Ààrẹ Rwanda ń du ipò fún sáà kẹrin lẹ́yìn ọdùn mẹ́rìnlélógún lórí oyè

Paul Kagame

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ Rwanda, Paul Kagame, ti n mura lati du ipo Aarẹ fun saa kẹrin lẹyin to ti lo ọdun mẹrinlelogun lori oye.

Awọn onimọ nipa eto oṣelu ti sọ pe yoo wọle lai si wahala kankan to ba le ṣaṣeyọri lati du ipo ọhun.

Lati ọdun 2000 ni Kagame ti wa lori oye Aarẹ, gbogbo idibo to n kopa lati ọdun naa lo si n bori.

Lọdun 2000, oun lo ko ida 90% ninu ibo Aarẹ ti wọn di, lọdun 2017, o tun bori lẹyin ti oun nikan ko ida 99% ibo ọhun.

Ẹni ọdun mẹrinlaadọrin naa n koju oludije meji pere, lẹyin ti ajọ eleto idibo orilẹede naa fofin de awọn oludije to ku.

Aarẹ Kagame ti wa loke tente eto oṣelu Rwanda lati ọdun 1994 ti ẹgbẹgun alatako rẹ ti gbajọba lẹyin isẹlẹ ifẹmiṣofo laarin ẹya Tutsi ati Hutu, ninu eyii ti ẹmi eeyan 800,000 ti sọnu.

Lati ọdun naa lọhun lawọn eeyan ti n kan sara fun akitiyan rẹ lati mu idagbasoke ati isọkan ba orilẹede naa.

Ọmọwe Felix Ndahinda lati agbegbe Great Lakes sọ fun BBC pe “ni ọgbọn ọdun sẹyin, Rwanda ko ni ireti kankan, amọ nnkan bẹrẹ si n pada bọ sipo pẹlu akitiyan iṣejọba Kagame.”

Awọn alatako Aarẹ naa ti fẹsun kan an pe ko gba ẹgbẹ alatako kankan laaye lati koju rẹ, koda awọn kan sọ pe o n ṣekupa awọn to ba le fidi rẹ janlẹ ninu oṣelu.

Lọpọ igba ni Kagame funra rẹ maa n fi ọwọ sọya pe orilẹede oun ki n gbẹmi alaiṣẹ lọna aitọ, paapaa awọn alatako.

Ṣugbọn, onimọ eto oṣelu kan ti sọ pe fun BBC pe oju aye lasan ni eto idibo orilẹede naa latari pe Kageme naa ni yoo papa wọle.

Wayi o, nnkan bii miliọnu mẹsan an eeyan lo ti forukọsilẹ lati kopa ninu eto idibo naa lọdun yii.