Ẹ ṣí gbogbo síìmù tí ẹ tì padà - NCC

Wo ìgbésẹ̀ tí o lè gbé láti ṣí síìmù rẹ bí wọ́n bá dèna rẹ̀ láti fi pè

Wo ìgbésẹ̀ tí o lè gbé láti ṣí síìmù rẹ bí wọ́n bá dèna rẹ̀ láti fi pè

Aworan awọn to n ta SIM

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọjọ Aiku to kọja yii, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 2024, ni awọn ileeṣẹ ibanisọrọ kan gbẹsẹ le awọn oju opo ibanisọrọ kan lorilẹede Naijiria.

Eyi jẹ ara igbesẹ to kẹyin lati gbegidina ipe awọn to kọ lati so nọmba NIN wọn papọ mọ siimu wọn.

Titi di asiko yii ni ọpọ araalu n kọminu lori bi awọn ileeṣẹ ibanisọrọ naa ṣe gbegidina awọn nọmba ibanisọrọ awọn onibara wọn, paapaa awọn ti wọn ko tii so nọmba idanimọ NIN papọ mọ siimu wọn.

‘Ki lo ṣẹlẹ’, abi foonu mi ti bajẹ ni’...wọnyi ati awọn ọrọ kayeefi miran lo n jade lẹnu ọpọ awọn onibara MTN, nigba ti wọn ṣakiyesi pe awọn ko le pe jade, bẹẹ si ni awọn ko le yẹ iye owo ku lori siimu wọn, pẹlu awọn nnakn miran.

Inu oṣu kejila, ọdun 2020 ni ijọba apapọ Naijiria paṣẹ fun gbogbo awọn ileeṣẹ eleto ikansira-ẹni bii MTN, Airtel, Glo, Etisalat ati awọn miran lati so nọmba idanimọ (NIN) awọn onibara wọn papọ mọ siimu wọn.

Eyi ni ijọba sọ pe yoo fopin si iwa ijinigbe, iṣẹkupani, igbesunmọmi ati oniruuru iwa ọdaran miran.

Ijọba apapọ sọ pe ki awọn ileeṣẹ eleto ikansira-ẹni yii gbegidina ipe awọn onibara wọn, ti wọn ba kọ lati tẹle ilana laarin gbedeke ọjọ ti wọn fi sita.

Awọn onibara miliọnu mẹtalelaadọrin ni awọn ileeṣẹ eto ikansira-ẹni yii dawọ ipe jade wọn duro, ti wọn ko si tun le ṣe ohun miran.

Igba mẹsan ọtọọtọ ni ijọba apapọ fi wọgile gbedeke ọjọ ti wọn pa a laṣẹ fun awọn ileeṣẹ ikansira-ẹni wọnyi, lati le gba awọn eeyan laaye lati kopa ninu eto naa, iyẹn ṣaaju ọjọ kẹrin, oṣu kẹrin, ọdun 2022

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ naa ni minisita fọrọ eto ikansira-ẹni, Ọmọwe Ali Pantami paṣẹ pe ki wọn bẹrẹ sii gbegidina awọn to ba kọ lati so nọmba NIN wọn papọ mọ siimu wọn.

Bo tilẹ jẹ pe ọjọ karundinlogun, oṣu kẹrin, ọdun 2024 ni ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ikansira-ẹni lorileede Naijiria, NCC sọ pe ohun yoo bẹrẹ sii gbegidina awọn to ba kọ lati so NIN wọn papọ mọ siimu wọn, ṣugbọn ti wọn tun sun un si ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje, ọsun 2024.

NCC sọ pe awọn ti ṣagbeyẹwo iṣoro ti araalu n koju nipa siso NIN wọn papọ mọ siimu wọn, leyi to jẹ ki wọn tun sun gbedeke naa siwaju.

