Èyí ni bí o ṣe lè fi iṣẹ́-abẹ tún abẹ́ tí wọ́n dá fún ọ ṣe ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ bó ṣe rí láti jẹ́ obìnrin tó pé báyìí’

Shamsa Sharaawe

Oríṣun àwòrán, Shamsa Sharaawe

Àkọlé àwòrán, Shamsa Sharaawe ree lọsibitu lẹyin iṣẹ-abẹ atunṣe naa.
    • Author, Bushra Mohamed
    • Role, BBC News
    • Reporting from, London

Ikilọ:Awọn ohun to le ma ba ọ lara mu wa ninu ayọka yii.

“‘’Ẹru ba mi gan-an lati tun gbọ pe wọn tun fẹẹ ṣiṣẹ abẹ fun mi lẹẹkan si i, bo tilẹ jẹ pe funra mi ni mo gba pe ki wọn ṣe e ni ti eyi, ṣugbọn mo gbọdọ ṣe e fun ilera ọkan ati ara mi ni’’

Ọmọbinrin kan, Shamsa Sharaawe lo n sọrọ nipa ipinnu rẹ lati ṣiṣẹ abẹ ti yoo tun oju ara rẹ ṣe gẹgẹ bii obinrin léyin ti wọn dabẹ fun un lọdun mẹẹẹdọgbọn sẹyin, iyẹn nigba to wa lọmọ ọdun mẹfa pere.

Dídá abẹ fun ọmọbinrin ti oyinbo n pe ni ‘Female Genital Mutilation’ (FGM) ni wọn ṣe fun Shamsa niluu rẹ ti i ṣe Somalia. Awọn mọlẹbi ni wọn pe oníkọlà obinrin kan wa to dabẹ ọhun fun un.

O le ni igba ati ọgbọn miliọnu ọmọbinrin (230m) ti wọn ti koju abẹ dida yii kaakiri agbaye, gẹgẹ bi abajade ajọ UNICEF kan ṣe kede laipẹ yii.

Nilẹ Adulawọ nikan, abajade naa fidi ẹ mulẹ pe o ju ogoje miliọnu (140m) ọmọbinrin ati awọn agbalagba obinrin lọ ti wọn ti dabẹ fun.

Lorilẹede Somalia, Guinea ati Djibouti, ọpọlọpọ ọmọbinrin ni wọn maa n dabẹ fun, o to ida aadọrun (90%). Igbagbọ wọn ni pe dida abẹ fun ọmọbinrin yoo jẹ ki iable rẹ duro rẹgi. Eyi si jẹ nnkan babara ti wọn ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu rara.

Ọpọ eeyan lo tiẹ gbagbọ ni Somalia, pe ibale ọmọbinrin ati idile to ti wa ko ṣee pin, ọkan ṣoṣo ni wọn.

Wọn gbagbọ pe ogo idile yoo duro digbi bawọn ba dabẹ fun awọn ọmọbinrin.

Awọn obinrin ti ko ba dabẹ ni Somalia, aṣa ọmọ ti ko lẹkọọ ibalopọ ni wọn maa n pe wọn, wọn si gbagbọ pe eyi yoo ba iyi ati ijẹọmọluabi mọlẹbi jẹ ni.

Dokita Adan n ṣiṣẹ-abẹ kan ni Nairobi

Oríṣun àwòrán, Dr Adan Abdullahi

Àkọlé àwòrán, Dokita Adan n ṣiṣẹ-abẹ kan ni Nairobi
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n dagba, Shamsa ṣalaye pe inira to lagbara loun maa n koju nigbakigba toun ba n ṣe nnkan oṣu.

‘’Ohun ti mo ṣaa fẹ nigba yẹn ko ju ki n ma ri inira naa mọ’’ Bẹẹ ni Shamsa wi.

Ni ipari ọdun 2023, nigba ti Shamsa ti pe ẹni ọgbọn ọdun, o gbiyanju lati ṣiṣẹ abẹ ti yoo fi dẹkun inira to n koju.

