Wo àwọn Ìpínlẹ̀ ní Nàìjíríà tó ṣeéṣe káwọn ìjọba ìbílẹ̀ wọn má rówó gbà bẹ̀rẹ̀ l'óṣù tó ń bọ̀ nítorí àìní alága

Aworan Naijiria ati idanimọ ALGON

Oríṣun àwòrán, Getty Images/ other

Ile ẹjọ to ga ju lorilẹede Naijiria ni o gbe idajọ kalẹ lana, ọjọ kọkanla Oṣu keje ọdun 2024 pe ki ijọba apapọ ma san owo to wa fun awọn ijọba ibilẹ taara si aṣuwọn ijọba ibilẹ.

Igbẹjọ yii tumọ si pe awọn alaga ijọba ibilẹ yoo ni anfani lati se ijọba ni ẹsẹ kuku ni agbegbe kowa wọn.

Ọpọ awọn ipinlẹ lorilẹede Naijiria ni ko ni awọn alaga kansu to n se akoso ijọba ibilẹ gẹgẹ bii ilana ofin orilẹede Naijiria se gbe kalẹ.

Ijọba lorilẹede Naijiria lo pin si ọna mẹta, ijọba apapọ, ijọba ipinlẹ ati ijọba ibilẹ.

Aarẹ orilẹede Naijiria lo n lewaju fun ijọba ipinlẹ, Gomina si n lewaju fun ijọba ipinlẹ.

Awọn alaga kansu lo ma n se kokari fun ijọba ibilẹ, ti igbagbọ si wa pe ijọba ibilẹ lo sum mọ araalu ju.

Awọn ipinlẹ bi Osun, Jigawa, Ondo, Anambra, Imo, Kwara, Zamfara, Bauchi, Plateau, Abia, Enugu, Katsina, Kano, Sokoto, Yobe , Delta, Akwa-Ibom, Cross-River ati Benue ni wọn ti se eto idibo fun awọn ijọba ibilẹ.

O ṣeeṣe ki awọn ipinlẹ yii ma ni anfani si awọn ẹtọ kan ti wọn gba tẹlẹ lati ọwọ ijọba apapọ.

Eyi lo jẹ ki BBC News Yoruba kan si awọn onimọ lati sọ nnkan ti yoo waye si awọn ipinlẹ ti ko ni alaga kansu lọwọ lasiko yii.

Aworan agbegbe

Oríṣun àwòrán, Others

Ki ni yoo sẹlẹ si awọn ipinlẹ ti ko wọn ko ni alaga kansu lẹyin idajọ ileẹjọ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu alaye rẹ fun BBC News, Onimọ nipa ọrọ oṣelu, Ọjọgbọn Gbade Ojo lati fasiti Unilorin ṣalaye pe o ṣeeṣe ki ijọba ma san owo ijọba ibilẹ fun awọn ipinlẹ ti wọn ko ni alaga kansu.

Bakan naa lo fikun pe idajọ ile ẹjọ yoo jẹ ki awọn gomina yara lati ri pe awọn se eto idibo fun awọn alaga ijọba ibilẹ.

O tẹsiwaju pe o ṣe ni laanu pe dipo ẹka ijọba mẹta to ko wa gẹgẹ bi ofin se gbe kalẹ meji nikan lo wa sugbọn idajọ ile ẹjọ yoo anfani fun eto idibo ijọba ibilẹ lati waye ni awọn agbegbe yii.

“Awọn ipinlẹ kọọkan ṣẹṣẹ n gbero lati se idibo ijọba ibilẹ sugbọn idajọ ile ẹjọ yoo wa ri daju bayii pe awọn ipinlẹ yii gbe igbesẹ to yẹ.

“Ti wọn ba kọ lati gbe igbesẹ, o ṣeeṣe ki ijọba apapọ fi ma fi owo ijọba ibilẹ ransẹ si ipinlẹ gẹgẹ bi ti tẹlẹ, ti gomina yoo ri pe oun san gbogbo owo oṣu awọn osisẹ lasiko naa.

“Eyi yoo jẹ ki wọn tete gbajumọ sise eto idibo fun awọn ijọba ibilẹ ni kiakia.”

Bakan naa, Alaga tẹlẹ nijọba ibilẹ Oluyole nipinlẹ Oyo, Abass Aleshinloye naa jẹ ko di mimọ pe ti awọn Gomina ba kọ lati se eto idibo ijọba ibilẹ, ijọba o ni san owo ijọba sinu apo ijọba ipinlẹ.

“Wọn ma se eto idibo ijọba ibilẹ nitori owo o ni aṣuwọn apo ijọba ipinlẹ mọ, wọn lati se eto idibo ni kiakia.

“Nnkan ile ẹjọ sọ fun niyẹn pe ki owo lọ sinu apo ijọba ibilẹ ti ilu dibo yan sipo.”