Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Lara Olubo, èèkàn akọrin àti òṣèré tíátà tó jáde láyé

Lara Olubo

Oríṣun àwòrán, Instagram/lagoslately_

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajumọ akọrin ẹmi to tun jẹ ilumọọka agbohunsafẹfẹ, aranṣọ ati oṣere tiata, Lara Olubọ ti jade laye.

Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ ni ọjọ Abamẹta ni Arabinrin lara Olubọ jade laye bi o tilẹ jẹ wi pe ko tii si ẹni le sọ ni pato ohun to ṣe okunfa iku rẹ, amọṣa awọn kan to sun mọ ọ n sọ pe, o ti ṣe diẹ ti o ti wa ninu aarẹ.

Ta ni Lara Olubọ?

Gbajumọ atọkun eto lori afẹfẹ ni arabinrin Olubọ. O si jẹ ẹni ti ọpọ awọn eeyan to n wo mohunmaworan Orisun ko le tete gbagbe nibi to ti n ṣe atọkun awọn eto bii Miliki Express, Eto Baba Eto ati Oju Ọja.

Awọn eto wọnyii mu u ko di ilumọọka kaakiri.

Bakan naa lo tun jẹ eekan elere tiata ati sinima nibi to ti kopa ninu ọpọlọpọ awọn sinima agbelewo lede Yoruba.

Ki lawọn eeyan n sọ lori itakun ayelujara

Ọkanojọkan awọn eeyan to mọ oloogbe naa nigba aye rẹ ni wọn ti n daro iku rẹ paapaa lori itakun ayelujara gbogbo.

Pupọ lara wọn bii @yemiterry, @wumitoriola, @iameyinjueledumare_, @itz_temmykiss lo kẹdun igbe aye to ni ipa ti wọn ni oloogbe naa gbe.

Bẹẹni awọn miran gba ladura ki eleduwa tẹ ẹ si afẹfẹ rere.