Kí ni àbọ̀ ìpàdé Tinubu àtẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lórí owó oṣù tó kéré jùlọ?

Tinubu, Joe Ajaero àti Festus Osifo

Oríṣun àwòrán, NLC/BOLA TINUBU

Ìpàdé láàárín ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tó wáyé ní ilé ìjọba ní ìlú Abuja ti wá sópin.

Ṣùgbọ́n wọn kò ì tíì fẹnukò lọrí owọ oṣù tó kéré jùlọ fún àwọn òṣìṣẹ́.

Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, Nigeria Labour Congress, Joe Ajaero àti akẹgbẹ́ rẹ̀ ti Trade Union Congress, Festos Osifo ni wọ́n ṣaájú ikọ̀ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ láti lọ ṣèpàdé pẹ̀lú ààrẹ Tinubu lórí ọ̀rọ̀ owó oṣù tó kéré jùlọ fáwọn òṣìṣẹ́ lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Keje, ọdún 2024.

Níṣe ni ìrètí wà pé lẹ́yìn tí wọ́n bá parí ìpàdé náà ni ààrẹ Tinubu yóò kéde pé àwọn ti fẹnuk]o pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ àma tí èyí kò ṣẹlẹ̀.

Mínísítà fétò ìròyìn, Mohammed Idris tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé náà ṣàlàyé pé ìjíròrò ṣì ń lọ lọ́wọ́ lórí owó oṣù náà àti pé ìpàdé tí ààrẹ ṣe pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ni láti fẹnukò lórí iye kan ní pàtó.

Idris ṣàlàyé pé ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní lẹ́yìn ìjíròrò wọn pẹ̀lú ààrẹ, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní kí ààrẹ fún àwọn ní ọ̀sẹ̀ láti lọ jíròrò pẹ̀lú àwọn èèyàn wọn kí wọ́n sì jábọ̀ padà nígbà náà.

Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan yìí, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti ìjọba yóò fẹnukò lórí iye kan pàtó àti pé yóò so èso rere fáwọn ọmọ Nàìjíríà.

Ẹ ó rántí pé láti bíi oṣù mélòó kan ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lórí owó oṣù tó kéré jùlọ.

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní ẹgbẹ́rùn lọ́nà igba lé ní àádọ́ta náírà (N250,000) ni àwọn ń fẹ́ gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ àmọ́ ìjọba àpapọ̀ àtàwọn iléeṣẹ́ aládani ní àwọn kò lè san ju ẹgbẹ́rùn méjìlélọ́gọ́ta (N62,000) lọ.

Bákan náà ni àwọn gómìnà ní àwọn kò lè san ẹgbẹ́rùn méjìlélọ́gọ́ta (N62,000) tí ìjọba àpapọ̀ ní àwọn fẹ́ san.

Tinubu yóò bá àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ṣe ìpàdé lónìí

Aarẹ Tinubu ati ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti ṣetan lati ba apapọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, NLC ati TUC ṣe ipade papọ lati wa iyanju si ọrọ owo oṣu tuntun to n da aawọ silẹ.

Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣe TUC, Festus Osifo lo fi iroyin naa mulẹ fun awọn akọroyin.

Agbẹnusọ NLC, Benson Upah sọ fun awọn akọroyin pe ẹgbẹ oṣosẹ ko ni ero wọn pada, ti wọn yoo si duro le owo toto N250,000 gẹgẹ bi owo oṣu to kere ju ti awọn osiṣẹ yoo ma gba loṣu.

"A n lọ ba Aarẹ lati so pe iye ti a fẹ ni N250,000 gẹgẹ bi owo oṣu to kere ju nitori ọwọngogo to gbode."

Ẹgbẹrun lọna aadọtalenigba (N25,000) naira ni apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ n beere fun gẹgẹ bi owo oṣu to kere julọ fawọn oṣiṣẹ Naijiria, ṣugbọn ti ijọba apapọ sọ pe ohun ko le san ju ẹgbẹrun mejilelọgọta (N62,000) naira lọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nibi ipade ti yoo waye nile agbara ilẹ wa, Aso Rock to wa niluu Abuja lo ti ṣee ṣe ki wọn fẹnu ko lori iye ti ijọba apapọ lagbara lati san gẹgẹ bi owo oṣu tuntun.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ipade ọhun ni yoo waye lẹyin bi oṣu kan gbako ti Aarẹ Tinubu sọrọ, to si ṣeleri pe oun yoo fi iwe aba lori owo oṣu tuntun ranṣẹ sile igbimọ aṣofin laati buwọ lu, iyẹn lọjọ ayajọ eto iṣọba awa-arawa ti June 12.

Bakan naa, Benson Upah to jẹ agbẹnusọ fẹgbẹ oṣiṣẹ NLC sọ pe awọn yoo ṣi duro lori ẹgbẹrun lọna aadọtalenigba naira ti awọn n beere fun bi aarẹ ba bawọn ṣepade lonii.

“A maa gbe N250,000 naira ti a n beere fun siwaju wọn nitori pe gbogbo nnkan ti a ra lo ti gbowo lori. Awa naa ti ṣe ọmọluabi gẹgẹ bi ọmọ Naijiria rere,” Upah sọrọ.

Lọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun yii, awọn alakoso (FEC) ti Aarẹ jẹ alaga rẹ juwọ silẹ lori erongba wọn nipa owo oṣu tuntun, eyi si ni lati le tubọ gba ijiroro ati ajọsọ laarin ijọba apapọ ati awọn ti ọrọ kan laaye.

Ọjọ meji lẹyin eyi ni Aarẹ Tinubu ati igbakeji rẹ, Shettima nibi ipade NEC to waye, ṣepade pẹlu awọn gomina Naijiria ati awọn minisita lati jiroro lori owo oṣu tuntun f’awọn oṣiṣẹ.