Ṣugbọn ṣa, lọjọ Aiku to kọja, ajọ NCC bẹrẹ igbesẹ ipele to kẹyin ninu eto ati ilana igbegidina awọn onibara lati pe jade lori foonu wọn, leyi to si jẹ pe awọn onibara MTN lo pọ ju.

Ọkan lara awọn alakoso ẹgbẹ to n ṣakoso eto ikansira-ẹni, Association of Licensed Telecom Operators of Nigeria sọ pe kii ṣe awọn onibara MTN nikan ni wọn n koju iṣoro yii, ati pe awọn yoo to o gbe atẹjade sita laipẹ.

Bakan naa ni oṣiṣẹ alẹnulọrọ miran sọ pe awọn ko le ṣa dede bẹrẹ sii gbegidina awọn onibara wọn lati pe jade, bi ko ṣe pe wọn nilo lati so NIN wọn papọ mọ siimu wọn.

Ju gbogbo rẹ lọ, BBC YORUBA ti wa ṣawari awọn ilana lati wa ọna abayọ si iṣoro fun awọn ti wọn ko lanfaani lati pe jade.

Awọn wo ni wọn gbegidina siimu wọn?

Awọn to kọ lati so nọmba idanimọ apapọ wọn, NIN papọ mọ siimu wọn.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn ileeṣẹ eleto ikansira-ẹni yoo maa gbegidina awọn onibara wọn lati pe jade.

Pupọ lo jẹ pe iwa nitori iwa aibikita wọn lo fa a, ti wọn ko fi le pe jade mọ.

Ọpọ igba ni ijọba Naijiria ati ileeṣẹ to n ṣabojuto eto ikansira-ẹni nilẹ yii ti pariwo pe ki awọn araalu lọ so nọmba NIN wọn papọ mọ siimu wọn.

Awọn igbesẹ ti o ni lati gbe

MTN

Oríṣun àwòrán, ninlinking/Web

Bi o ba wa lara awọn ti ileeṣẹ ikansira-ẹni MTN ba gbegidina siimu rẹ lati pe jade, awọn nnkan wọnyi ni o nilo lati ṣe:

Kọkọ wa nọmba NIN rẹ sitosi, ki o si rii daju pe o ni imeeli to n ṣiṣẹ

Lọ soju opo https://ninlinking.mtn.ng

Tẹle ilana lati fi nọmba ẹrọ ibanisọrọ rẹ ati imeeli rẹ soju opo naa ki o to tẹsiwaju

Wọn yoo fi awọn nọmba kan ranṣẹ sori imeeli rẹ, nọmba naa lo maa nilo lati fi tẹsiwaju igbesẹ yii.

O ni lar jafafa ki asiko ma ba a lọ, nitori pe ọgbọn iṣẹju aaya (30seconds) lo ni anfaani lati fi tẹ nọmba ọhun.

Bi o ko ba ri nọmba naa lori imeeli rẹ, tẹ ‘resend OTP’, o daju wi pe wa a ri nọmba ọhun pada lori imeeli rẹ.

Bi o ba ti ṣe eyi, yoo gbe ọ lọ si ipele to kan nibi ti o ti maa tẹ nọmba NIN rẹ sibẹ lati tẹsiwaju.

Lẹyin ti o ba ti fi NIN rẹ sibẹ, o maa nilo lati duro fun igba diẹ ki wọn to le fidi rẹ mulẹ wi pe o ti ṣiṣẹ.

Bi ko ba lọ, o ni lati fi awọn idanimọ rẹ silẹ bii orukọ rẹ, orukọ ti mama rẹ n jẹ tẹlẹ, iye owo ti o ra sori nọmba rẹ gbẹyin, awọn ẹrọ ibanisọrọ ti o maa n pe latigbadegba ati awọn miran.

O ṣee ṣe ki nọmba rẹ ma ṣiṣẹ loju ẹsẹ, o maa nilo lati duro fun bii wakati mẹrin si marun-un ki o to le bẹrẹ iṣẹ pada.

