Wo ọ̀nà tí o fi lè bọ́ lọ́wọ́ àrùn jẹ̀dọ̀-jẹ̀dọ̀ 'Hepatitis'
Awọn ti wọn ni arun 'Hepatitis C' ni Naijiria to miliọnu mẹrin lọdun 2019.
Dokita fi ye eto BBC ''La a han mi'' pé abẹrẹ ajẹsara maa n dena Hepatitis A ati B ṣugbọn ko si eyi to le dena C
Bakan naa ni Dokita ṣalaye awọn ọna ti eeyan fi le ko arun jẹdọjẹdọ yii lawujọ.
Ni afikun, Dokita Afeez ṣalaye ni kikun lori awọn ọna ti eeyan ko fi le ko arun jẹdọjẹdọ yii ati nipa ki a maa ma dẹyẹsi awọn to ti nii.
Imọ toto lo le bori arun gbogbo ninu ile, lẹnu ounjẹ, fun itọju ara ati gbigba abẹrẹ ajẹsara lasiko le dena awọn arun kọọkan.