Wo ibi tí o ti lè ra àpò ìrẹsì tí ìjọba ń tà ní N40,000

Aworan Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, @PBATMediaCentre

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọpọ ọmọ Naijiria ni wọn ti n beere ibi ti wọn ti le ri apo irẹsi ti ijọba apapọ n ta ni N4,000 kaakiri orilẹede Naijiria ti minisita eto iroyin ati ilanilọyẹ, Mohammed Idris, kede igbesẹ ijọba naa.

Idris ṣalaye pe ijọba oun ṣe agbekalẹ awọn igbimọ kaakiri gbogbo ipinlẹ lorilẹede Naijiria lati ṣagbatẹru tita irẹsi naa.

Minisita eto iroyin sọ pe ijọba ti pese fawọn ibudo ti wọn yoo ti maa ta irẹsi ọhun kaakiri orilẹede Naijiria.

Ninu ọrọ rẹ, minisita eto iroyin ṣalaye pe ‘’awọn ẹṣọ eleto abo ti wa nilẹ lati mojuto tita irẹsi naa ti awọn eeyan ko fi ni maa ra a ju N40,000 iye ti ijọba gbe e kalẹ lọ.

Erongba ijọba ni pe awọn ti ko rọwọ họri ni yoo ra irẹsi yii ni ẹdinwo gẹgẹ bi ijọba ti gbe e kalẹ.

A ṣi ti gbe igbesẹ lati ri pe irẹsi yii tẹ awọn ti oṣi n ba a finra ni Naijiria lọwọ.’’

Amọ ṣa, bo tilẹ jẹ pe iroyin ayọ ni eyi jẹ fun araalu, ọpọ eeyan lo ti n sọ pe awọn gomina ipinlẹ ko tii bẹrẹ sii pin irẹsi ti ijọba apapọ sọ pe oun fun wọn lati pin.

Wo ìdí tí ìjọba ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ta àpò ìrẹsì ní N40,000 káàkiri Nàìjíríà

Aworan apo irẹsi

Lọjọ Aje to kọja yii ni ijọba apapọ sọ pe awọn ti ṣi awọn ibusọ kaakiri orileede Naijiria, nibi ti awọn araalu yoo ti maa lanfani lati ra irẹsi aadọta kilogiraamu ni ẹgbẹrun lọna ogoji naira.

Minisita fọrọ eto iroyin ati ilanilọyẹ apapọ, Mohammed Idris lo sọ eyi di mimọ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade awọn alakoso ijọba, eyi ti Aarẹ Bola Tinubu dari rẹ niluu Abuja.

Minisita sọ pe anfaani ti wa fun gbogbo ọmọ Naijiria lati ra irẹsi baagi kan ni ẹgbẹrun lọna ogoji naira, lati mu adinku ba iṣẹ ati oṣi to n ba awọn eeyan finra.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Idris wa rọ gbogbo eeyan lati wọgile ifẹhonuhan to fẹẹ bẹrẹ lọjọ kinni, oṣu kẹjọ, ọdun 2024, to si ni wọn ko nilo rẹ mọ lasiko yii.

O sọ pe “Aarẹ Tinubu ti n fẹhonuhan lati ja fun awọn araalu.”

Bakan naa lo sọ pe gbogbo ohun ti awọn araalu fẹẹ ṣe iwọde le lori ni ijọba ti wa ojutu sii.

“Ibi ti igbimọ alaṣẹ ijọba FEC duro le lori ni pe gbogbo ibeere awọn olufẹhonuhan ni ijọba ti bẹrẹ iṣẹ le lori, ati pe fun idi eyi, wọn ko nilo lati fẹhonuhan mọ.

“Ọpọ ohun ti awọn olufẹhonuhan n gbe siwaju ni ijọba ti ṣiṣẹ le lori. Gẹgẹ bi a si ti n tẹnumọ ọn, ijọba eleti-gbaroye ree.

Minisita ni aarẹ ti gbọ gbogbo ohun ti awọn to fẹẹ ṣe ifẹhonuhan yii n sọ, esi to si fi ranṣẹ ni pe ifẹhonuhan naa ko nilo mọ.

O ni otitọ ni pe aarẹ funra rẹ ti n fẹhonuhan lati ja fun araalu nipa ṣiṣe ohun ti wọn n fẹ ki ijọba ṣe.

O tun jẹ ko di mimọ pe ijọba apapọ ti fi tirela ounjẹ 740 ranṣẹ si awọn ipinlẹ to wa lorileede Naijiria, nibi to ni awọn eeyan yoo ti maa ra baagi irẹsi aadọta kilogiraamu ni ẹgbẹrun lọna ogoji naira lawọn ibusọ ti wọn ya sọtọ.

“Bi apẹẹrẹ, ipade ti a ṣe kọja, a kede wi pe tirela ogun ni awọn gomina ipinlẹ kọọkan gba lati pin fun awọn to nilo rẹ, paapaa awọn alaini lawujọ.

O ni sibẹ, ijọba ko dawọ duro nitori pe ida aadọta ni iye ti ijọba n ta irẹsi si iye to wa.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “awọn irẹsi yii la ti ko lọ sawọn ibusọ ti a ya sọtọ kaakiri orileede yii, ti wọn si n ta a ni ẹgbẹrun lọna ogoji naira.

Lakọkọ, tirela mẹwaa irẹsi ni awọn ipinlẹ kọọkan ti kọkọ gba tẹlẹ lati le pin in fun araalu.”