Orilẹede UK lo n gbe nigba naa, o si ti di agbẹnusọ to n tako abẹ dida fawọn obinrin lori ayelujara.

Shamsa mọ pe ọpọ obinrin lo wa nipo inira bii toun ti wọn ko si mọ ohun ti wọn le ṣe, eyi lo jẹ ko pinnu pe oun yoo maa kede iṣẹ-abẹ atunṣe abẹ naa lori ayelujara.

‘’ Ko ti i si alaye kikun to lori iṣẹ-abẹ yii funra rẹ, idi niyẹn ti mo fi n sọrọ nipa eyi’’ Shamsa lo sọ bẹẹ.

Iṣẹ-abẹ ti wọn fi n tun oju ara ṣe yii wa fun ki abẹ obinrin le ṣiṣẹ to yẹ ko ṣe, ki i sẹ fun faari abi oge ṣiṣe.

O ni i ṣe pẹlu idọ ati eyi ti oyinbo n pe ni ‘labia’, yiyọ kokoro aifojuri to ba wa nibẹ kuro ati àpa, ki irora le dinku fobinrin, ki ibalopọ si le jẹ amoriya fun wọn.

Fun awọn mi-in si ree, wọn le mu iwaju abẹ naa ki wọn ṣiṣẹ lori rẹ, yoo si pada si bo ṣe yẹ ko wa.

Lẹyin ọpọlọpọ iwadii, Shamsa ri i pe ibi kan ṣoṣo ti wọn ti le ṣiṣẹ-abẹ toun ti yoo ṣe rẹgi ni orilẹede Germany.

O da oju opo kan silẹ to ti n beere fun iranlọwọ lori ayelujara, o si ri owo to to dọla mọkalelọgbọn ( $31,000) (£25,000) pa.

Ṣugbọn bi awọn eeyan ṣe dawo fun un to, koda to jẹ pe awọn mi-in ko tiẹ gbọ nipa abẹ dida fun obinrin ri ti wọn fi dawo ọhun, sibẹ owo to ri ko too ṣiṣẹ-abẹ naa.

Ni gbẹyin, owo ti Shamsa na lorii wiwa ẹni ti yoo ba a mojuto ọmọ obinrin to bi, ati eyi to fi wọ baaluu lọ si Germany pẹlu owo iṣẹ abẹ gan-an ju $37,000 (£30,000) lọ.

Eyi mu ko jẹ ọsibitu naa lowo to to 3800 Euros (£3,280, $4045)

“ Mi o ti i le pada lọọ maa gba itọju to yẹ lẹyin ti mo ṣiṣẹ abẹ naa tan, nitori mi o lowo ti mo maa fi ṣe e.’’ Bayii ni Shamsa wi.

“Keeyan maa sanwo fun iṣoro ti ki i ṣe oun lo fa a funra ẹ ki i ṣe ohun to daa rara.”

Dokita Reham Awwad ni Egypt.

Oríṣun àwòrán, Dr Reham Awwad

Ṣé ọ̀nà àbáyọ ni iṣẹ́-abẹ bi?

Oriṣi mẹrin ni abẹ dida fun obinrin,bi wọn ṣe lagbara si, ti wọn n dun eeyan si naa si yatọ sira wọn.

Akọkọ ni ki wọn yọ apa kan idọ kuro tabi ki wọn ge gbogbo ẹ patapata. Ikeji ni ki wọn ge apa kan tabi gbogbo idọ naa kuro, ki wọn tun ge inu eyi ti wọn n pe ni labia.

Ikẹta ni ki wọn din iho oju ara naa ku nipa gige labia tabi ki wọn sun un si apa ibo mi-in. Ikẹrin to le ju ni ki wọn ge idọ kuro, ki wọn ge eyi toyinbo n pe ni vulva ati gbogbo ohun to ba ṣee ge nibẹ pata, ki wọn si ran an pada.

Ni nnkan bii ogun ọdun sẹyin,lilo iṣẹ abẹ onike lati ṣatunṣe awọn ibi ti wọn n ge yii bẹrẹ.

