Mi ò ní ilé kankan lókè òkun, mo ń yálégbé nílùú Abuja ni - Dangote

Aworan Dangote

Oríṣun àwòrán, X/DangoteGroup

Baba olowo ilẹ Afirika, Aliko Dangote ti ṣalaye ọrọ kan to ya ọpọ eeyan lẹnu nigba to kede pe bi o ṣe jẹ pe oun lo lowo julọ nilẹ Afrika, oun ko ni ile ẹyọkan ṣoṣo bayii loke okun.

Dangote tun sọ pe ile meji loun ni, sibẹ oun n ya ile gbe ni nilu Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria.

Aliko Dangote ni oniṣowo to lowo julọ ni gbogbo ilẹ Afrika gẹgẹ bi abajade iwadii ọlọdọọdun ileeṣẹ iroyin Forbes Magazine. Fun igba kẹtala ni ṣisẹ n tẹle ni Dangote ti di ipo yii mu lainaani ipo ti eto ọrọ aje Naijiria wa.

Ọrọ Dangote tun lekun si pẹlu irinwo dọla owo ilẹ Amẹrika ni ọdun to kọja, ti igbewọn ọrọ rẹ kalenkako bayii si jẹ biliọnu mẹrinla o din ẹgbẹrun lọna ọgọrun dọla ilẹ Amẹrika.

Eekan oniṣowo, ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin naa kede eyi lasiko to fi n ṣe ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin ni ileeṣẹ ipọnpo rẹ lọjọ Aiku.

Ki nidi ti Dangote ko fi nile si oke okun?

Aworan Aliko Dangote

Oríṣun àwòrán, X/DangoteGroup

Alaye ti Dangote ṣe yi ti fa ọpọlọpọ ifanfa laarin awọn eeyan lori ayelujara. Nibi ti awọn kan ti n woye pe ohun to ṣe naa dara fun idokoowo nitori pe sisan owo iyalegbe rọrun ju kikọ ile lọ.

Amọṣa o, awọn kan wa ti wọn n woye pe pẹlu gbogbo ọrọ ati owo to ni, ṣe o tun yẹ ki baba olowo naa gbe irufẹ igbesẹ yii.

Dangote ni eredi ti oun fi n gbe awọn igbesẹ ti oun n gbe kaakiri orilẹede Naijiria ni lati rii pe orilẹede Naijiria goke agba.

“Idi ti mi o fi ni ile ni ilu London tabi Amẹrika ni pe mo fẹ mojuto idagbasoke idaleeṣẹsilẹ lorilẹede Naijiria.

Mo fẹ ki orilẹede Naijiria mu awọn ala rere rẹ ṣẹ. Bẹẹni , Yatọ si ile ti mo ni nilu Eko, mo ni ile miran ni Kano to jẹ ilu mi. Igbakugba ti mo ba lọ si ilu Abuja, mo maa n san owo ati ya ile gbe nibẹ ni.”

Ki lawọn eeyan n sọ nipa ọrọ Dangote yii lori ayelujara?

Ọkan lara awọn eeyan kan lori ayelujara X pelu orukọ @Zuzutips kan sara si Dangote to si ni oun mọ pe bo ba wu u lati yi ile to n gbe naa pada nigba to ba wu u, o le ṣe e.

“Dangote n ya ile gbe ni Abuja nitori pe o rọrun lati ya ile gbe ju lati kọ ile lọ to si jẹ pe iwọnba akoko lo n gbe nibẹ. Nibayii yoo le yi i pada nigbakugba to ba wu u. Owo kọ ni iṣoro rẹ.”

Aworan Dangote pẹlawọn olori ileeṣẹ iroyin kan ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, X/DangoteGroup

Eeyan miran loju opo X, @common_wealthy ni o yẹ ki eeyan kan saara si Dangote fun ọrọ to sọ yii ati pe ero oun ni pe awọn ọdọ a le ri arikọṣe yii mu lo.

Amọṣa, @Ppweshiouz13 ati @Homiebishop ni tiwọn sọ pe, bafi bi ala ni ọrọ ti Dangote sọ naa ri loju awọn, ati pe awọn n fẹ lati ri ẹri lati ọdọ Dangote pe lootọ lọrọ to sọ.

Kiiṣe ohun to pamọ pe Dangote ni ile kan si agbegbe Banana Island nilu Eko nibi ti ọpọ awọn ilumọọka lorilẹede Naijiria kọ ile si.

Bakan naa ni ile rẹ to kọ si ilu Kano wa ni opopona Lawal Dambazaun nibi to ti maa n gba awọn alejo.