Ikú dóró, Sénétọ̀ Ifeanyi Ubah jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Ifeanyi Ubah/X
Ọkan lara awọn aṣofin agba nilẹ igbimọ aṣofin agba lorilẹede Naijiria, Sẹnetọ Ifeanyi Ubah ti jade laye lẹni ọdun mẹtalelaadọta.
Sẹnetọ Ubah lo jade laye niluu London, nibi to ti lọ gba itọju, gẹgẹ bi ọkan lara awọn mọlẹbi ti ko fẹẹ darukọ ara rẹ ṣe ṣalaye fun BBC.
Sẹnetọ Ubah lo n ṣoju ẹkun Anambra South Senatorial District nile igbimọ aṣofin agba orileede Naijiria ko to di pe ọlọjọ de.
Ọdun 2019 ni wọn dibo yan Ubah gẹgẹ bii Sẹnetọ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Young Progressive Party, YPP, ti wọn si tun dibo yan an lẹẹkeji labẹ ẹgbẹ oṣelu kan naa.
Ni ibẹrẹ ọdun yii ni Ubah darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC, to si fi erongba rẹ han lati jade du ipo gomina ipinlẹ Anambra ninu eto idibo to n bọ lọdun 2025.
Àwọn ohun tó yẹ́ kí o mọ̀ nípa Ifeanyi Ubah
Ifeanyi Uba jẹ gbajugbaja lẹka eto okoowo pẹlu ileeṣẹ Capital Oil Corporation.
Inu oṣu Kẹsan, ọdun 1971 ni wọn bi i, to si jẹ akọbi ninu awọn ọmọ meje ti baba rẹ, Alphonsus Ubah bi.
Ubah ti fẹ iyawo, o si ni ọmọ marun-un.
Agbegbe Otolo, ilu kekere kan nipinlẹ Anambra lo ti jade.
O lọ sile-ẹkọ Premier Academy Lugbe to wa ni Abuja, ṣugbọn ko pari rẹ nitori ailowo lọwọ awọn obi rẹ lati ran an nile ẹkọ.
O lọ si oriṣiriṣi idanilẹkọ nipa okoowo, ileeṣẹ ati ijọba.
Ọdun 2001 ni Ifeanyi da ileeṣẹ rẹ, 'Capital Oil' silẹ.
Bakan lo tun jẹ pe oun lo ni ẹgbẹ agbabọọlu Ifeanyi Ubah FC, ti wọn jẹ Gabros International Football Club, ti wọn si n kopa ninu idije ati ifẹsẹwọnsẹ ilẹ Naijiria, iyẹn Nigeria Premier League.
Ẹgbẹ oṣelu Labour Party ni Ifeanyi Ubah ba jade lati du ipo gomina ipinlẹ Anambra lọdun 2014, ṣugbọn to padanu.
Lọdun 2019, Ubah jade du ipo aṣọfin agba lati ṣoju ẹkun Anambra South Senatorial District labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Young Democratic Party (YPP).
Ajọ eleto idibo, INEC kede rẹ lọdun 2019 gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori pẹlu ibo ọgbọn.















