Wo ìkìlọ̀ tí ọmọbìnrin ààrẹ Nàìjíríà Folasade Tinubu-Ojo ṣe fáwọn ìyálọ́jà lórí ìwọ́de tó ń bọ̀

Oríṣun àwòrán, Iyaloja General/Youtube
Iyalọja gbogbogbo niluu Eko, Arabinrin Folasade Tinubu-Ojo ti gba gbogbo obi ati alagbatọ lamọran lati tọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ nipa ifẹhonuhan ti wọn n gbero lati ṣe, bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024.
Tinubu-Ojo lo sọrọ naa ninu fọnran kan to gbe soju opo ayelujara rẹ, eyi to n tan kaakiri, lasiko abẹwo to ṣe lọ si ọja Dosumu nipinlẹ Eko lọjọ Abamẹta to kọja.
Obinrin naa to jẹ ọmọ Aarẹ Bola Tinubu sọ pe ko sohun to n jẹ ifẹhonuhan, bi ko ṣe pe awọn kan lo n dọgbọn lati dabaru gbogbo eto ijọba lori idagbasoke ati ilọsiwaju ilu.
Bakan naa lo tẹnumọ ọrọ rẹ pe awọn oloṣelu kan ni wọn n ṣagbatẹru ifẹhonuhan ọhun lati le ba dukia ti ijọba n fowo ilu tun ṣe jẹ, to si ni awọn ni jẹ ki ohun to ṣẹlẹ lasiko ifẹhonuhan ENDSARS tun ṣẹlẹ lasiko yii.
Ninu ọrọ rẹ, Iyalọja General sọ pe “ẹ jẹ sọ fun awọn ọmọ wa nile, ka sọ fun awọn mọlẹbi wa wi pe ko si nnkan to n jẹ ifẹhonuhan, afọgbọn balujẹ ni.
Bi ẹ ba wo eyi ti wọn ṣe kọja, ẹ wo gbogbo nnkan ribiribi ti ijọba ṣe, ti wọn lọ dana sun.
“Awa la n fa ara wa sẹyin, nitori ẹgbẹ oṣelu kan n ko owo fun awọn kan lati lọ ja, ẹ ma ṣe jẹ ki awọn ọmọ wa tori bọ ọ, ki wọn wa fori jona.
“Ile itaja Shoprite to wa ni Adeniran Ogunsanya, eyi to wa ni Sangotedo ati ni Lekki ti wọn sọna si, awọn ọlọja to fara ko o ko kere, wọn ko si tii dide pada latigba naa.
“Ẹ dakun, ẹ jẹ ka ba ara wa sọrọ, ka ba awọn ọmọ wa sọrọ wi pe ko si nnkan to n jẹ ifẹhonuhan nipinlẹ Eko, nitori pe gomina ipinlẹ Eko n wu wa lori, wọn si n mu inu wa dun.
“Fun idi eyi, ẹ jẹ ka maa sọ fun gbogbo eeyan pe ijọba ipinlẹ Eko n ṣe wa daadaa. Ijọba apapọ ṣẹṣẹ debẹ ni, ki ẹ to le sọ pe ijọba kan ko ṣe daadaa, ẹ jẹ ko lo ọdun mẹta.
Iyalọja General tun fi kun ọrọ rẹ pe bi ọja ọlọja kan ba jona, ẹlomiran wa to jẹ pe lati dide pada di ọwọ Ọlọrun, to si ni ohun to ṣe pataki julọ ni ki lati dena ajalu to ṣee ṣe ko tẹyin rẹ yọ.
''A ko fẹ ki ohun to ṣẹlẹ lasiko ifẹhonuhan ENDSARS nipinlẹ Eko tun waye''
“A ko fẹ ki ohun to ṣẹlẹ lasiko ifẹhonuhan ENDSARS nipinlẹ Eko tun pada waye, nitori pe o mu ifasẹyin wa fun wa, ọpọ okowo ati nnkan ti ijọba kowo le lori ni wọn bajẹ.
“A le fẹhonuhan, ka fi ẹdun ọkan wa han, awọn ọna to dara wa lati ṣe awọn nnkan wọnyi, koda bi awọn to fẹẹ fẹhonuhan ba ni erongba rere, ẹ jẹ ka wo ti awọn janduku ti wọn fẹẹ lo anfaani ẹ lati ba nnkan jẹ.
“A ko fẹ iru nnkan bayi, ijọba si n gbiyanju lati wa ọna ti ifẹhonuhan ọhun yoo gba waye lai faaye gba awọn janduku lati gba a mọ wọn lọwọ. A n rawọ ẹbẹ si awọn obi ati awọn ọmọ wa wi pe ki wọn ṣi ṣe suuru,'' Tinubu-Ojo ṣalaye.
Bẹẹ naa lo sọ pe ko tii pẹ ju, nitori pe ijọba n gbiyanju agbara rẹ lati rii pe wọn wa ọna abayọ si wahala ebi ati iyan ti araalu n pariwo.
O ni ko sẹni ti ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria lasiko yii ko kan, to si ni bo ṣe kan mẹkunnu naa lo kan awọn olowo ati ọlọrọ.
















