Kí ló dé tí àwọn ọmọ Nàìjíríà fẹ́ ṣe ìfẹhonúhàn lẹ́yìn tí wọ́n ti mú ọ̀pọ̀ wọn si àhámọ́?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Yusuf Akinpelu
- Role, West Africa Journalist
- Reporting from, Lagos
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Khalid Aminu n mura lati jade lọ fun eto redio kan ni Kaduna nigba ti awọn ọlọpaa mẹta wa sinu yara ile itura ti wọn gbe e lọ fun ifọrọwanilẹnuwo.
O sọ pe oun wa ni atimọle fun bii wakati mẹfa, ti wọn si n bere awọn ibeere nipa ipolongo ti o n dari nipa ero lati se ifẹhonuhan bẹrẹ lati ọjọ kinni Oṣu Kẹjọ.
Ọpẹ lopẹ agbẹjọro rẹ to dasi ọrọ naa ko to di pe o gba itusilẹ, o sọ.
“Emi yoo kopa ninu ehonu naa sibẹsibẹ,” o sọ fun BBC.
Bii tirẹ, oṣere ori TikTok, Junaidu Abdullahi (Abusalma) lati ilu Kano wa ni atimọle fun bii ọjọ mẹfa lẹyin ti o ṣe fidio kan, eyi to ti yọ kuro bayii, ni bi to ti n ke pe awọn eeyan lati tako ẹnikẹni to ba lodi si ifẹhonuhan ti wọn fẹ fi tako ijọba. O gba itusilẹ lẹyin ọpọ igbinyanju, ti wọn si ki nilọ pupọ gẹgẹ bii ohun ti agbẹnusọ rẹ ṣalaye.
“Fifi ofin mu awọn eeyan ni ko yẹ ko jẹ ohun pataki fun awọn alaṣẹ Naijiria ni akoko yii ti ebi n pa ọpọ awọn eeyan lorilẹede Naijiria ,” Amnesty International sọ sita.
Akọle “End Bad Governance in Nigeria”, awọn ajafitafita bii Ọgbẹni Aminu ti n ko awọn eeyan jọ lati se iwọde, ti wọn si n bere nnkan lọwọ ijọba bii fi fun ni ni eto-ẹkọ ọfẹ, wiwa ojutu si eto aabo, kikede ilu o fararọ lori ọwọngogo, ati ṣafihan owo oṣu awọn aṣofin.
Aare Bola Tinubu ti rọ awọn ọdọ lati ma ṣe darapọ mọ awọn ehonu nitori awọn ti ko fẹran ilu lo n ṣe bẹ.
Ọpọ awọn araalu ni ko ti finu tan Aarẹ nigba ti o kede pe ijọba ko ni san owo iranwọ epo bẹntiroolu mọ ati to si tun se afikun owo ina mọnamọna.
Eyi, pẹlu jija owo naira walẹ nii ẹẹmeji laarin ọdun kan, jẹ ki ọwọngogo de ba ounjẹ ati eto iriina.
Aarẹ Tinubu sọ pe awọn atunṣe jẹ ifọkansi lati ki awọn ara oke okun wa dokowo ati lati mu atunse ba eto ọrọ aje to mẹhẹ. Ṣugbọn igbesẹ yii sọ ọpọ di nnkan mii ti ebi si gbode.
Kudiẹkudiẹ eto aabo , paapa ni apa ariwa orilẹede Naijiria ti lẹ awọn agbẹ wọle, ti ọwọngogo si ti de ba ounjẹ.
Iye awọn ounjẹ bii iresi, ewa,tomati, anamọ ati iṣu ni o ti le ku ni ida 250% laarin Oṣu Karun ọdun 2023 si Oṣu Karun ọdun 2024, ni ibamu si ọfiisi awọn iṣiro ti orilẹ-ede. Eyi to fa ibinu kaakiri.
Aarẹ ti beere akoko diẹ sii lati ṣe awọn eto lati wa oju si iṣoro “to n dojukọ eeyan” rẹ ati pe o ti buwọlu owo oṣu tuntun to kere ju to jẹ 70,000 naira ($ 44) fun awọn oṣiṣẹ, to si n n duro de ifọwọsi rẹ lẹyin ti ile-igbimọ aṣofin ti buwọlu. Awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin tun gba lati da owo osu wọn ni idaji fun oṣu mẹfa.
Ijọba orilẹede Naijiria tun kede ipinpin awọn toonu ounjẹ fun awọn ipinlẹ, idasilẹ eto ẹya owo fun awọn akẹkọọ ile ẹkọ, idaduro owo-ori lori awọn ounjẹ ti a n wọle lati ilu okeere ati ifilọlẹ ile-iṣẹ tuntun kan ti yoo n fi gaasi rọpo epo bẹntiroolu fun ọkọ ati awọn igbesẹ mii

Oríṣun àwòrán, Getty Images
N jẹ se iwọde yii ko ni da bi iwọde ENDSARS ọdun 2020?
