Wo kókó méje tí o lè fojú sọ́nà fún nínú ayẹyẹ ìṣíde 2024 Olympics tí yóò wáyé lónìí nílùú Paris

Aworan odo ati oko oju-omi

Oríṣun àwòrán, Paris 2024/Florian Hulleu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ko din ni ẹgbẹrun mẹwaa olukopa ninu ere idaraya ni yoo yan bi ologun lonii ọjọ Ẹti nibi ayẹyẹ ìṣíde 2024 Olympics niluu Paris, ti i ṣe olu ilu orilẹede France.

Ko si ẹni to le sọ pato bi ayẹyẹ naa yoo ṣe ri tori ọpọ nkan ni ko tii han sita lori ayẹyẹ ọhun.

Ni irọlẹ oni ọjọ Ẹti ni ayẹyẹ naa yoo waye, eleyii ti yoo si waye fun wakati mẹrin gbako.

Wọnyi l'awọn koko ti o le foju sọna fun nibi ayẹyẹ iṣide 2024 Olympics naa:

1. Ayẹyẹ iṣide Olympics yii ko ni waye ninu papa iṣere

Aworan odo ati oko oju-omi

Oríṣun àwòrán, Paris 2024/Florian Hulleu

Fun igba akọkọ, ayẹyẹ iṣide Olympics ko ni waye ninu papa iṣere.

Laarin ilu ni ayẹyẹ iṣide 2024 Olympics yoo ti waye.

Awọn olukopa ninu idije Olympics yoo ṣafihan bawọn oludije yóò ṣe maa yan lori odo Seine ninu ọkọ oju-omi ti ẹgbẹrun l'ọna odunrun un eeyan yoo si lanfaani lati wo wọn.

Awọn oludije yoo yan niwaju awọn ibi to ṣe pataki bii ile ijọsin Notre-Dame cathedral, ile iko nnkan iṣẹnbaye si Louvre, Place de la Concorde, Invalides ati Eiffel Tower.

2. Ilu ti ina ti n tan yinrin-yinrin

Ọkọ oju-omi t'awọn oludije wa ninu rẹ yoo kọja labẹ awọn afara nla nla kan nibi ayẹyẹ iṣide 2024 Olympics.

Ayẹyẹ naa yoo pari si apa guusu ilu Paris nigba ti oorun ba rọ.

3. Kamẹra lori ọkọ oju-omi

Awọn alakoso idije 2024 Olympics ti so pe awọn ti ṣeto fun bi kamẹra yoo ṣe wa lori gbogbo ọkọ oju-omi lati le maa gbe oju awọn oludije daadaa fáwọn oluworan lati ri.

Ọpọ ọkọ oju-omi lo ti wa nilẹ ti yoo gbe awọn oludije lasiko ayẹyẹ iṣide idije Olympics 2024.

Amọ, awọn oludije ti wọn yoo gbe asia orilẹede wọn lọwọ ni kamẹra yoo maa gbe oju wọn julọ.

4. Oniruuru akọrin ni yoo ṣere

Ko din ni ẹgbẹrun mẹta awọn amuludun to fi mọ awọn akọrin ati irinwo onijo ni yoo dawọn eeyan lara ya nibi ayẹyẹ ọhun.

Gbajugbaja akọrin R&B un ni, Aya Nakamura ti o n fede Faranse kọrin ni a gbọ pe o ṣee se ko kọrin nibi ayẹyẹ naa.

Ko si ẹni to mọ awọn olorin yoku ti yoo ṣere nibi ayẹyẹ iṣide idije 2024 Olympics naa.

Awọn ilumọọka akọrin bi Celine Dion ati Lady Gaga l'awọn eeyan tun n sọ pe awọn naa yoo sere nibi ayẹyẹ ọhun.

5. Tana-tana aramanda

Aworan tanatana

Oríṣun àwòrán, IOPP/Getty Images

Ina idije Olympics rinrin ajo lati Paris tii ṣe olu ilu orilẹede France lọ si orilẹede Greece.

Ninu irin-ajo yii to bẹrẹ ni bii oṣu mẹta sẹyin, ina Olympics yii rinrin ajo lori ọkọ oju-omi to tobi julọ lagbaaye - Stampfli Express.

Amọ, ko si ẹni to mọ ẹni ti yoo tan ina 2024 Olympics yii.

Ogbontarigi abẹṣẹkubiojo Muhammad Ali lo tana Olympics ọdun 1996 ni Atlanta, nigba ti elere-ije Cathy Freeman tan ina idije Olympics ọdun 2000 niluu Sydney.

Ilumọọka agbabọọlu, Thierry Henry naa wa lara awọn gbajumọ to ti tan ina Olympics ri.

6. Oniruuru aṣọ alaranbara

Aworan awon oludije

Oríṣun àwòrán, Stella Jean/Eugenio D'Orio

Aṣọ yoo maa pe aṣọ ránṣẹ nibi ayẹyẹ iṣide idije Olympics ọdun 2024 oni.

Ikọ oludije orilẹede USA ati Great Britain yoo wọ aṣọ ti Ralph Lauren ati Ben Sherman ran.

Awọn alakoso idije Olympics yii sọ pe oniruuru aṣọ bii ẹgbẹrun mẹta lo wa nilẹ fun ayẹyẹ iṣide idije Olympics ati ti Paralympics.

7. Oniruuru ilumọọka elere idaraya

Ara awọn ohun to yẹ ki ẹ foju sọna fun nibi ayẹyẹ iṣide 2024 Olympics irọlẹ oni ni awọn oniruuru ilumọọka elere idaraya.

Bakan naa ni awọn olori orilẹede jankan jankan at'awọn alẹnulọrọ yoo wa nibi ayẹyẹ naa.

Ileeṣẹ iroyin Reuters sọ pe o le ni ọgọrun olori orilẹede ti yoo wa nibi ayẹyẹ ọhun.

Aya aarẹ Amẹrika, Jill Biden ati aarẹ Javier Milei orilẹede Argentina wa lara awọn alejo pataki ti yoo wa nibi ayẹyẹ naa to fi mọ Aarẹ Emmanuel Macron orilẹede France, ati adari idije Olympics, Thomas Bach.