Òkú Họnọrebu Jagaban wọ káà ilẹ̀ sùn

Olaide Akinremi àti òkú rẹ̀ nínú pósí

Wọn ti sin oku Họnọrebu to n ṣoju ẹku idibo Ariwa Ibadan nile igbimọ aṣoju-ṣofin l'abuja, Ọlajide Akinrẹmi ti ọpọ eeyan mọ si "Jagaban" si ile rẹ to n bẹ ni Temidire Estate ni agbegbe Ologunẹru niluu Ibadan.

Ọpọlọpọ ẹbi, ara, ọrẹ, ojulumọ ati awọn oloṣelu lo kọrajọpọ lati ṣe idaro oloogbe naa.

Lara awọn oloṣelu to pejupesẹ si ibi eto isinku naa ni oludije tẹlẹri si ipo Gomina ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Tẹslim Fọlarin, aṣoju ile igbimọ aṣoju-ṣofin tẹlẹri, Shina Peller, aṣoju ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Họnọrebu Stanley Adedeji Odidiọmọ, aṣoju ile igbimọ aṣoju-ṣofin tẹlẹri, Saheed Fijabi ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oku Jagaban ninu posi
Àwọn olùdárè Jagaban

Sẹnetọ Tẹslim Fọlarin ba awọn oniroyin sọrọ nibi eto isinku naa, ni ibi ti o ti ṣe alaye wi pe titilae ni oun yoo maa ṣe afẹri oloogbe Akinrẹmi nitori eeyan daadaa to ni ọkọ rere ni.

Aṣoju ile igbmo aṣofin tẹlẹ ri, Shina Peller ṣe alaye wi pe ariwo oloṣelu to di oloogbe ni araye n pa, ṣugbọn ọrẹ timọtimọ ni oun padanu.

Peller fi kun ọrọ rẹ pe laarin ọjọ meji si asiko ti ọrẹ oun jade laye ni awọn jọ n sọrọ leralera.

O ni kodaa, awọn ṣi jọ sọrọ laarọ ọjọ ti o jade laye.

Lati ẹnu iloro adugbo oloogbe naa titi de inu ile rẹ ti wọn sin in si ni ẹsẹ ko ti gba ero. Ariwo oro, ẹkun ati abamọ ni ọpọlọpọ awọn to wa kẹdun fi dirọmọ ọkọ to gbe oku wa sile.

Teslim Folarin nibi eto isinku Jagaban
Shina Peller nibi eto isinku Jagaban
Àwọn oludaro Jagaban
Awọn oludaro lara ọkọ to gbe oku Jagaban lọ sile

Inú ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin Abuja ni Họnọrẹbu Jagaban ti dédé ṣubú kí ọlọ́jọ́ tó dé - Alábaṣiṣẹ́pọ̀

Aworan Akinremi Jagaban to di oloogbe

Oríṣun àwòrán, Others

Họnọrebu to n ṣoju ẹku idibo Ariwa Ibadan nile igbimọ aṣoju-ṣofin l'abuja, Ọlaide Akinrẹmi ti ọpọ eeyan mọ si "Jagaban" jade laye l'Ọjọru l'ẹni ọdun mọkanlelaadọta.

Lonii ni wọn o bo aṣiri oloogbe naa ni ile rẹ to n bẹ ni Temidire Estate ni agbegbe Ologunẹru niluu Ibadan.

BBC Yoruba ṣe abẹwo si ile oloogbe naa, a si ni afani lati ba Alagba L.A Fatoyibo ti o jẹ ọkan lara awọn alabaṣiṣẹpọ oloogbe naa sọrọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Fatayinbo ṣe alaye fun akọroyin wa wi pe ṣaka ni ara oloogbe na da ki ọlọjọ to de, o si darapọ mọ awọn akẹgbẹ rẹ nile igbimọ aṣoju-ṣofin lọjọ naa, ṣugbọn ṣa dede ni o ṣubu nigba ti ijoko ile n lọ lọwọ ti wa si gbee digbadigba lọ si ile iwosan to n bẹ nile igbimọ aṣoju-ṣofin. Ibi ti wọn ti n tọju Họnọrebu naa lo dakẹ si.