Ẹwẹ, pẹlu gbogbo igbesẹ yii awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lero pe gbogbo nnkan yii ko ti to lati tan iṣoro kudiẹkudiẹ to gbode.
Wọn sọ pe oloṣelu ko gbe igbesẹ kankan lori nnkan ti awọn araalu n bere fun.
Wọn fẹ ki ijọba ge awọn minisita rẹ , ko si fi ọpọ owo kun owo oṣu awọn oṣiṣẹ, ko si jawọ ninu erongba pe o fẹ ọkọ nla ati ọkọ ofurufu ti wọn fẹ ra fun ileeṣẹ Aarẹ.
Bakan naa ni awọn kan tun lero pe ijọba ko ti gbe igbesẹ to yẹ lati tako iwa siṣe owo ilu mọkumọku, nitori minisita to n risi ẹka ijọba to n tan iṣoro iṣẹ ni wọn fẹsun kan pe o ṣe owo mọkumọku.
Ọgbẹni Aminu sọ fun BBC pe oun n lewaju fun ipolongo iwọde ni oju aye ati lori ayelujara fun iwọde ti yoo fun awọn araalu ni anfani lati sọ ọrọ ẹnu sita tako ijọba buburu lori awọn igbeṣẹ ti awọn gbagbọ pe o n ni araalu lara.
Ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria kilọ pe ki awọn ọmọ Naijiria ma wo awọkọsẹ ohun to waye ni orilẹede Kenya, o sọ pe o ṣee ṣe ki awọn ọmọ orilẹede Naijiria gba awokose lati ọdọ awọn ọdọ Kenya ti wọn n ke fun pe ki Aare William Ruto kọwe fipo silẹ, to ni lati yi erongba rẹ nipa lori afikun owo ori pada , to si tun fọwọ osi juwe ile fun awọn eeyan to wa ni isejọba rẹ.
"Awọn ẹgbẹ kan ti ko awọn eeyan jọ lati da wahala silẹ lorilẹede lori pe wọn ṣe irufẹ nnkan to waye ni Kenya.” Ọgbẹni Egbetokun sọ.
Iwọde to waye gbẹyin lorilẹede Naijiria to lagbara ju lo waye ni ọdun mẹrin sẹyin, iwọde to tako idunkoko ẹka ileeṣẹ ọlọpaa lori iṣekupani ati awọn ẹsun mii
Iwọde EndSars ṣe aṣeyọri ipe rẹ lati tuka ẹka ileeṣẹ ọlọpaa naa ka sugbọn ọpọ ajalu lo waye lasiko iwọde naa si awọn araalu

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn wo ni olori fun iwọde yii?
Lọwọ yii, irinajo iwọde yii ni ko ni olori , ọpọ gbagbọ pe eyi waye nitori ki awọn alaṣẹ ma le mu awọn eeyan tabi ki wọn le yi ero wọn pada.
Ṣugbọn Ọgbẹni Aminu sọ pe nigba ti ko si awọn oludari, awọn alakoso wa.
“Ọpọlọpọ awọn eto lo wa ;ati jẹ erongba yi pada,” o sọ. "Eyi ni idi ti gbogbo awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti o ni imọran daradara nilo lati jade lati fọwọsowọpọ ."
Omoyele Sowore, oludije fun ipo aarẹ tẹlẹ, naa ti n ko awọn eeyan jọ fun iwọde “Ọjọ Ibinu”, to si ti n pin iwe kiri fun awọn araalu.
Awọn oṣiṣẹ ijọba kan ni ileeṣẹ aarẹ ti fi ẹsun kan awọn oloselu alatako bii Ọgbẹni Sowore ati oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi pe wọn n se atilẹyin fun iwọde to fẹ waye ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party si ti fesi pada pe ọrọ ko ri bẹ.
Ẹwẹ, minisita fun iroyin, Mohammed Idris ti gbiyanju lati yii ero iwọde pada nigba to n sọ pe awọn ti n ṣe iwọde naa jẹ“ mọlẹbi wa ni ọkunrin ati obinrin ni wọn”.
"Eyi jẹ ọrọ idile Naijiria ati pe gbogbo wa n wo ọrọ yii daradara, a nireti pe alaafia yoo bori ni opin rẹ," o sọ.
Awọn ehonu ti o kọja bii EndSars ti pada ja si wahala llaarin awọn olufẹhohunhan ati ileeṣẹ alaabo.
Ọgbẹni Tinubu sọ pe gẹgẹ bi alatako, oun ti lewaju fun iwọde - ṣugbọn o jẹ iwọde alaafia.















