Ilé olókè wó lulẹ̀ l’Osogbo, àwọn èèyàn há sí abẹ́ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Ori ko eeyan meji yọ lọwọ iku ojiji lẹyin t'awọn oṣiṣẹ pajawiri at'awọn ẹṣọ eleto abo doola wọn labẹ ogulutu ile alaja kan to wo lu wọn mọlẹ lagbegbe Sabo niluu Osogbo lọjọ Aiku ọjọ kẹrinla oṣu Keje.
SP Yemisi Opalola to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ṣalaye ninu atẹjade to fi sita pe ni bii ago mẹjọ aabọ owurọ l'awọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa.
SP Opalola ni lẹsẹkẹsẹ naa ni kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Osun, CP Mohammed Umar Abba ti gbe awọn ọlọpaa dide lati lọ doola awọn eeyan nibi iṣẹlẹ ọhun.
Bakan naa ni ajọ aabo ara ẹni laabo ilu, NSCDC, awọn oṣiṣẹ panapana to fi mawọn oṣiṣẹ pajawiri naa lo wa níbẹ lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa," SP Opalola ṣalaye.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ile alaja kan ọhun to jẹ akọpati, lawon eeyan kan ti ko rọwọ họri n gbe inu rẹ ki o to wo.
SP Opalola ni eeyan meji to ha sabẹ ile to wo ọhun l'awọn ọlọpaa at'awọn ẹṣọ eleto ri yọ jade laaye.
Agbẹnusọ ọlọpaa ni Shehu Abubakar ẹni ọdun marunlelogoji ati Muktairu Mohammed ẹni ọgbọn odun tawọn doola nibi iṣẹlẹ naa ti n gba itoju nile iwosan.
Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ti rọ awọn eeyan ipinlẹ Osun lati fi to awọn ọlọpaa leti ti wọn ba ri ile to ti fẹ wo lati le dena ijamba iru eyi to ṣẹlẹ lagbegbe Sabo l'Osogbo.
Kọmiṣọna ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ni kaarẹ ninu akitiyan rẹ lati maa daabo bo araalu ati dukia wọn.















