Èdè àìyedè míì bẹ́ sílẹ̀ láàrín ìjọba Oyo àtàwọn afọbajẹ lórí ẹni tí yóò joyè Alaafin

Oríṣun àwòrán, Collage
Ede aiyede mii tun ti n rugbo bọ bayii lori ọrọ ọba jijẹ nipinlẹ Oyo, eyii ti ko ṣeyin yiyan Alaafin tuntun.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2021 ni Alaafin Ọba Lamidi Adeyemi waja, ti wọn ko si tii yan ọba mii lẹyin eto isinkun rẹ.
Lati igba naa wa ni awuyewuye ti n waye lori ẹni ti ipo Alaafin kan.
Ṣaaju ni awọn afọbajẹ, ti ọpọ mọ si Oyomesi ti kọkọ gba ile ẹjọ lọ lati fofin de gomina Seyi Makinde ko ma le kọ ẹni ti wọn fọwọ si, iyẹn Ọmọba Lukman Gbadegesin, ti wọn ti kọkọ yan lẹyin ipade wọn to waye ni ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023.
Ile ẹjọ ti awọn Oyomesi gba lọ yii ti fa họwuhọwu laarin wọn ati gomina Makinde.
Amọ lẹnu lọlọ yii ni iroyin gbode pe ijọba Oyo ti bẹrẹ igbesẹ tuntun lati yan ọmọ oye lati le ri daju pe ẹni ti oye ọba naa tọ si lo gori itẹ.
Ileeṣẹ iroyin Punch jabọ pe kọmiṣọna to n ri si ọrọ oye jijẹ, Ademola Ojo sọ pe “igbesẹ tuntun lati yan ọmọ oye yoo bẹrẹ laipẹ.”
Ko si igbesẹ lati yan ọmọ tuntun - Oyomesi
Ẹwẹ, BBC Yoruba kan si Oloye Akinade Ayoola, to jẹ Bashorun ilu Oyo ati olori awọn Oyomesi, o ni ko si ohun to jọ bẹ.
O ni “irọ ni, ko si igbesẹ tuntun lati yan ọmọ oye.”
Wayi o, agbẹjọro awọn Oyomesi ti sọ pe awọn ko ni gba ki ijọba bẹrẹ igbe tuntun lati yan ọmọ oye lodi si igbesẹ ti awọn ti gbe ṣaaju.
Agbẹjọro Oyomesi, Kunle Sobaloju ti kọ lẹta si gomina Seyi Makinde pe ko jawọ ninu igbeṣe ọhun.
Igbeṣe naa lo waye lẹyin ti iroyin gbode pe Makinde ti fẹ bẹrẹ igbesẹ tuntun lati yan ọmọ oye.
Sobaloju gba gomina niyanju pe ko maṣe dawọ le ohunkohun ti yoo ṣe akoba fun awọn ẹjọ to ti wa nile ẹjọ lori ọrọ ọhun.
Eeyan mejilelọgọrin ni Oyomesi ṣe ayẹwo fun ṣaaju ki wọn to fontẹ lu ọmọba Lukman Gbadegesin, ti wọn si fi orukọ rẹ ṣọwọ si ijọba.
Amọ lẹyin ti mẹta ninu awọn Oyomesi tako Gbadegesin ni ijọba sọ pe ki wọn bẹrẹ igbesẹ tuntun lati yan ọmọ oye.















