Ààrẹ Tinubu buwọ́lu àbádòfin N70,000 gẹ́gẹ́bí owó oṣù tuntun f'áwọn òṣìṣẹ́ Nàìjíríà

Aarẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Asiwajubolatinubu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Tinubu, ti buwọlu ofin owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria.

Igbesẹ yii mu gbogbo awuyewuye eyi to ti n rọ mọ ọrọ owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria wa si opin naa lẹyin ọpọlọpọ ijiroro laarin ijọba, ẹgbẹ oṣiṣẹ ati ẹka iṣẹ aladani.

Aarẹ Tinubu buwọlu abadofin tuntun naa ni ile aarẹ to wa nilu Abuja ljọ Aje lẹyin ti awọn aṣofin apapọ buwọlu abadofin sisan ẹgbẹrun lọna aadọrin Naira gẹgẹ bi owo oṣu to kere julọ fun oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria.

Ikọ awọn aṣofin apapọ kan eyi ti aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnetọ Godswill Akpabio ko sodi wa nikalẹ lasiko ti aarẹ n buwọlu abadofin naa.

Ijọba apapọ ati ẹgbẹ oṣiṣẹ fẹnuko si owo oṣu tuntun lẹyin ọpọlọpọ ijiroro

Afikun ti ba owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ bayii lorilẹde Naijiria, ijọba apapọ ati ajọ oṣiṣẹ ti fẹnuko si ẹgbẹrun lọna aadọrin (70,000) naira bii owo oṣu to kere ju ti oṣiṣẹ kan yoo maa gba.

Lati Ọjọbọ, ọjọ kejidinlogun, oṣu Keje 2024 ti ijọba apapọ ti kede afikun yii ni oriṣiriṣi ero ọkan awọn eeyan lori igbesẹ naa ti n jade.

Bawọn kan ṣe n sọ pe bo ti le wu ko ri, ẹgbẹrun lọna aadọrin yii ṣi yatọ si ẹgbẹrun lọna ọgbọn tijọba n san tẹlẹ, ati pe nnkan yoo tun rrun diẹ si i pẹlu ẹkunwo yii, bẹẹ ni awọn mi-in n sọ pe owo ọhun ko le ka nnkan kan.