Wo ìdí tí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fi yí ohùn padà lórí gbèdéke gbígba ìwé àṣẹ e-CMR

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti sọ pe awọn ti sun ọjọ ti awọn yoo bẹrẹ sii fi ọwọ ofin mu gbogbo awọn awakọ ti ko ba gba iwe aṣẹ e-CMR siwaju di igba miran.
Atẹjade ti agbẹnusọ agba fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Olumuyiwa Adejobi lo fidi iroyin yii mulẹ ninu atẹjade to fi sita lọjọ kẹrinla, oṣu Keje, ọdun 2024.
Ninu atẹjade naa ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe awọn tubọ fẹẹ fi aaye silẹ lati ṣe idanilẹkọọ to peye fun araalu lori bi iwe aṣẹ e-CMR ọhun ṣe ṣe pataki.
Ọga ọlọpaa, Kayọde Egbetokun sọ pe iwe aṣẹ e-CMR jẹ ọna igbalode ti wọn yoo maa lo lati fi ni akọsilẹ iye ọkọ ati awọn to ni ọkọ lorileede Naijiria, paapaa bi awọn eeyan tun ṣe n ṣe paṣipaarọ ọkọ wọn.
Ẹgbẹtokun ni o ṣe pataki lati sun gbedeke ọjọ ti wọn fi silẹ yii siwaju, lati le ni asiko to to lati fi ṣe idanilẹẹkọ nipa pataki rẹ fun araalu.
Bẹẹ lo rọ gbogbo awọn ọlọpaa lati ma ṣe bẹrẹ sii beere iwe aṣẹ naa lọwọ araalu, nitori pe pupọ awọn eeyan lo n ri igbesẹ naa gẹgẹ bi eto ilọnilọwọgba.
Ọlọ́pàá yóò bẹ̀rẹ̀ síí mú àwọn awakọ̀ tí kò bá gba ìwé àṣẹ E-CMR fún ọkọ̀ wọn - Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force/X
Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Kayode Egbetokun, ti paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa bẹrẹ si fi ofin mu ẹni ti ko ba ni iwe aṣẹ E-CMR fun ọkọ wọn.
Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2024, ni igbesẹ naa yoo bẹrẹ.
Gẹgẹ bi alaye ti Ọga agba ọlọpaa ṣe, ilana tuntun yii jẹ ti igbalode, ti yoo mu ki fifi orukọ ọkọ silẹ maa waye lori ayelujara, fun ifẹsẹ aabo mulẹ ni Naijiria.
"Ilana e-CMR yii jẹ oju opo ti yoo maa ṣiṣẹ lai duro lori akọsilẹ nipa ọkọ.
"Yoo tun ran awọn ọlọpaa lọwọ ninu isẹ iwadii.
Bakan naa ni yoo gbogun ti awọn iwa ọdaran to nii ṣe pẹlu ọkọ, igbesunmọmi, ijinigbe, ati idigunjale.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe sisọ iforukosilẹ ọkọ di ti igbalode yoo mu ki iwadii lori ọkọ maa ya kiakia.
Ninu atẹjade to fi sita lọjọ Abamẹta, agbẹnusọ ọlọpaa, Muyiwa Adejobi, sọ pe e-CMR tuntun yoo jẹ ki ipaarọ orukọ ẹni to ni ọkọ, nọmba ọkọ, awọ ọkọ, lati mu adinku ba rira ati tita ọkọ ti wọn ba ji gbe.
Adejobi sọ pe fifi ofin gbigba iwe iforukosilẹ naa jẹ igbesẹ lati daabo bo Naijiria, ati lati mu adinku ba bi wọn ṣe n ji ọkọ gbe kaakiri.
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni awọn ọmọ Naijiria ṣi n sọ erongba wọn lori igbesẹ tuntun yii.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force/X















