Ẹ wá forúkọ àti ìdánimọ̀ yín sílẹ̀ - Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá sọ fún àwọn olùfẹ̀hónúhàn

Oríṣun àwòrán, Nigria Police/X
Ọga agba pata fun ileeṣẹ ọlọpaa orileede Naijiria, Kayode Egbetokun ti pe gbogbo awọn ti wọn n gbero lati ṣe iwọde ifẹhonuhan ti yoo bẹrẹ lọjọ kinni, oṣu Kẹjọ tete wa fi orukọ ati idanimọ wọn silẹ.
Egbetokun lo sọrọ yii lọjọ Ẹti, ọsẹ yii lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja, nibi to ti jẹ ko di mimọ pe awọn naa ti n gbaradi fun eto aabo to pe ye lori iwọde ọhun.
Ọga ọlọpaa sọ pe ki gbogbo ẹgbẹ, ajọ ati awọn to n gbero lati kopa ninu iwọde fi orukọ silẹ ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa to ba sunmọ wọn, lati le mọ iru eeyan ti wọn jẹ.
Siwaju sii lo sọ pe ẹtọ araalu ni lati fi ẹhonu wọn han nipa kikorajọ soju kan, ati pe wọn gbọdọ ṣe ẹ pẹlu alaafia lai si iwa jagidijagan.
“Awa naa fidi ẹtọ araalu labẹ ofin mulẹ nipa iwọde ifẹhonuhan alalaafia.
“Ṣugbọn ṣa, lati le daabo bo dukia ati ẹmi araalu, a rọ gbogbo awọn ẹgbẹ ti wọn n gbero lati kopa ninu iwọde ifẹhonuhan naa lati lọ fi orukọ ati idanimọ wọn silẹ lọdọ ọga ọlọpaa to wa ni ipinlẹ wọn, nibi ti iwọde yoo ti waye.
“Lati le ṣagbatẹru iwọde ifẹhonuhan alalaafia ti ko nii mu ipalara dani, ki wọn lọ fi awọn nnkan wọnyi silẹ: ipinlẹ ti wọn ti fẹẹ ṣe e ati ibi ti wọn yoo korajọpọ si; igba ati asiko ti wọn yoo fi ṣe e; orukọ ati idanimọ awọn adari olufẹhonuhan ati awọn alagbatẹru.”
Bakan naa lo tun fi kun ọrọ rẹ pe awọn fẹẹ tete mọ awọn to n gbero lati da iwọde ọhun ru, lojuna lati le tete ko wọn pamọ.