Lati le fi idi rẹ mulẹ wi pe oloogbe naa ko ṣe aisan ki ọlọjọ to de, Alagba Fatoyinbo ṣe alaye wi pe ile ẹkọ kan wa ti o kọ fun awọn eeyan ẹkun idibo rẹ ti o yẹ ki o ṣi lanaa, bakan naa si ni o ti ra aṣọ fun ajọyọ aafin Olubadan tuntun lẹyin ti oun gan an gbe owo silẹ fun awọn eto ti wọn fẹ ṣe, ṣugbọn ọlọjọ de ba oloogbe naa lojiji.

Lẹyin iṣẹlẹ yii ni ile igbimọ aṣoju-ṣoju pasẹ isinmi ranpẹ lati ṣe idaro oloogbe naa, bẹẹ sini ijọba apapọ orilẹẹde Naijiria, ijọba ipinlẹ Ọyọ ati, ẹgbẹ oṣelu APC ati awọn ọkanojọkan oloṣelu ti kọwe ibanikẹdun ranṣe lati ṣe idaro oloogbe naa.

Fatoyinbo ṣe apejuwe Akinrẹmi gẹgẹ bii oloṣelu to ko gbogbo eeyan mọra to si n tọju ọmọde ati agba. O ni ipapoda Họnọrebu naa ti ṣi alafo nla silẹ gẹgẹ bi o ṣe n gbadura pe ki eledua tẹẹ si afẹfẹ rẹrẹ.

Ọpọlọpọ ẹbi, ara, ọrẹ ati ojulumọ ti korajọpọ ti wọn si n reti ki wọn gbe oku rẹ de lati Abuja ki eto isinku to waye lonii.

Saa meji ni Họnọrebu Jagaban lo gẹgẹ bii ẹni to ṣoju ẹkun idibo Ariwa Ibadan nile igbimọ aṣoju-ṣofin, oun naa sini o n ṣoju ẹkun idibo naa ki ọlọjọ to de.

Ohun to yẹ ko mọ nipa Akinremi Jagaban

  • Ọjọ kinni, Oṣu kẹwaa ọdun 1972 ni wọn bi Ọmọọba Olaide Adewale Musliudeen Akinremi si idile Baba Latifu Adisa Akinremi.
  • Ẹni ọdun mọkanlelaadọta ni Jagaban ko to jade laye.
  • O kẹkọ gboye ni okowo ni fasiti African Methodist Zion ni Monrovia.
  • Ọdun 2019 ni o gbe apoti ibo lati jẹ aṣoju awọn eeyan ariwa Ibadan ni ile igbimọ aṣofin kekere labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress.
  • O fẹ Arabirin Adama Akinremi, ti wọn si bimọ marun un fun ara wọn.

Ki ni awọn eekan ilu sọ nipa Akinremi Jagaban?

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti ransẹ ibanikẹdun si mọlẹbi Akinremi Olaide to di oloogbe lanaa.

Aarẹ ninu atẹjade ti agbẹnusọ Aarẹ Ajuru Ngelale fi sita fun awọn akọroyin ṣapejuwe Oloogbe gẹgẹ bii akikanju to fẹran ilu, to si n wa idagbasoke fun orilẹede Naijiria .

Tinubu gba ladura pe ki Ọlọrun duro ti mọlẹbi ati awọn ọrẹ oloogbe .

Olori ile igbimọ aṣofin lorilẹede Naijiria, Abbas Tajudeen ṣapejuwe ipapoda Akinremi Jagaban gẹgẹ bii eyi to ba ni lọkan jẹ pupọ.

Ninu iwe ibanikẹdun to fi ransẹ si idile Akinremi, eyi ti agbẹnusọ rẹ, Musa Krishi buwọlu fun awọn akọroyin sọ pe iroyin nipa iku Jagaban ba oun lojiji.

O ṣapejuwe oloogbe gẹgẹ bii eeyan to fẹran araalu, to si gbe ọrọ ilu sori pupọ.

Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo naa ti palasẹ pe ki wọn sọ aisa orilẹede di idaji kaakiri gbogbo ọfisi ijọba lati fi daro Oloogbe Jagaban.

Gomina pa aṣẹ ninu atẹjade kan ti Minisita fun iroyin nipinlẹ Oyo, Dotun Oyelade fi ransẹ si awọn akọroyin lati fi se idaro Hon Jagaban to di oloogbe.