Kí ló dé tọ́mọ Nàìjíríà ń gba àdúrà fún àṣeyọrí Iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń fọ epo?

Awọn ileese afọpo Dangote

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Mansur Abubakar
    • Role, BBC News, Kano, Nigeria
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Adura kan waye ni oṣu diẹ sẹyin ni Kano, ilu ẹlẹsin ni apa ariwa Naijiria.

Won se eto akanse adura fun aseyọri ileese afọpo tuntun pe titi osu to n bọ yoo bere si ni maa pese epo fun igba akọkọ.

Gbigbadura fun iru ileeṣẹ yii ni o le dabi awada, ṣugbọn ọpọlọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni ireti pe ileeṣẹ afọpo ti Dangote ni yoo se anfani meji, yoo jẹ ki epo bọ janburata ti yoo si tun mu adinku ba iye owo epo to ga soke.

Ileeṣẹ yii ni wọn fi owo toto $19bn (£ 15bn) da silẹ, to wa eti okun nipinlẹ Eko, ni guusu orilẹ-ede Naijiria, lo fẹ bi paapa iṣere bọọlu afẹsẹgba ẹgbẹrun mẹrin.

Kikọ ileeṣẹ yii lo bẹrẹ pada ni ọdun 2016, to si bẹrẹ si ni ma pese epo Diesel ati epo ọkọ ofurufu ni Oṣu Kini ọdun yii. Epo bẹntiroolu ni o kan bayii lati tẹle.

Ireti ni pe ileeṣẹ yoo fopin si igbẹkẹle Naijiria lori gbigbe epo rọbi wọle lati oke okun.

Pẹlu bi Naijiria ṣe jẹ olupilẹṣẹ epo robi ti o tobi julọ ni ilẹ Afirika, ti a si wa ni ipo kẹdogun 15th ni agbaye to ni epo, ko si ọkan ninu awọn ijọba ti o ni ileeṣẹ to n fọ epo naa.

Olowo ile Afirika, Aliko Dangote ti kọ ileeṣe Dangote to jẹ aladani.

Dangote ni wọn bi ni Kano, ẹni ọdun 67 ni apapọ owo rẹ jẹ $ 12.6bn (£ 9.7bn), gẹgẹ bi iwe iroyin Forbes se gbe sita.

Ileeṣẹ rẹ , Dangote Group, o ko ọpọ owo jọ latara tita simẹnti tita ati suga ṣaaju ki o to mu ohun ti ọpọlọpọ sọ pe o ti ri ipenija nla julọ sugbọn sibẹsibẹ o ṣe ifilọlẹ ileeṣẹ naa.

Aworan Aliko Dangote

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Eto adura laipe yii ni ilu Kano ni eni to ni ile itaja kan, Lado Danladi seto, ti won si se ni mosalasi kan to wa nitosi. Diẹ ninu awọn olutaja adugbo rẹ darapọ mọ ọ.

"Mo n ṣiṣẹ ni ile itaja ti mo ti n ba awọn eeyan fina sori foonu, lojoojumọ mo ra epo petirolu dọla marun un fun ina mọnamọna nitori ko si ina mọnamọna," Ọgbẹni Danladi sọ. “Ṣugbọn lati igba ti mo ti gbọ nipa ileeṣẹ afọpo Dangote ni mo ti n gbadura fun aṣeyọri rẹ.

"N ko le ṣe iṣiro awọn wakati ti mo ti padanu lati ri epo ra lasikọ to wọn yii, nitori naa mo ni ireti pe ileeṣẹ yii yoo fopin si ijiya, ti yoo si ṣe iranlọwọ fun awọn iṣowo kekere bi temi lati ra epo ni rọrun."

Akẹgbẹ ontaja to wa ni ẹgbẹ Ọgbẹni Danladi, oluta ẹran, ati olutaja ohun mimu naa ni wọn fi ẹdun ọkan ha nipa rira ọwọngogo epo lati tan ina mọnamọna.

Fun ọpọ ọdun, awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria gbadun idiyele owo epo. Ṣugbọn ni ọdun to kọja ni Aarẹ Bola Tinubu fopin si sisan owo iranwọ epo, o ni wọn ko le san owo naa mọ. Eyi lo fa ti ọwọngogo fi gbode ni ilọpo mẹrin.

Eyi lo fa ti ọpọ ọkọ ayọkẹlẹ fi wa ni ile epo, ti ileeṣẹ to n risi epo rọbi lorilẹede si ṣekilọ pe ki awọn araalu ma se ra epo pamọ.

Ipo naa ko ṣe iranlọwọ nipasẹ iṣoro iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria. Gẹgẹ iwadii se ṣafihan rẹ, orilẹede Naijiria wa ni ipo 145th ninu orilẹede 180 ti iwa ibajẹ ti wọpọ.

Aworan Lado Danladi

Ileeṣẹ Dangote yoo ni agbara lati ma pese epo rọbi 650,000 ni ọjọ kan ni kete to ba ti bẹrẹ iṣẹ.

Devakumar Edwin, igbakeji Aare Dangote Group sọ ma pese 500,000 ko to di ipari Oṣu Kẹjọ, eyi ti yoo kọja iye ti orilẹede n pese tẹlẹ to jẹ 480,000 lojoojumọ. Ero ni lati pese ọpọ ju ti tẹlẹ lọ.

Abubakar Maigandi, aarẹ ẹgbẹ awọn ontaja epo olominira lorilẹede Naijiria, ẹni to wa nidi iṣẹ epo tita fun ọgbọn ọdun, ni ileeṣẹ Dangote yoo yanju awọn iṣoro ti wọn n koju nipasẹ irinna.

“Mo ri ọjọ iwaju pe lle afọpo Dangote yoo yanju awọn iṣoro irinna ti a n koju ni akoko igbiyanju lati gba epo ti a ko wọle fun awọn onibara, nitori eyi yoo jẹ atunṣe nitori orilẹede ni a ti n pese rẹ” o sọ.

“Eyi yoo tun tumọ si bẹntiroolu yoo din owo fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria niwon ti a ba ti yọ owo ti a n fi gbe epo wọle kuro. Ireti mi tun ni pe ileeṣẹ afọpo Dangote yoo ma ọja taara laisi awọn alarinna ti yoo da nnkan ru.”

Ẹwẹ, Ọgbẹni Dangote sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ni ọjọ kọkanlelogun Oṣu Keje pe o le mura lati ta ileeṣẹ afọpo naa fun NNPC lọjọ iwaju.

Nigba ti o n ba iwe iroyin Premium Times sọrọ, o sọ pe awọn eniyan kan n tako pe oun ni iru ohun ileeṣẹ to ṣe pataki.

Oluyanju ọrọ ilu Naijiria Sani Bala sọ pe ileeṣẹ Dangote nilo lati "jawo owo epo walẹ" ko ni ipa lati mu aye dẹrun awọn araalu.

O fikun: “Fun emi, mo ro pe ko yẹ ki a gbẹkẹle ileeṣẹ Dangote nikan fun epo rọbi wa. Ti nnkan ba sẹlẹ si nkọ? A lọ pada si ibi ti a ti bẹrẹ. O yẹ ki ileeṣẹ afọpo miiran wa.

Olori ọdọ Arepo Azeez sọ pe ọpọlọpọ awọn ọran lo wa, bii “awọn gbigbọn” lati ileeṣẹ afọpo. "A tun ṣe aniyan lori awọn ijalu alairotẹlẹ ti epo robi da.”

Sibẹsibẹ fun Ọgbẹni Lado ni Kano, o n reti adinku iye owo epo rọbi.