Wo ìhà tí àwọn wòlíì kọ sí òfin tí ìjọba fi de ìpéjọpọ̀ tako àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn àti àjẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ebonyi ti fofin de gbogbo ipagọ, iwọde ati oniruuru ipejọpọ ti wọn gbero lati fi kọlu awọn ti wọn pe ni ajẹ tabi ẹlẹmi okunkun.
Wọn ni awọn lodi si asọtẹlẹ kan tawọn kan gbe jade sita laipẹ yii wi pe wọn gbọdọ gbadura lati kọlu awọn ẹlẹmi okunkun ati oniruuru iwa ajẹ niluu Izzi to wa ni Ebonyi.
Ọjọru to lọ ni olori ile igbimọ naa, Moses Ije Odunwa buwọ lu aṣẹ yii nibi ipade ti wọn ṣe nile aṣofin to wa ni Abakaliki.
Eyi lo waye lẹyin ti ọmọ ile igbimọ aṣofin to n ṣoju ẹkun Izzi, Godwin Abiri gbe ọrọ ọhun dide lỌjọru, ọjọ kẹwaa, oṣu Keje, ọdun 2024.
Abiri sọ pe ohun to n ṣẹlẹ naa yoo fi ẹmi ọpọ araalu sinu ewu nla, nitori to ti ba ọpọ dukia lagbegbe naa jẹ kọja sisọ.
Bakan naa lo fẹsun kan pe “ayederu asọtẹlẹ lo n ṣi awọn eeyan lọkan lati da wahala silẹ, ati lati ba gbogbo iṣẹ akanṣe ti ijọba dawọ le jẹ, eyi ti ko si bojumu to.”
Abiri sọ eyi di mimọ nitori wahala to bẹ silẹ ni Agharaoza lagbegbe Ndi-Ebo Ezzainyimagu, ijọba ibilẹ Izzi, ipinlẹ Ebonyi, nibi ti awọn ọdọ ti kọlu ọkunrin kan ti wọn pe ni John Ekpono.
Yatọ si Johyn Ekpono ti wọn kọlu, wọn tun kọlu mọlẹbi rẹ, ko to di pe wọn dana sun ile rẹ kọja afẹnu-royin.
Ohun ti wọn n binu si ni ti asọtẹlẹ kan ti alufaa kan ni Ekpona sọ sita pe wọn ti de ayanmọ ọpọ awọn ara agbegbe ọhun mọlẹ.
Njẹ iru rẹ ti ṣẹlẹ ri tẹlẹ?
Bo tilẹ jẹ pe ko fẹẹ si orileede ọhun lagbaye ti awọn wolii kii ti ii sọ asọtẹlẹ, lara eyi ti Naijiria wa nibẹ. Koda ilẹ Afrika lo pọ ti a le sọ pe awọn wolii ti n sọ asọtẹlẹ julọ.
Bi awọn kan ṣi ṣe nifẹẹ si asọtẹlẹ lati maa gbọ, bẹẹ si lawọn miran ri ọpọ awọn wolii alasọtẹlẹ gẹgẹ bi eke ati alatẹnujẹ, oni jibiti ati alọnilọwọgba.
Ọpọ awọn wolii ni wọn ti fi asọtẹlẹ wọn da wahala silẹ laarin ilu, nipa sisọ ohun ti Ọlọrun ko ba wọn fun awọn araalu.
Koda, ọpọ awọn idile lo ti daru nipa iran eke ti awọn ayederu wolii ni awọn n ri, yala si ọkọ tabi aya, ẹgbọn tabi aburo.
Ninu oṣu kejila, ọdun 2021, ileeṣẹ ọlọpaa orileede Ghana gbe ikilọ nla jade fun gbogbo awọn olori ẹlẹsin lati ṣọra fun oniruuru asọtẹlẹ ti wọn yoo maa gbe jade.
Atẹjada ti agbẹnusọ ọlọpaa Ghana, Alexander Obeng buwọ jẹ ko di mimọ pe awọn fẹ ki awọn olori ẹlẹsin ṣadinku si asọtẹlẹ wọn, eyi to ṣee ṣe ko da wahala silẹ.
“O ti di iwa ọdaran fun eeyan lati lo oniruuru ikanni ibanisọrọ lati maa fi pin ọrọ ti ko jẹ otitọ, eyi to le ṣi awọn eeyan lọkan sita, to si ṣee ṣe ko da wahala silẹ niluu.
“Ẹni ti ọwọ ba tẹ ni yoo foju winna ofin, ti wọn yoo si fi ẹwọn ọdun mẹsan gbako gbara,” ikilọ ti ọlọpaa Ghana gbe jade ree.