Ni 2004, ileeṣẹ alatunṣe akọkọ waye. Dokita ọmọ ilẹ Faranse kan, Pierre Foldès, to mọ nipa ibi ti eeyan ti n tọ lo da a silẹ. Lẹyin igba naa, awọn dokita mi-in naa ti wa ọna itọju miran lati ṣe atunṣe si abẹ ti wọn ba da.

Ṣugbọn, nilẹ Adulawọ ti wọn ti nilo atunṣe yii ju, iwọnba ni wọn ni anfaani si iṣẹ abẹ mọ. Orilẹede Kenya nikan ni anfaani naa ṣi wa bayii, nibi ti awọn to fẹẹ tun abẹ wọn ṣe yoo ti sanwo funra wọn. Tabi ni Egypt, nibi ti awọn ajọ ti ki i ṣe tijọba ti maa n ba awọn kan sanwo iṣẹ abẹ naa.

Ni Europe, awọn orilẹede kan maa n gba owo ti ko to nnkan fun iṣẹ-abẹ atunṣe yii. Ni Belgium, Germany, France, Sweden, Finland ati Switzerland, awọn eleto ma-dami-dofo fun awujọ lo maa n ba wọn sanwo ọhun, o si wa bẹẹ ni Netherlands naa.

Gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ kan nipa abẹ dida ni Kenya ṣe wi, iṣẹ-abẹ atunṣe yii ti n gbilẹ gan-an lawọn orilẹede to ti gunke agba.

“ Awọn dokita oniṣẹ-abẹ diẹ ti n ṣe e nilẹẹ Europe ati Amẹrika’’ Dokita Adan Abdullahi lo ṣalaye bẹẹ.

“Ṣugbọn ki i ṣe gbogbo dokita oniṣẹ-abẹ lo le ṣe iṣẹ-abẹ yii, o gbẹgẹ pupọ, awọn eeyan ti wọn si fẹẹ ṣe e fun yatọ sira wọn.

Dokita Abdullahi sọ pe iru abẹ dida yoowu ti wọn ba ṣe fobinrin, iṣẹ abẹ yoo yanju rẹ. O ni ṣugbọn awọn to maa n gba itura ju ni awọn ti wọn ti dabẹ fun kọja sisọ.

“Ipa to daa lo maa n ni teeyan ba fẹẹ bimọ, paapaa awọn ti wọn din oju ara wọn ku nigba ti wọn n ṣe e fun wọn.’’

Bakan naa lo ni inira lasiko ibalopọ naa yoo duro lẹyin iṣẹ-abẹ atunṣe yii. O ni awọn toun n tọju maa n ri ara wọn bii ẹni to peye lẹyin iṣẹ-abẹ naa.

Haja Bilkisu ni 2002.

Oríṣun àwòrán, Haja Bilkisu

Àkọlé àwòrán, Haja Bilkisu nigba ti wọn dabẹ fun ni 2002

‘Ó le lára’

Haja Bilkisu, ọmọ orilẹede Sierra Leone to ti di ọmọ oniluu ni Germany, ti ṣe iṣẹ-abẹ atunṣe yii lọpọ igba. O rọ awọn eeyan lati wadii daadaa ki wọn too gbe igbesẹ naa.

" Atunṣe yii ki i ṣe lati tun idọ ṣe lasan" Haja Bilkisu lo sọ bẹẹ.

" Ọpọlọpọ obinrin ti wọn ti ṣiṣẹ abẹ fun ni àpá wa lara wọn. Bawo lo ṣe le mu apa naa kuro? O ni lati ba dokita rẹ sọrọ’’

Kí lohun tí o lè ṣe tí yóò mú kí abẹ́ rẹ padà sípò?

Haja Bilkisu ṣalaye pe o ṣe pataki ki abẹ obinrin pada sipo, ki i ṣe fun ibalopọ nikan bo ṣe wi, ati fun ọmọ bibi naa.

Wakati mẹfa ni wọn fi ṣe iṣe-abẹ kọọkan ti Haja Bilkisu ṣe.

