Oríṣun àwòrán, OTHER
Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan ti padanu oju rẹ mejeji lẹyin ti awọn adigunjale yinbọn lu oju rẹ nilu Eko.
Tom Waziri, to jẹ akẹkọjade Fasiti ipinlẹ Kogi to si n gbaradi lati lọ ṣe eto agunbanirọ ki iṣẹlẹ naa to ṣelẹ si i.
Gẹgẹ bi ọrọ to sọ fun awọn oniroyin, iṣẹ awakọ lo n ṣe pẹlu ileeṣẹ awakọ Bolt nilu Eko.
- Iná iná ṣáá l'Eko! Ọkọ̀ aképo dàwó, iná ṣẹ́yọ ní Gowon Estate
- Ààye wà fún àgunbanirọ láti wọ sòkòtò labúlabú- Ọ̀gá àgbà
- Ẹ̀nh ẹ́ẹ̀nh! Àṣẹ ilé-ẹjọ́ ilẹ̀ òkèrè nìkan ni ìjọba lè pamọ́ ṣùgbọ́n tàpá sí ti Nàìjíríà lórí Sowore àbí?
- Ààye wà fún àgunbanirọ láti wọ sòkòtò labúlabú- Ọ̀gá àgbà
- Toyin Abraham ní 'gbogbo wa loníbárà', Ijebu ta sí Odunlade
Ọjọ kejila oṣu kẹsan an ọdun 2019 ni akọlu naa waye, ti awọn adigunjale ọhun yinbọn fun un, leyii to mu ki ọta ibọn wọ oju rẹ.
Waziri sọ pe, ni igba ti oun n gbe ero ọkọ kan lọ si agbegbe Papa Ajao, to wa ni Mushin, ni nkan bi aago mẹjọ aṣalẹ ni iṣẹlẹ naa waye.
O ṣalaye pe, "Ọkan lara awọn adigunjale ọhun kọ oju ibọn si mi, bi mo ṣe fẹ fun un ni ẹrọ ibanisọrọ mi lo yin ibọn ọhun si mi loju. Lẹyin naa lo gba ẹrọ ibanisọrọ ti wọn si fẹsẹ fẹ."
Lẹyin eyii ni ero ọkọ naa sa jade to si pe fun iranlọwọ, ko to di pe awọn ọlọpaa jade si wọn.