Bakan naa ninu oṣu karun-un, ọdun to kọja, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lorileede Naijiria sọ pe ọwọ awọn tẹ gendekunrin, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan, Akpannu lori wi pe o yọ ada si pasitọ lasiko ijọsin lati ṣaa pa.
Ẹsun ti ileeṣẹ ọlọpaa ni Akpannu fi kan pasitọ ọhun, Anayochukwu ni pe o sọ asọtẹlẹ eke fun oun wi pe oun yoo padanu ẹgbọn oun obinrin, lasiko ti wọn n gbadura lọwọ.
Bẹẹ lo ni pasitọ naa sọ pe koun to le bọ lọwọ ogun, afi koun ṣe iwẹnu kuro lọwọ ogun nipa rira ogogoro ati agbọn lati fi ṣe iṣẹ iwẹnu naa.
Akpannu sọ pe gbogbo ohun ti pasitọ naa ṣe foun ni ko ṣiṣẹ, ati pe irọ lasan ni iran to loun ri soun.
Eyi ati awọn ohun miran lo ti ṣẹlẹ kaakiri agbaye.
Siwaju sii, ninu oṣu karun-un, ọdun 2011 ni ẹgbẹ awọn pasitọ lawọn ṣetan lati maa koju awọn ayederu wolii ti wọn sare wọnu iṣẹ naa lati di olowo ojiji.
Isaac Mills Owoo to jẹ alakoso ẹkun guusu iwọ-oorun ijọ Baptist ni Ghana nigba naa sọ pe ọna ti awọn eeyan fi n sare wọnu iṣẹ iranṣẹ n kọ awọn lominu, to si yẹ ki awọn gbe igbesẹ.
O ni awọn pasitọ kan n ba oku sọrọ lori ẹrọ amohunmaworan, bẹẹ lo lawọn miran n beere owo lọwọ awọn eeyan ko to di pe wọn da awọn eeyan lohun.
Ki ni awọn agba wolii sọ?

Oríṣun àwòrán, Prophet Sebioba
Ojiṣẹ Ọlọrun Solomon Moses Oni Mustapha ti ọpọ mọ si Baba Ṣebi-Ọba, oludasilẹ ijọ Seed of Christ Golden Church, Land of Reality to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ naa sọrọ, o sọ erongba rẹ lori igbesẹ naa fun BBC.
Baba Ṣebi-Ọba sọ pe awọn ko le ba ijọba wi lori igbesẹ wọn, nitori pe Bibeli ti sọ ọ pe a ni lati bọwọ fun awọn alaṣẹ, bo tilẹ jẹ ewu maa n wa ninu awọn igbesẹ naa nigba miran.
“Bibeli naa sọ ninu iwe Owe ori kọkandinlọgbọn, ẹsẹ kejidinlogun pe ilu ti ko ba ti si iran, awọn eeyan to wa nibẹ maa ṣegbe ni.
“Ọpọlọpọ iranṣẹ Ọlọrun ni ko gbọ ohun Oluwa, ko to di pe wọn bẹrẹ sii sọrọ.
Bibeli ni egbe ni fun ẹni to n wi, nigba ti Oluwa ko wi, ṣugbọn o ti gbilẹ bayii fun awọn to pe ara wọn ni ojiṣẹ Ọlọrun ti wọn n sọ pe bayii ni Oluwa wi.
“Fun idi eyi, oriṣiriṣi asọtẹlẹ eke to wa nita ko jẹ ka mọ ojulowo ẹni ti Ọlọrun pe ati awọn ti Ọlọrun n ba sọrọ mọ.
“Ewu ti awọn ti sọ ba sọ iran maa n da silẹ nigba ti Oluwa ko ran wọn tabi nigba ti Ọlọrun ba ran wọn, ṣugbọn ti wọn ko fi ọgbọn gbe ọrọ naa kalẹ ni iru eyi to ṣẹlẹ nipinlẹ Ebonyi yẹn.
Agba wolii naa sọ pe to ba jẹ pe wolii naa fi ọgbọn gbe ọrọ yii kalẹ ni, o ṣee ṣe ki ọrọ ma ri bo ṣe ri yẹn.
Bakan naa lo sọ pe ewu wa lori ilu, ipinlẹ tabi orileede ti ko ba ti si asọtẹlẹ, bẹẹ si ni ewu lori ilu ti wọn ba da adura tabi isọji duro.
O ni awọn to wa ni iru iru bẹẹ ni lati kiyesara, ki wọn si gbadura gidigidi.