Igbesẹ miran ni pe

O ni lati wa ẹrọ ibanisọrọ miran lati fi pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ikansiraẹni MTN lori 300, ki o si ba wọn sọrọ.

Loju ẹsẹ ni wọn yoo ba ọ ṣii pada.

Bẹẹ si lo tun le *996*NIN# lati fi so NIN rẹ papọ mọ siimu rẹ.

Bi awọn igbesẹ yii ko ba ti wa ṣiṣẹ fun ọ, o ni lati lọ si ẹka ileeṣẹ MTN, tabi awọn ṣọọbu kereje-kereje lati ṣe e.

Ṣugbọn ṣa, bi o ko ba NIN, o ni lati lọ si ọfiisi NIMC lati forukọ silẹ fun un.

Ni ti Airtel

Airtel

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ẹ tẹ *121# lori foonu yin, ki ẹ si tẹle awọn ilana to ba gbe wa fun un yin.

Bi eyi ko ba ṣiṣẹ fun un yin, ẹ lọ soju opo ayelujara Aitel lori www.airtel.com.ng/NIN lati ṣe e lẹkunrẹrẹ.

Bi eyi ko ba si tun ṣiṣẹ bi ẹ ṣe fẹ, a jẹ pe ẹ ni lati lọ si eyikeyi ṣọọbu wọn to ba wa lagbegbe yin.

Fun awọn onibara Glo

Glo

Oríṣun àwòrán, Glo World/Web

Ẹ fi ọkan balẹ, irọrun lo ba de bi wọn gbegedina atipe yin, ẹ ko nilo lati laagun jinna tabi daamu.

Ẹ le tẹ *996# lori foonu yin, ki ẹ si tẹle awọn ilana ti wọn ba gbe wa fun un yin.

Bẹẹ si lẹ le lọ soju opo www.gloworld.com/ng/nin-offer lati ṣe e.

Kí ni àṣẹ tuntun tí àjọ ìbánisọ̀rọ̀ NCC pa lórí ṣíṣí gbogbo síìmù tí wọ́n tì padà?
Fóònù

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Àjọ tó ń mójútó àwọn iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ ní Nàìjíríà, NCC ti darí àwọn iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ láti ṣí ojú òpó àwọn oníbàárà wọn tí wọ́n ti nọ́mbà wọn lópin ọ̀sẹ̀ yìí padà.

Adarí ẹ̀ka ètò ìròyìn àti ọ̀rọ̀ aráàlú NCC, Reuben Mouka ló kéde ìdarí yìí nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́ja Ajé.

NCC ṣàlàyé pé ìdarí yìí ń wáyé látàrí ìpalára tí títi àwọn nọ́mbà náà ti dá sílẹ̀ lẹ́nu ìgbà tí ìgbésẹ̀ náà fi wáyé.

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé ni ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn yabo ẹ̀ka iléeṣẹ́ MTN káàkiri Nàìjíríà láti mọ ìdí tí wọ́n fi ti ojú òpó ìbánisọ̀rọ̀ àwọn àti láti ṣi padà.

NCC kọminú pé láti ìgbà tí àwọn ti ń ké sí àwọn ọmọ Nàìjíríà láti so nọ́mbà ìdánimọ̀ wọn papọ̀ mọ́ síìmù wọn, ọ̀pọ̀ ló kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Wọ́n ní gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kan ni kí wọ́n tètè so nọ́mbà ìdánimọ̀ NIN wọn papọ̀ mọ́ síìmù wọn ní kété tí wọ́n bá ti ṣi fún wọn padà nítorí tí wọn kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, wan tún máa ti nọ́mbà náà padà.

Wọ́n sọ pé ṣíṣí àwọn ojú òpó náà padà jẹ́ ọ̀nà láti fún wọn láàyè díẹ̀ si láti so nọ́mbà náà papọ̀.