“ Eyi ko dẹrun, o daju. Wọn yoo fun ọ ni oogun ti yoo pa irora fun ọ. O tun gbọdọ maa lo oogun lẹyin igba naa. Fun ọsẹ mẹta ni mi o fi le rin.” Bayii ni Haja Bilkisu wi.

Nitori ipa ti iṣẹ-abẹ yii le ni lara eeyan, awọn dokita kan ti n polongo ilana mi-in ti ko jẹ mọ iṣẹ-abẹ.

Dokita Reham Awwad, jẹ ọkan lara awọn oludasilẹ ọsibitu kan ni Egypt, Restore, ni wọn pe orukọ rẹ, ọdun 2020 ni wọn da a silẹ lati maa tọju awọn obinrin ti wọn dabẹ fun ni kekere.

Dokita Awwad ṣalaye pe ẹnikan ti wọn dabẹ fun toun ri lasiko toun n kọṣẹ dokita lọwọ lo wu oun lori, toun fi pinnu lati kẹkọọ nipa itọju awọn eeyan ti wọn dabẹ fun.

O ni bo tilẹ jẹ pe iṣẹ-abẹ le mu idẹrun wa, o nira lati ge ara eeyan, koda pẹlu awọn irinṣẹ igbalode,yoo ṣoro ki oju apa too le jọ oju ara.

"Emi o ro pe iṣẹ-abẹ ni ọna abayọ fun gbogbo eeyan" Dokita Awwad lo sọrọ yii.

" A ti din iye iṣẹ-abẹ to yẹ ka maa ṣe ku."

Dokita Awwad sọ pe o ti sunmọ idaji bayii ninu atunṣẹ tawọn n ṣe lọsibitu oun,to jẹ awọn ko lo ilana iṣẹ-abẹ.

O ni eyi ri bẹẹ nitori awọn fẹ ki ẹjẹ de apa ibi ti atunṣe ti wa naa. O lo tun wa fun kawọn obinrin ti wọn ti jẹ irora abẹ ikọla ri, gbagbe ohun ti wọn la kọja.

O ṣalaye pe awọn ilana kan wa to ṣee lo lai ṣiṣẹ-abẹ, awọn bii eyi to pe ni ‘platelet-rich plasma’, ilana kan ti wọn n lo kaakiri ilana iṣegun bayii.

" Ohun ti a pe ni Plasma yii n mu ki aaye teeyan ti gba abẹrẹ ji pepe si i, yoo si jẹ ki ẹjẹ ṣan gba ibẹ bo ṣe yẹ’’

Ṣugbọn, owo itọju yii pọ gẹgẹ bi Dokita Awwad ṣe wi, o ni eyi maa n jẹ ko ṣoro fawọn eeyan to nifẹẹ si i lari ra a.

Atọka awọn orilẹde ti wọn n sanwo iṣẹ-abẹ naa fun awọn obinrin

Ara tuntun

Fun awọn ti wọn ṣiṣẹ-abẹ atunṣe yii,wọn maa n mọ ọ lara gan-an.

Ni ti Haja lati Sierra Leone, o pẹ ki ara tuntun to ṣe naa too mọ ọn lara.

‘’Ẹnu ya mi gidi nigba ti mo ri idọ mi fun igba akọkọ lẹyin iṣẹ-abẹ naa, niṣe lo da bii pe temi kọ.

“ Ọmọ ọdun mẹjọ ni mo wa nigba ti wọn dabẹ fun mi. Mi o wo apa ibẹ yẹn ninu ara mi ri.’’ Haja Bilkisu lo wi bẹẹ.

Fun Shamsa to ṣẹṣẹ n bọ sipo pada, o ni pẹlu gbese to wa lọrun oun, inu oun dun pe oun kowo leri iṣẹ-abẹ atunṣe naa.

“ Nigba ti ara mi balẹ tan,mo ni lati kọ bi maa ṣe maa lo idọ ati oju ara mi tuntun ni.

“Ṣugbọn nisinyi, mo ti mọ beeyan ṣe n jẹ obinrin to pé.”