Àpapọ̀ owó rìbá tí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba lórílẹ̀èdè Nàìjíríà gbà láàrín ọdún 2023 nìkan jẹ́ ₦721b

Eeyan kan n gba owo lọwọ ẹlomiran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ NBS to n ri iṣiro nnkan ni Naijiria ati ẹka ajọ iṣọkan agbaye UNODC to n gbogun ti oogun oloro ati iwa odaran ti sọ pe ko din ni N721bn owo riba t'awọn oṣiṣẹ ọba gba ni Naijiria lọdun 2023.

Eyi jẹ esi iṣẹ iwadii ti ajọ UNODC ṣe.

Gẹgẹ bi esi iwadii naa eyi ti ajọ NBS gbe jade l'Ọjọbọ ṣe sọ, N721bn yii ko ida to pọ ninu owo ti ko ba jẹ owo ajẹmọnu awọn ọmọ Naijiria.

Iṣẹ iwadii naa ṣalaye pe N8,284 lowó abẹtẹlẹ to wọpọ julọ t'awọn oṣiṣẹ ọba gba lọdun 2023.

Esi iwadii naa sọ pe bo tilẹ jẹ pe ida 56% ọmọ Naijiria lo ni ajọṣepọ pẹlu awọn oṣiṣẹ ọba lọdun 2023, eyi to ju ida 63% ti ọdun 2019 lọ, gbigba owo abẹtẹlẹ ṣi n pọ si ni.

Ọna wo lawọn oṣiṣẹ ijọba fi gba riba N721bn ọhun?

Esi iwadii ajọ UNODC ṣalaye pe ida 95% ninu 100% owo yii l'awọn oṣiṣẹ ọba gba tabi gba nipa fifi owo naa ranṣẹ si akaunti banki wọn.

Esi iwadii naa tun fidi rẹ mulẹ pe lootọ l'awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ti kii ṣe ti ijọba naa n gba owo abẹtẹlẹ, amọ awọn oṣiṣẹ ijọba lo n gba riba to pọju.

Gẹgẹ bi iṣẹ iwadii naa ṣe sọ, ida 27% eeyan to ni ajọṣepọ pẹlu awọn oṣiṣẹ ijọba lọdun 2023 ni wọn gba riba lọwọ wọn.

Iwadii ni lootọọ l'awọn oṣiṣẹ ijọba kan kọ lati gba owo abẹtẹlẹ lọwọ awọn eeyan kan to fẹ fun wọn.

Amọ, iwadii naa ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe ida kan ninu ida meta ajọṣepọ awọn oṣiṣẹ ijọba pẹlu araalu lo ni ṣe pẹlu riba gbigba.

Ẹwẹ, esi iwadii naa tun gbe e jade pe iye awọn ọmọ Naijiria ti wọn kọ lati gba owo abẹtẹlẹ ti n pọ si.

Esi iwadii naa sọ pe ida 70% awọn eeyan tawọn oṣiṣẹ ijọba beere owo abẹtẹlẹ lọwọ wọn lo sọ pe awọn ko ni san an.

Iwadii ọhun tun fihan pe bii idaji awọn to gba ipo kan tabi omiran lẹnu iṣẹ ọba ni bii ọdun ṣaaju iṣẹ iwadii yii lo yege ninu idanwo igbaniṣiṣẹ tabi ifọrọwanilẹnuwo.

Bi ida 41% awọn eeyan to ṣe idanwo igbaniṣiṣẹ lo san owo abẹtẹlẹ lati ti ri iṣẹ gba.

Lakotan, iwadii naa sọ pe adinku ti ba igboya t'awọn ọmọ Naijiria ni ninu ijọba orilẹede naa sii ju ti atẹyinwa lọ.