Wo ìdí tí o fi gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nípa áàpù TikTok àti áàpù mẹ́ta míràn lórí fóònù rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n ri si imọ ẹrọ igbalode ni Naijiria, NITDA, ti fi ikilọ sita nipa awọn aapu kan to lewu fun awọn ọmọ araalu.
Awọn aapu naa ni wọn ni ki awọn eeyan ṣọra fun, paapaa awọn to n lo ẹrọ ibaraẹnisọrọ Android.
NITDA sọ pe awọn aapu ọhun le wọ inu kọrọkọndu foonu eeyan lọna aitọ, ti wọn yoo si ji awọn iroyin tabi aṣiri to ṣe pataki lori foonu irufẹ ẹni.
Awọn aapu naa
- Crazy Game
- Sexy Videos
- TikToks
- Weapons
NITDA sọ pe awọn aapu wọnyii le ni eroja ‘malware’ to lagbara lati maa ṣọ iṣe ẹni to ni foonu lojulẹsẹ, ti yoo si maa ṣe ofofo rẹ fun awọn ẹlomiran.
Ninu atẹjade kan ni NITDA fi lede lo ti kede bẹẹ.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, awọn aapu kan to n ji iroyin nipa eeyan le dibọn bii ojulowo aapu lọna ati wọ inu ẹrọ ilewọ.
Ewu nla lo wa fun ẹnikẹni ti eroja ‘malware’ ba ti wọ inu foonu rẹ.
Fun apẹrẹ, ‘ malware’ naa le maa ka ohun ti eeyan n ṣe lori foonu silẹ, irufẹ eroja bẹẹ si lawọn onijibiti ori ayelujara maa n lo lati ji owo ninu akanti eeyan.
NITDA ti wa kilọ fun awọn ọmọ Naijiria ki wọn ṣọra fun awọn aapu ọhun, nitori oju ni alakan fi n ṣọri.















